Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 34

Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

MÁÀKÙ 3:13-19 LÚÙKÙ 6:12-16

  • ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ MÉJÌLÁ

Ó ti tó nǹkan bí ọdún kan àtààbọ̀ báyìí tí Jòhánù Arinibọmi ti kéde fáwọn èèyàn pé Jésù ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run. Bí Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin mélòó kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Lára wọn ni Áńdérù, Símónì Pétérù, Jòhánù, ó ṣeé ṣe kí Jémíìsì náà wà lára wọn (ìyẹn arákùnrin Jòhánù), Fílípì àti Bátólómíù (tó tún ń jẹ́ Nàtáníẹ́lì). Nígbà tó yá, àwọn míì náà bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Kristi.—Jòhánù 1:45-47.

Ó ti wá tó àkókò báyìí tí Jésù máa yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Àwọn ló máa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ó sì máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ lákànṣe. Àmọ́ kó tó yàn wọ́n, ó lọ sórí òkè kan, bóyá èyí tó wà nítòsí Òkun Gálílì, tí kò jìnnà sí Kápánáúmù. Gbogbo òru mọ́jú ló fi gbàdúrà, ó ṣeé ṣe kó bẹ Jèhófà pé kó fún òun ní ọgbọ́n, kó sì tọ́ òun sọ́nà. Nígbà tó dọjọ́ kejì, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jọ, ó sì yan méjìlá (12) lára wọn láti di àpọ́sítélì.

Jésù yan àwọn mẹ́fà tá a dárúkọ ṣáájú àti Mátíù tó pè ní ọ́fíìsì àwọn agbowó orí. Àwọn márùn-ún yòókù ni Júdásì (tó tún ń jẹ́ Tádéọ́sì “ọmọ Jémíìsì”), Símónì tó jẹ́ Kánánéánì, Tọ́másì, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù.—Mátíù 10:2-4; Lúùkù 6:16.

Ó ṣe díẹ̀ táwọn méjìlá yìí ti ń bá Jésù rìnrìn àjò, ó sì dájú pé ó mọ̀ wọ́n dáadáa. Mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tiẹ̀ làwọn kan lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, kò sí àní-àní pé ìbátan tímọ́tímọ́ Jésù ni Jémíìsì àti Jòhánù tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò. Tó bá sì jẹ́ pé òótọ́ làwọn kan sọ pé arákùnrin ni Áfíọ́sì jẹ́ sí Jósẹ́fù alágbàtọ́ Jésù, á jẹ́ pé mọ̀lẹ́bí Jésù ni àpọ́sítélì Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì.

Kò ṣòro rárá fún Jésù láti rántí orúkọ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Àmọ́ ṣé ìwọ náà lè dárúkọ wọn? Jẹ́ ká ṣe ohun kan tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Símónì méjì ló wà, Jémíìsì méjì àti Júdásì méjì. Símónì (Pétérù) ní arákùnrin kan tó ń jẹ́ Áńdérù, Jémíìsì (ọmọ Sébédè) náà sì ní arákùnrin kan tó ń jẹ́ Jòhánù. Ìyẹn ti jẹ́ ká mọ orúkọ mẹ́jọ lára wọn. Àwọn mẹ́rin yòókù ni agbowó orí kan (Mátíù), èyí tó ṣiyèméjì nígbà tó yá (Tọ́másì), èyí tí wọ́n pè lábẹ́ igi (Nàtáníẹ́lì) àti ọ̀rẹ́ Nàtáníẹ́lì (Fílípì).

Gálílì tó jẹ́ agbègbè ìbílẹ̀ Jésù ni mọ́kànlá lára àwọn àpọ́sítélì náà ti wá. Kánà ni Nàtáníẹ́lì ti wá. Bẹtisáídà ni Fílípì, Pétérù àti Áńdérù ti wá. Nígbà tó yá, Pétérù àti Áńdérù kó lọ sí Kápánáúmù, níbi tó ṣeé ṣe kí Mátíù máa gbé. Jémíìsì àti Jòhánù náà ń gbé ní Kápánáúmù tàbí nítòsí ibẹ̀, wọ́n sì ń ṣe òwò ẹja pípa níbẹ̀. Ó jọ pé Júdásì Ìsìkáríọ́tù tó da Jésù níkẹyìn nìkan ni àpọ́sítélì tó wá láti Jùdíà.