Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 19

Jésù Kọ́ Obìnrin Ará Samáríà Kan Lẹ́kọ̀ọ́

Jésù Kọ́ Obìnrin Ará Samáríà Kan Lẹ́kọ̀ọ́

JÒHÁNÙ 4:3-43

  • JÉSÙ KỌ́ OBÌNRIN ARÁ SAMÁRÍÀ KAN ÀTÀWỌN MÍÌ LẸ́KỌ̀Ọ́

  • ÌJỌSÌN TÍ ỌLỌ́RUN TẸ́WỌ́ GBÀ

Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń bọ̀ láti Jùdíà lọ sí Gálílì, wọ́n gba apá àríwá lọ sí agbègbè Samáríà, ìrìn àjò náà sì mú kó rẹ̀ wọ́n gan-an. Nígbà tó di ọ̀sán, wọ́n sinmi nítòsí ìlú Síkárì létí kànga kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jékọ́bù ló gbẹ́ ẹ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn tàbí tó sanwó fáwọn kan láti gbẹ́. Èèyàn lè rí irú kànga yìí nítòsí ìlú Nablus ti òde òní.

Nígbà tí Jésù ń sinmi nítòsí kànga yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ìlú kan tó wà nítòsí láti ra oúnjẹ. Kí wọ́n tó dé, Jésù ti ń bá obìnrin ará Samáríà kan tó wá fa omi sọ̀rọ̀. Jésù sọ fún un pé: “Fún mi lómi mu.”—Jòhánù 4:7.

Àwọn Júù àtàwọn ará Samáríà kì í da nǹkan pọ̀ torí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó wà láàárín wọn. Torí náà, ẹnu ya obìnrin náà pé Jésù bá òun sọ̀rọ̀, ó wá bi í pé: “Báwo ni ìwọ, tí o jẹ́ Júù, ṣe máa ní kí èmi, obìnrin ará Samáríà fún ọ lómi?” Jésù dá a lóhùn pé: “Ká ní o mọ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ni, tí o sì mọ ẹni tó sọ fún ọ pé, ‘Fún mi lómi mu,’ ṣe lò bá bi í, ì bá sì ti fún ọ ní omi ìyè.” Ni obìnrin náà bá sọ fún un pé, “Ọ̀gá, o ò tiẹ̀ ní korobá tí o máa fi fa omi, kànga náà sì jìn. Ibo lo ti wá fẹ́ rí omi ìyè yìí? O ò tóbi ju Jékọ́bù baba ńlá wa lọ, ẹni tó fún wa ní kànga náà, tí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹran rẹ̀ mu nínú rẹ̀, àbí o tóbi jù ú lọ?”—Jòhánù 4:9-12.

Jésù wá sọ pé: “Gbogbo ẹni tó bá ń mu látinú omi yìí, òùngbẹ tún máa gbẹ ẹ́. Ẹnikẹ́ni tó bá mu látinú omi tí màá fún un, òùngbẹ ò ní gbẹ ẹ́ láé, àmọ́ omi tí màá fún un á di ìsun omi nínú rẹ̀, á sì máa tú yàà jáde láti fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 4:13, 14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ Jésù, síbẹ̀ ó jẹ́rìí fún obìnrin ará Samáríà náà nípa òtítọ́ tó ń fúnni ní ìyè.

Obìnrin náà wá sọ pé: “Ọ̀gá, fún mi ní omi yìí, kí òùngbẹ má bàa gbẹ mí, kí n má sì máa wá síbí yìí láti fa omi.” Ni Jésù bá fọgbọ́n yí ìjíròrò náà pa dà, ó wá sọ fún obìnrin náà pé: “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ẹ sì wá síbí yìí.” Obìnrin náà dáhùn pé: “Mi ò ní ọkọ.” Ó dájú pé ó máa ya obìnrin yẹn lẹ́nu nígbà tí Jésù sọ fún un pé: “Òótọ́ lo sọ, bí o ṣe sọ pé, ‘Mi ò ní ọkọ.’ Torí o ti ní ọkọ márùn-ún rí, ọkùnrin tí o sì ń fẹ́ báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ.”—Jòhánù 4:15-18.

Ọ̀rọ̀ tí Jésù bá a sọ ṣe kedere sí i, ó sì yà á lẹ́nu débi tó fi sọ pé: “Ọ̀gá, mo rí i pé wòlíì ni ọ́.” Ọ̀rọ̀ tí obìnrin yìí sọ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ nǹkan tẹ̀mí. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé: “Orí òkè [Gérísímù tó wà nítòsí] yìí ni àwọn baba ńlá wa [ìyẹn àwọn ará Samáríà] ti jọ́sìn, àmọ́ ẹ̀yin [Júù] sọ pé Jerúsálẹ́mù ni àwọn èèyàn ti gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn.”—Jòhánù 4:19, 20.

Àmọ́, Jésù jẹ́ kó mọ̀ pé ibi téèyàn ti ń jọ́sìn kọ́ ló ṣe pàtàkì. Ó ní: “Wákàtí náà ń bọ̀ tí ẹ ò ní máa jọ́sìn Baba lórí òkè yìí tàbí ní Jerúsálẹ́mù.” Ó wá sọ fún un pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ á máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, torí ní tòótọ́, irú àwọn ẹni yìí ni Baba ń wá pé kí wọ́n máa jọ́sìn òun.”—Jòhánù 4:21, 23, 24.

