Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 35

Ìwàásù Orí Òkè

Ìwàásù Orí Òkè

MÁTÍÙ 5:1–7:29 LÚÙKÙ 6:17-49

  • ÌWÀÁSÙ ORÍ ÒKÈ

Ó dájú pé á ti rẹ Jésù lẹ́yìn tó gbàdúrà láti òru mọ́jú, tó sì yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá (12) tó máa jẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀. Ilẹ̀ ti wá mọ́ báyìí, síbẹ̀ kò rẹ Jésù débi tí ò fi ní lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ torí ó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ló bá lọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè kan ní Gálílì tó ṣeé ṣe kó wà nítòsí Kápánáúmù tó ti máa ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá a wá láti ọ̀nà jíjìn. Àwọn kan wá láti apá gúúsù, ìyẹn láti Jerúsálẹ́mù àtàwọn agbègbè kan ní Jùdíà. Àwọn agbègbè etí òkun ní Tírè àti Sídónì lápá àríwá ni àwọn tó kù sì ti wá. Kí nìdí tí wọ́n fi wá sọ́dọ̀ Jésù? Ìdí ni pé ‘wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì fẹ́ rí ìwòsàn.’ Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn, Jésù “wo gbogbo wọn sàn.” Àbẹ́ ò rí nǹkan! Gbogbo àwọn tára wọn ò yá ló rí ìwòsàn. Kódà, “àwọn tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú” pàápàá rí ìwòsàn, ìyẹn àwọn tí àwọn áńgẹ́lì Sátánì ń pọ́n lójú.—Lúùkù 6:17-19.

Jésù wá rí ibì kan tó tẹ́jú lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, àwọn èrò sì yí i ká. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) ló jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ló fẹ́ gbọ́ ohun tí olùkọ́ tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu yìí máa sọ. Ìwàásù Jésù ṣe ọ̀pọ̀ àwọn tó gbọ́ ọ láǹfààní gan-an. Àtìgbà yẹn lọ̀pọ̀ èèyàn sì ti ń jàǹfààní látinú ìwàásù yìí. Àwa náà lè jàǹfààní nínú ẹ̀ torí ìwàásù náà jinlẹ̀, ó rọrùn lóye, ó sì ṣe kedere. Àwọn àpèjúwe àtàwọn nǹkan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni Jésù lò. Èyí mú kí ohun tó ń sọ yé àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀, ìyẹn àwọn tó fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn kókó pàtàkì wo ni Jésù sọ nínú Ìwàásù orí Òkè?

ÀWỌN WO LÓ MÁA Ń NÍ AYỌ̀ TÒÓTỌ́?

Gbogbo èèyàn ló fẹ́ láyọ̀. Jésù mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ pẹ̀lú ohun tó lè fúnni láyọ̀ tòótọ́. Ẹ wo bọ́rọ̀ yìí ṣe máa wọ àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́kàn. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan kan máa rú wọn lójú.

Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn. Aláyọ̀ ni àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, torí a máa tù wọ́n nínú. . . . Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, torí wọ́n máa yó. . . . Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn. Aláyọ̀ ni yín tí àwọn èèyàn bá pẹ̀gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni sí yín . . . nítorí mi. Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì dùn gidigidi.”—Mátíù 5:3-12.

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “aláyọ̀”? Kì í ṣe kéèyàn lè dẹ́rìn-ín pani tàbí kó lè ṣàwàdà. Ayọ̀ tòótọ́ tí Jésù ń sọ jinlẹ̀ jùyẹn lọ. Èèyàn máa nírú ayọ̀ yìí tó bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, tọ́kàn ẹ̀ balẹ̀, tó sì ń fayé ẹ̀ ṣe ohun tó nítumọ̀.

Jésù sọ pé àwọn tó bá fẹ́ ní ayọ̀ tòótọ́ gbọ́dọ̀ gbà pé àwọn nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, kí wọ́n kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n mọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa sìn ín. Táwọn èèyàn bá tiẹ̀ kórìíra wọn tàbí ṣenúnibíni sí wọn torí pé wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, inú wọn ń dùn torí wọ́n mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ làwọn ń ṣe, wọ́n sì mọ̀ pé ó máa fi ìyè àìnípẹ̀kun san àwọn lẹ́san.

