Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 39

Jésù Dẹ́bi fún Ìran Aláìgbọràn

Jésù Dẹ́bi fún Ìran Aláìgbọràn

MÁTÍÙ 11:16-30 LÚÙKÙ 7:31-35

  • JÉSÙ DẸ́BI FÁWỌN ÌLÚ KAN

  • Ó ṢÈLÉRÍ PÉ ÒUN MÁA TU ÀWỌN ÈÈYÀN LÁRA

Jésù mọyì Jòhánù Arinibọmi gan-an, àmọ́ ojú wo lọ̀pọ̀ fi wo Jòhánù? Jésù sọ pé: “Ìran yìí . . . dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó nínú ọjà, tí wọ́n ń pe àwọn tí wọ́n jọ ń ṣeré, pé: ‘A fun fèrè fún yín, àmọ́ ẹ ò jó; a pohùn réré ẹkún, àmọ́ ẹ ò kẹ́dùn, kí ẹ sì lu ara yín.’”—Mátíù 11:16, 17.

Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Òun fúnra ẹ̀ ṣàlàyé nígbà tó sọ pé: “Jòhánù wá, kò jẹ, kò sì mu, àmọ́ àwọn èèyàn sọ pé, ‘Ẹlẹ́mìí èṣù ni.’ Ọmọ èèyàn wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu, àmọ́ àwọn èèyàn sọ pé, ‘Wò ó! Ọkùnrin alájẹkì, ti kò mọ̀ ju kó mu wáìnì lọ, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’” (Mátíù 11:18, 19) Lédè míì, ìgbé ayé àwọn Násírì ni Jòhánù gbé, kódà kì í mutí, síbẹ̀ àwọn èèyàn sọ pé ó ní ẹ̀mí èṣù. (Nọ́ńbà 6:2, 3; Lúùkù 1:15) Àmọ́ Jésù ní tiẹ̀ dà bí àwọn yòókù. Ó ń jẹun ó sì ń mu wáìnì níwọ̀nba, síbẹ̀ àwọn èèyàn sọ pé aláṣejù ni. Ó jọ pé kò sóhun téèyàn lè ṣe tó máa tẹ́ aráyé lọ́rùn.

Jésù fi ìran náà wé àwọn ọmọ kéékèèké tó wà nínú ọjà tí wọn ò jó nígbà táwọn ẹgbẹ́ wọn ń fun fèrè, tí wọn ò sì kẹ́dùn nígbà tí wọ́n pohùn réré ẹkún. Jésù wá sọ pé: “Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:16, 19) Ó ṣe kedere pé “àwọn iṣẹ́,” ìyẹn àwọn ohun tí Jòhánù àti Jésù ṣe fi hàn pé irọ́ làwọn èèyàn náà pa.

Lẹ́yìn tí Jésù pe ìran yẹn ní aláìgbọràn, ó dẹ́bi fún Kórásínì, Bẹtisáídà àti Kápánáúmù, ìyẹn àwọn ìlú tó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Jésù sọ pé tó bá jẹ́ Tírè àti Sídónì tó wà lágbègbè Foníṣíà lòun ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn ni, wọn ì bá ti ronú pìwà dà. Ó mẹ́nu kan Kápánáúmù torí pé ibẹ̀ ló wà fúngbà díẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ò gbà á gbọ́. Jésù wá sọ nípa ìlú náà pé: “Ilẹ̀ Sódómù máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù yín lọ.”—Mátíù 11:24.

Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù yin Baba rẹ̀ torí pé ó fi òtítọ́ tó ṣeyebíye pa mọ́ “fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye” àmọ́ ó ṣí i payá fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ tó fi wé ọmọ kékeré. (Mátíù 11:25) Ó sọ fáwọn onírẹ̀lẹ̀ yẹn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí, ara sì máa tù yín. Torí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.

Báwo ni Jésù ṣe ń tù wọ́n lára? Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn pẹ̀lú áwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn, àpẹẹrẹ kan ni òfin máṣu mátọ̀ tí wọ́n ṣe nípa Sábáàtì. Àmọ́ Jésù fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn èèyàn lára, kò sì ní àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ nínú. Ó tún pèsè ìtura fáwọn tí àwọn alákòóso ń ni lára àtàwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lọ́rùn. Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n máa ṣe kí Ọlọ́run lè dárí jì wọ́n, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Ọlọ́run.

Gbogbo àwọn tó bá gba àjàgà Jésù sọ́rùn wọn máa ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n á sì máa sin Baba wa ọ̀run tó jẹ́ aláàánú, tó sì ń gba tẹni rò. Àjàgà Jésù kì í wọni lọ́rùn torí pé àwọn òfin Jèhófà ò nira.—1 Jòhánù 5:3.