Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 30

Bí Jésù Ṣe Jẹ́ sí Baba Rẹ̀

Bí Jésù Ṣe Jẹ́ sí Baba Rẹ̀

JÒHÁNÙ 5:17-47

  • ỌLỌ́RUN NI BABA JÉSÙ

  • JÉSÙ ṢÈLÉRÍ PÉ ÀWỌN ÒKÚ MÁA JÍǸDE

Nígbà táwọn Júù fẹ̀sùn kan Jésù pé ó rú òfin Sábáàtì torí pé ó wo ọkùnrin kan sàn lọ́jọ́ Sábáàtì, Jésù dá wọn lóhùn pé: “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di báyìí, èmi náà ṣì ń ṣiṣẹ́.”—Jòhánù 5:17.

Jésù kò ṣe ohunkóhun tó lòdì sí òfin Ọlọ́run nípa Sábáàtì. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àpẹẹrẹ Baba rẹ̀ ni Jésù ń tẹ̀ lé bó ṣe ń wàásù tó sì ń wo àwọn èèyàn sàn. Abájọ tó fi ń ṣe iṣẹ́ rere lójoojúmọ́. Àmọ́ o, èsì tó fún àwọn alátakò rẹ̀ tún múnú bí wọn gan-an débi pé ṣe ni wọ́n ń wá ọ̀nà àtipa á. Kí ló le tó bẹ́ẹ̀?

Kì í ṣe pé àwọn Júù yẹn bínú sí Jésù pé ó ń wo àwọn èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì nìkan ni, wọ́n tún ń bínú torí Jésù sọ pé ọmọ Ọlọ́run lòun. Wọ́n ní ọ̀rọ̀ òdì ni Jésù sọ bó ṣe pe ara rẹ̀ ní ọmọ Ọlọ́run, bí ẹni pé Jésù ń sọ pé òun àti Baba òun dọ́gba. Àmọ́ Jésù ò bẹ̀rù, ó jẹ́ kí wọ́n mọ bóun àti Bàbá òun ṣe jẹ́ síra. Ó sọ fún wọn pé: “Baba ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọmọ, ó sì ń fi gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe hàn án.”—Jòhánù 5:20.

Jèhófà ni Olùfúnni-ní-Ìyè, ó sì hàn nínú bó ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan nígbà àtijọ́ lágbára láti jí òkú dìde. Jésù sọ pé: “Bí Baba ṣe ń jí àwọn òkú dìde gẹ́lẹ́, tó sì ń mú kí wọ́n wà láàyè, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ń sọ àwọn tí òun bá fẹ́ di alààyè.” (Jòhánù 5:21) Ọ̀rọ̀ yìí ò ṣòro lóye, ó sì fini lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la máa dáa! Kódà, Jésù ń jí àwọn òkú dìde nípa tẹ̀mí lásìkò wa yìí. Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tó sì gba Ẹni tó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun, a ò sì ní dá a lẹ́jọ́, àmọ́ ó ti tinú ikú bọ́ sínú ìyè.”—Jòhánù 5:24.

Lásìkò tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí, kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó sọ pé ó ti jí òkú dìde, àmọ́ ó sọ fún àwọn alátakò rẹ̀ pé òun máa jí àwọn tó ti kú dìde. Ó ní: “Wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn [òun], tí wọ́n á sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó dà bíi Jésù nígbà tó wà láyé, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ọlọ́run ju òun lọ, ó ní: “Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara mi. . . . Kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mò ń wá, ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni.” (Jòhánù 5:30) Jésù wá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe ipa kékeré lòun ń kó láti mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tó máa sọ bẹ́ẹ̀ létí gbogbo èèyàn. Yàtọ̀ sí ohun tí Jésù sọ yìí, àwọn nǹkan míì wà tó jẹ́rìí sí i pé ọmọ Ọlọ́run ni, ó sì hàn kedere sáwọn alátakò rẹ̀. Jésù rán wọn létí pé: “Ẹ ti rán àwọn èèyàn sí Jòhánù [Arinibọmi], ó sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.”—Jòhánù 5:33.

Ó ṣeé ṣe káwọn alátakò tó fẹ̀sùn kan Jésù gbọ́ ohun tí Jòhánù sọ fáwọn aṣáájú ìsìn Júù ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn pé Ẹnì kan ń bọ̀ lẹ́yìn òun, ìyẹn ẹni tí wọ́n mọ̀ sí “Wòlíì” tàbí “Kristi.” (Jòhánù 1:20-25) Jésù wá rán wọn létí bí wọ́n ṣe bọ̀wọ̀ fún Jòhánù tó kó tó dèrò ẹ̀wọ̀n. Jésù sọ pé: “Ó . . . wù yín pé kí ẹ yọ̀ gidigidi nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ fúngbà díẹ̀.” (Jòhánù 5:35) Àmọ́ o, kékeré ni ẹ̀rí tí Jòhánù jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Jésù.

Jésù sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí, [títí kan ìwòsàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe] ń jẹ́rìí sí i pé Baba ló rán mi.” Jésù wá fi kún un pé: “Baba tó . . . rán mi ti fúnra rẹ̀ jẹ́rìí nípa mi.” (Jòhánù 5:36, 37) Àpẹẹrẹ kan ni bí Jèhófà ṣe jẹ́rìí nípa Jésù nígbà tó ṣèrìbọmi.—Mátíù 3:17.

Torí náà, àwọn tó ń fẹ̀sùn kan Jésù kò ní àwíjàre kankan, kò sídìí tó fi yẹ kí wọ́n kọ̀ ọ́. Ó ṣe tán, Ìwé Mímọ́ tí wọ́n sọ pé àwọn ń kà jẹ́rìí nípa Jésù. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá gba Mósè gbọ́, ẹ máa gbà mí gbọ́, torí ó kọ̀wé nípa mi. Àmọ́ tí ẹ ò bá gba ohun tó kọ gbọ́, báwo lẹ ṣe máa gba ohun tí mo sọ gbọ́?”—Jòhánù 5:46, 47.