Ọ̀pọ̀ ló rò pé ohun tó ń fúnni láyọ̀ ni pé kéèyàn rí towó ṣe, kó sì jayé débi tó bá lè jẹ ẹ́ dé. Àmọ́ ohun tí Jésù sọ yàtọ̀ síyẹn. Ó sọ ohun tó máa mú káwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ ronú jinlẹ̀, ó ní: “Ó mà ṣe fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ o, torí pé ẹ̀ ń rí ìtùnú gbà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ó mà ṣe fún ẹ̀yin tí ẹ yó báyìí o, torí ebi máa pa yín. Ó mà ṣe fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín báyìí o, torí ẹ máa ṣọ̀fọ̀, ẹ sì máa sunkún. Ó mà ṣe fún yín o, nígbàkigbà tí gbogbo èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín dáadáa, torí ohun tí àwọn baba ńlá wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké nìyí.”—Lúùkù 6:24-26.

Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé ó mà ṣe o fún àwọn tó lọ́rọ̀, àwọn tó ń rẹ́rìn-ín àtàwọn tí àwọn èèyàn ń yìn? Ìdí ni pé tẹ́nì kan bá ka àwọn nǹkan yìí sí pàtàkì jù, onítọ̀hún lè pa ìjọsìn Ọlọ́run tì, kò sì ní rí ayọ̀ tòótọ́. Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé èèyàn máa láyọ̀ tó bá ṣáà ti jẹ́ òtòṣì, tí kò sì rí oúnjẹ jẹ? Rárá o. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ló máa ń ṣe ohun tí Jésù sọ, tí wọ́n sì ń rí ìbùkún àti ayọ̀ tòótọ́.

Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé.” (Mátíù 5:13) Ó dájú pé kì í ṣe iyọ̀ tá a fi ń sebẹ̀ ni Jésù ń sọ. Àfiwé lásán ló ń ṣe, bí àpẹẹrẹ, iyọ̀ kì í jẹ́ kí nǹkan tètè bà jẹ́. Wọ́n tún máa ń kó iyọ̀ tó pọ̀ gan-an sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ tó wà nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n sì máa ń fi sí àwọn ọrẹ tí wọ́n bá fẹ́ fi rúbọ. Yàtọ̀ síyẹn, iyọ̀ máa ń ṣàpẹẹrẹ ohun tí kò lè bà jẹ́ tàbí tí kò lè jẹrà. (Léfítíkù 2:13; Ìsíkíẹ́lì 43:23, 24) Torí náà, nígbà tí Jésù sọ pé “ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé,” ohun tó ń sọ ni pé wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn lóhun tí kò ní jẹ́ kí ìgbésí ayé wọn bà jẹ́, wọ́n sì ń jẹ́ kí wọ́n yẹra fún àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ tàbí tó lè sọ wọ́n dìdàkudà. Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, ìhìn rere táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń kéde lè gba ẹ̀mí gbogbo àwọn tó bá ń fetí sí wọn là.

Jésù tún sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Ó ṣetán a kì í gbé fìtílà sábẹ́ apẹ̀rẹ̀, orí ọ̀pá fìtílà la máa ń gbé e sí kó lè tan ìmọ́lẹ̀ sínú gbogbo ilé. Torí náà, Jésù gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín, kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.”—Mátíù 5:14-16.

ÌLÀNÀ TÁWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN JÉSÙ Á MÁA TẸ̀ LÉ

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbà pé Jésù kì í pa Òfin Ọlọ́run mọ́, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa pa á. Àmọ́, Jésù sọ pé: “Ẹ má rò pé mo wá láti pa Òfin tàbí àwọn Wòlíì run. Mi ò wá láti pa á run, àmọ́ láti mú un ṣẹ.”—Mátíù 5:17.

