Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 49

Ó Wàásù, Ó Sì Dá Àwọn Àpọ́sítélì Lẹ́kọ̀ọ́ ní Gálílì

Ó Wàásù, Ó Sì Dá Àwọn Àpọ́sítélì Lẹ́kọ̀ọ́ ní Gálílì

MÁTÍÙ 9:35–10:15 MÁÀKÙ 6:6-11 LÚÙKÙ 9:1-5

  • JÉSÙ PA DÀ LỌ WÀÁSÙ NÍ GÁLÍLÌ

  • Ó RÁN ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ RẸ̀ JÁDE LỌ WÀÁSÙ

Odindi ọdún méjì ni Jésù ti ń fìtara wàásù báyìí. Ṣé ó wá ronú pé kóun sinmi kóun sì máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Jésù mú kí iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ gbòòrò sí i nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í “lọ káàkiri gbogbo ìlú àti abúlé [ní Gálílì], ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ó sì ń wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn.” (Mátíù 9:35) Ohun tí Jésù rí mú kó túbọ̀ pinnu pé òun á mú kí iṣẹ́ ìwàásù òun gbòòrò sí i. Àmọ́ báwo ló ṣe máa ṣe é?

Bí Jésù ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì, ó rí i pé àwọn èèyàn nílò ìwòsàn nípa tẹ̀mí, kódà wọ́n nílò ìtùnú. Ìdí sì ni pé wọ́n dà bí àgùntàn tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká. Àánú àwọn èèyàn náà ṣe Jésù, ó wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Òótọ́ ni, ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan. Torí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde láti bá a kórè.”—Mátíù 9:37, 38.

Jésù mọ ohun táwọn èèyàn náà nílò. Torí náà ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá (12), ó sì pín wọn ní méjì-méjì. Ó wá fún wọn ní ìtọ́ni tó ṣe kedere, ó ní: “Ẹ má lọ sí ojú ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ má sì wọ ìlú Samáríà kankan; kàkà bẹ́ẹ̀, léraléra ni kí ẹ máa lọ sọ́dọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù. Bí ẹ ṣe ń lọ, ẹ máa wàásù pé: ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’”—Mátíù 10:5-7.

Ìjọba táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa wàásù rẹ̀ ni Ìjọba tí Jésù mẹ́nu bà nínú àdúrà àwòkọ́ṣe. Àmọ́ kí ló ní lọ́kàn nígbà tó ní kí wọ́n wàásù pé ‘Ìjọba yẹn ti sún mọ́lé’? Ohun tó ń sọ ni pé òun Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba tí Ọlọ́run yàn wà láàárín wọn. Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe máa fi hàn pé àwọn ń ṣojú fún Ìjọba náà? Jésù fún wọn lágbára láti wo àwọn aláìsàn sàn àti láti jí òkú dìde láìgba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Àmọ́, báwo làwọn àpọ́sítélì yẹn ṣe máa bójú tó ara wọn tí wọ́n á sì máa rí oúnjẹ jẹ?

Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe di ẹrù kankan fún ìrìn àjò náà. Ó ní kí wọ́n má ṣe mú wúrà, fàdákà tàbí bàbà sínú àpò wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò nílò àpò oúnjẹ, aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ tàbí bàtà fún ìrìn àjò náà. Kí nìdí? Jésù sọ fun wọn pé: “Oúnjẹ tọ́ sí òṣìṣẹ́.” (Mátíù 10:10) Ìyẹn túmọ̀ sí pé àwọn tó bá mọyì ìhìn rere náà máa pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún wọn. Jésù wá sọ pé: “Ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ilé kan, kí ẹ dúró síbẹ̀ títí ẹ máa fi kúrò níbẹ̀.”—Máàkù 6:10.

Jésù tún fún wọn ní ìtọ́ni nípa ohun tó yẹ kí wọ́n sọ tí wọ́n bá dé ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n fẹ́ wàásù fún, ó ní: “Tí ẹ bá wọ ilé kan, ẹ kí àwọn ará ilé náà. Tí ilé náà bá yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀; àmọ́ tí kò bá yẹ, kí àlàáfíà látọ̀dọ̀ yín pa dà sọ́dọ̀ yín. Ibikíbi tí ẹnikẹ́ni ò bá ti gbà yín tàbí fetí sí ọ̀rọ̀ yín, tí ẹ bá ń kúrò ní ilé yẹn tàbí ìlú yẹn, ẹ gbọn iyẹ̀pẹ̀ ẹsẹ̀ yín dà nù.”—Mátíù 10:12-14.

Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé odindi ìlú tàbí abúlé ló kọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere náà ńkọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí irú ìlú bẹ́ẹ̀? Jésù sọ pé ìdájọ́ tó le gan-an ni wọ́n máa gbà. Ó ní: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ilẹ̀ Sódómù àti Gòmórà máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ ju ìlú yẹn lọ.”—Mátíù 10:15.