Ohun tó ṣe pàtàkì sí Jèhófà ni ọ̀nà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà jọ́sìn rẹ̀, kì í ṣe ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn. Ohun tí Jésù sọ wú obìnrin yẹn lórí gan-an. Obìnrin náà wá sọ pé: “Mo mọ̀ pé Mèsáyà ń bọ̀, ẹni tí wọ́n ń pè ní Kristi. Nígbàkigbà tí ẹni yẹn bá dé, ó máa sọ gbogbo nǹkan fún wa ní gbangba.”—Jòhánù 4:25.

Jésù wá sọ òtítọ́ pàtàkì kan, ó ní: “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni ẹni náà.” (Jòhánù 4:26) Rò ó wò ná! Omi ni obìnrin yìí wá fà. Síbẹ̀, Jésù fi inúure hàn sí i. Ó tún dìídì sọ fún un pé òun ni Mèsáyà, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó ṣeé ṣe kó má tíì sọ fún ẹnikẹ́ni rí.

Ọ̀PỌ̀ ÀWỌN ARÁ SAMÁRÍÀ DI ONÍGBÀGBỌ́

Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pa dà dé láti Síkárì tí wọ́n ti lọ ra oúnjẹ. Ìdí kànga Jékọ́bù tí wọ́n fi Jésù sí náà ni wọ́n ti bá a, ó sì yà wọ́n lẹ́nu pé ó ń bá obìnrin ará Samáríà sọ̀rọ̀. Bí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe dé, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà fi korobá omi rẹ̀ sílẹ̀, ó sì pa dà sínú ìlú.

Nígbà tí obìnrin náà dé Síkárì, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo èèyàn nípa ohun tí Jésù sọ fún un. Ó wá fi ìdánilójú sọ fún wọn pé: “Ẹ wá wo ọkùnrin kan tó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi.” Kó bàa lè wu àwọn èèyàn náà láti lọ, ó béèrè pé: “Ṣé kì í ṣe pé òun ni Kristi?” (Jòhánù 4:29) Ọjọ́ pẹ́ tí ìbéèrè yẹn ti ń jà gùdù lọ́kàn àwọn èèyàn, kódà bó ṣe rí nìyẹn látìgbà ayé Mósè. (Diutarónómì 18:18) Èyí ló mú kí àwọn ará ìlú yẹn lọ fi ojú ara wọn rí Jésù.

Ní gbogbo àsìkò yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń rọ Jésù pé kó jẹun. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Mo ní oúnjẹ tí màá jẹ tí ẹ ò mọ̀ nípa rẹ̀.” Ohun tó sọ yìí ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́nu, wọ́n sì ń sọ láàárín ara wọn pé: “Ẹnì kankan ò gbé oúnjẹ wá fún un, àbí?” Jésù wá sọ ọ̀rọ̀ kan tó kan gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi, kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 4:32-34.

Kì í ṣe iṣẹ́ kíkórè ọkà táwọn èèyàn máa ṣe ní nǹkan bí oṣù mẹ́rin lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Jésù ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìkórè tẹ̀mí ni Jésù ní lọ́kàn, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun, wọ́n ti tó kórè. Ní báyìí, olùkórè ti ń gba èrè, ó sì ń kó èso jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun, kí afúnrúgbìn àti olùkórè lè jọ yọ̀.”—Jòhánù 4:35, 36.

Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti mọ ibi tí ọ̀rọ̀ tóun bá obìnrin ará Samáríà náà sọ máa yọrí sí. Ohun tí obìnrin yẹn sọ mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn ìlú náà gba Jésù gbọ́ nítorí ó ń sọ fún wọn pé: “Gbogbo ohun tí mo ṣe ló sọ fún mi.” (Jòhánù 4:39) Wọ́n gbéra láti Síkárì, wọ́n sì lọ bá Jésù nídìí kànga, nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó dúró sọ́dọ̀ àwọn káwọn lè túbọ̀ gbọ́rọ̀ ẹ̀. Jésù gbà pẹ̀lú wọn, ó sì dúró sí Samáríà fún ọjọ́ méjì.

Bí àwọn ará Samáríà ṣe ń tẹ́tí sí Jésù, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó gbà á gbọ́ ń pọ̀ sí i. Wọ́n sì sọ fún obìnrin náà pé: “Kì í ṣe ohun tí o sọ nìkan ló mú ká gbà gbọ́; torí àwa fúnra wa ti gbọ́, a sì mọ̀ pé olùgbàlà ayé ni ọkùnrin yìí lóòótọ́.” (Jòhánù 4:42) Ó dájú pé àpẹẹrẹ àtàtà ni obìnrin ará Samáríà yìí jẹ́ tó bá di pé ká wàásù nípa Kristi, ká sì mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa.

Ẹ má gbàgbé pé ó ṣì ku oṣù mẹ́rin kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í kórè ọkà báálì, èyí tó sábà máa ń bọ́ sí ìgbà ìrúwé lágbègbè yẹn. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ oṣù November tàbí December ni Jésù sọ̀rọ̀ yẹn. Ìyẹn fi hàn pé lẹ́yìn Ìrékọjá ọdún 30 S.K., Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti lo nǹkan bí oṣù mẹ́jọ ní Jùdíà, tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ń batisí wọn. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n wá lọ sí Gálílì tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ wọn lápá àríwá. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn níbẹ̀?