Ó dájú pé Jésù máa ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́, ó sì máa ń gba àwọn míì níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá tẹ ọ̀kan nínú àwọn àṣẹ tó kéré jù yìí lójú, tó sì ń kọ́ àwọn míì pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, a máa pè é ní ẹni tó kéré jù lọ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run.” Ohun tí Jésù ń sọ ni pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò ní wọnú Ìjọba Ọlọ́run rárá. Ó tún fi kún un pé: “Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń pa á mọ́, tó sì ń fi kọ́ni, a máa pè é ní ẹni ńlá ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run.”—Mátíù 5:19.

Jésù dẹ́bi fáwọn ìwà tó máa ń jẹ́ kéèyàn rú Òfin Ọlọ́run. Lẹ́yìn tó tọ́ka sí Òfin tó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn,” ó sọ pé: “Gbogbo ẹni tí kò bá yéé bínú sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún ilé ẹjọ́.” (Mátíù 5:21, 22) Téèyàn bá ń bínú sí ẹlòmíì, tí kò sì gbé ìbínú náà kúrò lọ́kàn, ó lè jẹ̀bi ìpànìyàn. Torí náà, Jésù sọ ohun tó yẹ ká ṣe ká lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, ó ní: “Tí o bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ. Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ, lẹ́yìn náà, kí o pa dà wá fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Mátíù 5:23, 24.

Òfin míì tún dẹ́bi fún àgbèrè. Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.’ Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá tẹjú mọ́ obìnrin kan lọ́nà tí á fi wù ú láti bá a ṣe ìṣekúṣe, ó ti bá a ṣe àgbèrè nínú ọkàn rẹ̀.” (Mátíù 5:27, 28) Kì í ṣe èrò tó kàn wá síni lọ́kàn fìrí téèyàn sì gbé kúrò lọ́kàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Jésù ń sọ. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ń jẹ́ ká rí bó ṣe léwu tó téèyàn bá ń “tẹjú mọ́” ohun tí kò yẹ kó wò. Ìdí sì ni pé téèyàn bá ń tẹjú mọ́ ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀, ọkàn ẹ̀ á máa fà sí i ni ṣáá. Tó bá wá ní àǹfààní ẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ó lè bá a ṣèṣekúṣe. Kí lèèyàn lè ṣe kí irú ẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀? Àwọn kan máa ń sọ pé ojú bọ̀rọ̀ kọ́ ni wọ́n fi ń gbọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́, tó túmọ̀ sí pé èèyàn gbọ́dọ̀ sapá gan-an kó má bàa ṣèṣekúṣe. Jésù sọ pé: “Tí ojú ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. . . . Tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, gé e, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.”—Mátíù 5:29, 30.

Àwọn kan ti gbà kí oníṣègùn gé ẹsẹ̀ àwọn kí àwọn má bàa kú. Ó sì bọ́gbọ́n mu torí Jésù náà sọ pé ó ṣe pàtàkì ká sọ ohunkóhun tó lè mú ká máa ro èròkerò nù, ká má bàa ti ìka àbámọ̀ bọnu. Ó ní: “Ó sàn kí o má ní ẹ̀yà ara kan ju kí o bá gbogbo ara rẹ nínú Gẹ̀hẹ́nà” (ìyẹn ààtàn kan tí wọ́n ti ń sun ìdọ̀tí lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù), tó túmọ̀ sí ìparun pátápátá.

Jésù tún sọ ohun tó yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá fẹ́ bá wa jà tàbí tí wọ́n bá ń bú wa. Ó ní: “Ẹ má ṣe ta ko ẹni burúkú, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá gbá yín ní etí ọ̀tún, ẹ yí èkejì sí i.” (Mátíù 5:39) Ìyẹn ò sọ pé a ò lè dáàbò bo ara wa tàbí ìdílé wa tẹ́nì kan bá fẹ́ ṣe wọ́n léṣe, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tá a máa ṣe tẹ́nì kan bá rí wa fín tàbí bú wa ló ń tọ́ka sí. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé tẹ́nì kan bá fẹ́ bá wa jà tàbí tó ń bá wa jiyàn, yálà ṣe ló gbá wa létí ni o tàbí ṣe ló ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wa, a ò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san.

Ìmọ̀ràn yẹn bá ohun tó wà nínú òfin Ọlọ́run mu pé ká nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa. Jésù wá sọ fún àwọn tó ń tẹ́tí sí i pé: “Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín.” Ó tún sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kí ẹ lè fi hàn pé ọmọ Baba yín tó wà ní ọ̀run lẹ jẹ́, torí ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere.”—Mátíù 5:44, 45.

Jésù ṣàkópọ̀ ohun tó ń sọ nínú apá yìí, ó ní: “Kí ẹ jẹ́ pípé gẹ́lẹ́, bí Baba yín ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.” (Mátíù 5:48) Jésù ò sọ pé àwa èèyàn lè jẹ́ pípé bíi ti Jèhófà, ohun tó ń sọ ni pé tá a bá ń fara wé Ọlọ́run, àá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn títí kan àwọn ọ̀tá wa pàápàá. Lédè míì, ó gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa jẹ́ aláàánú, bí Baba yín ṣe jẹ́ aláàánú.”—Lúùkù 6:36.

GBÀDÚRÀ KÓ O SÌ GBẸ́KẸ̀ LÉ ỌLỌ́RUN

Jésù tún gba àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ nímọ̀ràn pé: “Ẹ rí i pé ẹ ò ṣe òdodo yín níwájú àwọn èèyàn, torí kí wọ́n lè rí yín.” Jésù dẹ́bi fún ìwà àgàbàgebè nígbà tó sọ pé: “Tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe fun kàkàkí ṣáájú ara rẹ, bí àwọn alágàbàgebè ṣe ń ṣe.” (Mátíù 6:1, 2) Torí náà, kò yẹ ká máa ṣe àṣehàn tá a bá fẹ́ fúnni lẹ́bùn.

Jésù wá sọ pé: “Tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe bíi ti àwọn alágàbàgebè, torí tí wọ́n bá ń gbàdúrà, wọ́n máa ń fẹ́ dúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní ìkóríta àwọn ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba, kí àwọn èèyàn lè rí wọn.” Ó fi kún un pé: “Tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ, lẹ́yìn tí o bá ti ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀.” (Mátíù 6:5, 6) Jésù ò sọ pé ká má gbàdúrà ní gbangba rárá, torí pé òun náà ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó ń sọ ni pé ká má ṣe máa gbàdúrà tó lè mú káwọn èèyàn máa kan sáárá sí wa tàbí kí wọ́n máa yìn wá.

Jésù tún sọ pé: “Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe máa ń ṣe.” (Mátíù 6:7) Jésù ò sọ pé ó burú láti gbàdúrà nípa ohun kan léraléra. Àmọ́ kò fẹ́ ká máa ka àkọ́sórí tàbí ká máa sọ ohun kan náà ní “àsọtúnsọ” tá a bá ń gbàdúrà. Jésù wá sọ ohun méje tó yẹ ká máa gbàdúrà fún nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Mẹ́ta àkọ́kọ́ jẹ mọ́ ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti jẹ́ alákòóso àtohun tó ní lọ́kàn fún aráyé. Bí àpẹẹrẹ, ó ní ká máa gbàdúrà pé kí orúkọ Jèhófà di mímọ́, kí Ìjọba rẹ̀ dé, kí ìfẹ́ rẹ̀ sì ṣẹ. Ẹ̀yìn ìyẹn la wá lè gbàdúrà fún oúnjẹ òòjọ́ àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. A tún lè bẹ Jèhófà pé kó má ṣe jẹ́ ká kó sínú ìdẹwò, kó sì gbà wá lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.

Báwo ló ṣe yẹ káwọn ohun ìní tara gbà wá lọ́kàn tó? Jésù sọ fáwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ pé: “Ẹ má to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ayé mọ́, níbi tí òólá ti ń jẹ nǹkan run, tí nǹkan ti ń dípẹtà, tí àwọn olè ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè.” Ẹ ò rí i pé ohun tó sọ yẹn bọ́gbọ́n mu gan-an! Torí bópẹ́ bóyá ohun ìní tara máa bà jẹ́, béèyàn bá sì kó wọn jọ, kò sọ pé kéèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìyẹn bá ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn náà mu, ó ní: “Ẹ to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run.” A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ láyé wa. Kò sẹ́ni tó lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ tàbí tó lè sọ pé kó má fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Torí náà, òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.”—Mátíù 6:19-21.

Kí kókó yìí lè túbọ̀ ṣe kedere, Jésù ṣe àkàwé kan, ó ní: “Ojú ni fìtílà ara. Tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ máa mọ́lẹ̀ yòò. Àmọ́ tí ojú rẹ bá ń ṣe ìlara, gbogbo ara rẹ máa ṣókùnkùn.” (Mátíù 6:22, 23) Tá a bá ń lo ojú wa bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, á dà bí àtùpà tó ń jẹ́ ká ríran kedere. Àmọ́ kíyẹn lè ṣeé ṣe, ibì kan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ gbájú mọ́, torí pé tá a bá ń wo ìhín wo ọ̀hún, a ò ní lè ṣèpinnu tó tọ́ nígbèésí ayé wa. Torí náà, tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan ìní tara ló gbà wá lọ́kàn dípò ìjọsìn Ọlọ́run, ó túmọ̀ sí pé “gbogbo ara [wa] máa ṣókùnkùn.” Lédè míì, a lè lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tí kò mọ́ tàbí tínú Jèhófà ò dùn sí.

Jésù wá sọ àpẹẹrẹ kan tó sojú abẹ níkòó pé: “Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì; àfi kó kórìíra ọ̀kan, kó sì nífẹ̀ẹ́ ìkejì tàbí kó fara mọ́ ọ̀kan, kó má sì ka ìkejì sí. Ẹ ò lè sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.”—Mátíù 6:24.

Ó ṣeé ṣe káwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù máa ronú pé báwo làwọn ṣe máa gbọ́ bùkátà àwọn tó bá jẹ́ pé ìjọsìn Ọlọ́run làwọn fi ṣáájú ní ìgbésí ayé àwọn. Jésù wá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé kò sídìí tó fi yẹ kí wọ́n máa ṣàníyàn, ó ní: “Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run; wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn.”—Mátíù 6:26.

Kí ni Jésù sọ nípa òdòdó lílì inú pápá tó wà nítòsí wọn? Ó ní: “A ò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí.” Kí ló fẹ́ ká kọ́ nínú àkàwé yìí? Ó sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ?” (Mátíù 6:29, 30) Jésù wá gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ wá sọ pé, ‘Kí la máa jẹ?’ tàbí, ‘Kí la máa mu?’ tàbí, ‘Kí la máa wọ̀?‘ . . . Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan yìí. Torí náà, ẹ máa wá Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn yìí la sì máa fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:31-33.

BÍ A ṢE LÈ RÍ ÌYÈ

Bí àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ṣe máa wu Ọlọ́run ló jẹ wọ́n lógún, àmọ́ kò rọrùn fún wọn torí ipò tí wọ́n bá ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Farisí ò mọ̀ ju kí wọ́n máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Torí náà, Jésù gba àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; torí bí ẹ bá ṣe dáni lẹ́jọ́ la ṣe máa dá yín lẹ́jọ́.”—Mátíù 7:1, 2.

Èèyàn á kó sínú ìjàngbọ̀n tó bá ń tẹ́tí sáwọn Farisí tó jẹ́ alárìíwísí, ìyẹn ni Jésù fi ṣàkàwé pé: “Afọ́jú kò lè fi afọ́jú mọ̀nà, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa ṣubú sí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ojú wo ni Jésù fẹ́ káwọn olùgbọ́ rẹ̀ máa fi wo àwọn míì? Kò fẹ́ kí wọ́n máa ṣe àríwísí àwọn èèyàn torí pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni. Ó bi wọ́n pé: “Báwo lo ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí n bá ọ yọ pòròpórò tó wà nínú ojú rẹ,’ nígbà tó jẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ ò rí igi ìrólé tó wà nínú ojú tìrẹ? Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ, ìgbà yẹn lo máa wá ríran kedere láti yọ pòròpórò tó wà nínú ojú arákùnrin rẹ.”—Lúùkù 6:39-42.

Èyí ò wá túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò ní ríbi táwọn míì kù sí. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe fún àwọn ajá ní ohun tó jẹ́ mímọ́, ẹ má sì sọ àwọn péálì yín síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀.” (Mátíù 7:6) Ohun iyebíye ni òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣe ló dà bíi péálì. Torí náà, táwọn kan bá ń hùwà bí ẹranko, tí wọn ò mọrírì òtítọ́ tó ṣeyebíye, á dáa káwọn ọmọ ẹ̀yìn kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí wọ́n sì wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ.

Jésù tún pa dà sórí ọ̀rọ̀ àdúrà, ó sì rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n tẹra mọ́ àdúrà gbígbà. Ó ní: “Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín.” Jésù jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà wa nígbà tó sọ pé: “Èwo nínú yín ló jẹ́ pé, tí ọmọ rẹ̀ bá béèrè búrẹ́dì, ó máa fún un ní òkúta? . . . Torí náà, tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn tó dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín, mélòómélòó wá ni Baba yín tó wà ní ọ̀run, ohun tó dáa ló máa fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Mátíù 7:7-11.

Jésù wá sọ ìlànà tó yẹ kí gbogbo wa fi máa bá ara wa lò, ó ní: “Torí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.” Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn míì? Ká sòótọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò, torí Jésù sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé, torí ẹnubodè tó lọ sí ìparun fẹ̀, ọ̀nà ibẹ̀ gbòòrò, àwọn tó ń gba ibẹ̀ wọlé sì pọ̀; nígbà tó jẹ́ pé, ẹnubodè tó lọ sí ìyè rí tóóró, ọ̀nà ibẹ̀ há, àwọn díẹ̀ ló sì ń rí i.”—Mátíù 7:12-14.

Àwọn kan máa fẹ́ mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè, torí náà Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tó ń wá sọ́dọ̀ yín nínú àwọ̀ àgùntàn, àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀yánnú ìkookò ni wọ́n ní inú.” (Mátíù 7:15) Jésù sọ pé èso tí igi kan ń so ló máa fi hàn bóyá igi rere ni tàbí búburú. Bó ṣe rí pẹ̀lú àwọn èèyàn náà nìyẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun táwọn wòlíì èké fi ń kọ́ni àti ìwà wọn làwọn èèyàn fi máa dá wọn mọ̀. Jésù sọ pé kì í ṣe ohun tẹ́nì kan sọ ló máa fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn òun ni, bí kò ṣe ohun tó ń ṣe. Àwọn kan lè máa pe Jésù ní Olúwa, àmọ́ tí wọ́n bá ń ṣe ohun tó ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run ńkọ́? Jésù sọ pé: “Màá sọ fún wọn pé: ‘Mi ò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin arúfin!’”—Mátíù 7:23.

Jésù wá fi gbólóhùn yìí parí ìwàásù rẹ̀, ó ní: “Gbogbo ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tó sì ṣe é máa dà bí ọkùnrin kan tó ní òye, tó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta. Òjò sì rọ̀, omi kún àkúnya, ìjì sì fẹ́ lu ilé náà, àmọ́ kò wó, torí pé orí àpáta ni ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà.” (Mátíù 7:24, 25) Kí ni ò jẹ́ kí ilé náà wó? Ohun náà ni pé ọkùnrin yẹn “walẹ̀ jìn, [ó] sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta.” (Lúùkù 6:48) Torí náà, ó kọjá ká kàn gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti “ṣe é.”

Kí ni Jésù sọ nípa ẹni “tó gbọ́ ọ̀rọ̀” rẹ̀ àmọ́ ‘tí kò ṣe é’? Ẹni náà “máa dà bí òmùgọ̀ ọkùnrin tó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn.” (Mátíù 7:26) Ó dájú pé òjò, àkúnya omi àti ìjì máa wó ilé náà.

Ohun tí Jésù bá àwọn èèyàn náà sọ yà wọ́n lẹ́nu gan-an torí ó kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ yẹn di ọmọ ẹ̀yìn.