Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 17

Jésù Kọ́ Nikodémù Lẹ́kọ̀ọ́ ní Òru

Jésù Kọ́ Nikodémù Lẹ́kọ̀ọ́ ní Òru

JÒHÁNÙ 2:23–3:21

  • JÉSÙ BÁ NIKODÉMÙ SỌ̀RỌ̀

  • OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI DI “ÀTÚNBÍ”

Nígbà tí Jésù wà ní Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ Ìrékọjá lọ́dún 30 S.K., ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ló ṣe. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Iṣẹ́ ìyanu tó ṣe wú ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nikodémù lórí. Farisí ni, ó sì wà lára ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù tí wọ́n ń pè ní Sànhẹ́dírìn. Torí ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i lọ́dọ̀ Jésù, ó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lóru. Kí nìdí tó fi lọ lóru? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló ń bẹ̀rù ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù bíi tiẹ̀ máa sọ tí wọ́n bá rí i, kò sì fẹ́ kí orúkọ òun bà jẹ́ láwùjọ.

Nikodémù sọ pé: “Rábì, a mọ̀ pé olùkọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ́, torí kò sẹ́ni tó lè ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tí ò ń ṣe yìí, àfi tí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú rẹ̀.” Jésù dá Nikodémù lóhùn pé kí ẹnì kan tó lè wọ Ìjọba Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ di ‘àtúnbí.’—Jòhánù 3:2, 3.

Àmọ́, báwo ni ẹnì kan ṣe lè di àtúnbí? Nikodémù bi í pé: “Kò lè wọnú ikùn ìyá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, kí ìyá rẹ̀ sì bí i, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?”—Jòhánù 3:4.

Jésù ṣàlàyé pé ohun tó túmọ̀ sí láti di àtúnbí kọ́ nìyẹn. Ó wá sọ pé: “Tí a kò bá bí ẹnì kan látinú omi àti ẹ̀mí, kò lè wọ Ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:5) Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, tí ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e, ó di ẹni tí a bí “látinú omi àti ẹ̀mí.” Ohùn kan wá dún láti ọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:16, 17) Ọlọ́run tipa bẹ́ẹ̀ kéde pé òun ti fi ẹ̀mí tún Jésù bí, ìyẹn á sì mú kó lè wọ Ìjọba ọ̀run. Nígbà tó di Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 S.K., Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn kan tó ti ṣèrìbọmi, àwọn náà di àtúnbí, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọmọ Ọlọ́run.—Ìṣe 2:1-4.

Ohun tí Jésù ń sọ nípa Ìjọba náà kò fi bẹ́ẹ̀ yé Nikodémù. Torí náà, Jésù ṣàlàyé sí i nípa iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí òun máa ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Bí Mósè ṣe gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ náà la gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ èèyàn sókè, kí gbogbo ẹni tó bá gbà á gbọ́ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:14, 15.

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ejò olóró bù jẹ gbọ́dọ̀ gbójú sókè wo ejò tí Mósè fi bàbà ṣe kí wọ́n má bàa kú. (Nọ́ńbà 21:9) Lọ́nà kan náà, kí gbogbo aráyé tó lè bọ́ lọ́wọ́ ikú, kí wọ́n sì rí ìyè àìnípẹ̀kun, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run. Ohun tí Jésù wá sọ fún Nikodémù jẹ́ kó rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó ní: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Jésù sọ ọ̀rọ̀ yìí ní Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé ipasẹ̀ rẹ̀ ni aráyé fi máa rí ìgbàlà.

Jésù sọ fún Nikodémù pé: “Ọlọ́run ò rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé kó lè ṣèdájọ́ ayé.” Ó túmọ̀ sí pé kò wá sáyé láti wá dá aráyé lẹ́bi pé ikú ló tọ́ sí gbogbo wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí Jésù ṣe sọ, Ọlọ́run rán an “kí ayé lè rí ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀.”—Jòhánù 3:17.

Ṣe ni Nikodémù fi òru bojú lọ sọ́dọ̀ Jésù torí ẹ̀rù ń bà á. Abájọ tí Jésù ṣe fi ọ̀rọ̀ yìí parí ìjíròrò wọn, ó ní: “Ohun tí a máa gbé ìdájọ́ kà nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ [ìyẹn Jésù, nípa ọ̀nà tó gbà gbé ayé rẹ̀ àtàwọn ohun tó fi kọ́ni] ti wá sí ayé, àmọ́ àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, torí pé oníṣẹ́ ibi ni wọ́n. Torí ẹnikẹ́ni tó bá ń hùwà burúkú kórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a má bàa dá àwọn iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́bi. Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ohun tó tọ́ máa ń wá sínú ìmọ́lẹ̀, ká lè fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn kedere pé ó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.”—Jòhánù 3:19-21.

Ó wá kù sọ́wọ́ Nikodémù tó jẹ́ Farisí àti olùkọ́ ní Ísírẹ́lì láti ronú lórí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ nípa ohun tí Jésù máa ṣe láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ.