Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 53

Alákòóso Kan Tó Láṣẹ Lórí Àwọn Nǹkan Àdáyébá

Alákòóso Kan Tó Láṣẹ Lórí Àwọn Nǹkan Àdáyébá

MÁTÍÙ 14:22-36 MÁÀKÙ 6:45-56 JÒHÁNÙ 6:14-25

  • ÀWỌN ÈÈYÀN FẸ́ FI JÉSÙ JỌBA

  • JÉSÙ RÌN LÓRÍ OMI, Ó SÌ MÚ KÍ ÌJÌ DÁWỌ́ DÚRÓ

Bí Jésù ṣe bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ya ọ̀pọ̀ lẹ́nu. Torí náà, wọ́n ń sọ pé “ó dájú pé Wòlíì tí wọ́n ní ó máa wá sí ayé nìyí” ìyẹn Mèsáyà, ó sì máa jẹ́ alákòóso tó dáa. (Jòhánù 6:14; Diutarónómì 18:18) Torí náà, àwọn èèyàn yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n á ṣe mú un, tí wọ́n á sì fi jọba.

Àmọ́ Jésù mọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Torí náà, ó ní káwọn èèyàn náà máa lọ, ó sì ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wọnú ọkọ̀. Ibo ni wọ́n wá ń lọ báyìí? Wọ́n ń lọ sọ́nà Bẹtisáídà, lẹ́yìn náà wọ́n á lọ sí Kápánáúmù. Àmọ́ Jésù dá lọ sórí òkè kan láti lọ gbàdúrà lálẹ́ ọjọ́ yẹn.

Nígbà tó kù díẹ̀ kí ilẹ̀ mọ́, Jésù rí ọkọ̀ táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wọ̀ láti ibi tó wà. Ìgbì òkun le gan-an débi pé ṣe ni wọ́n ń “tiraka láti tukọ̀, torí atẹ́gùn ń dà wọ́n láàmú.” (Máàkù 6:48) Jésù wá sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè yẹn, ó sì ń rìn lórí omi tó ń ru gùdù náà lọ sọ́dọ̀ wọn. “Wọ́n ti tukọ̀ tó nǹkan bíi máìlì mẹ́ta sí mẹ́rin” nígbà yẹn. (Jòhánù 6:19) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí i pé Jésù fẹ́ gba ẹ̀gbẹ́ àwọn kọjá, ni wọ́n bá kígbe pé: “Ìran abàmì ni!”—Máàkù 6:49.

Jésù wá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹ mọ́kàn le! Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” Àmọ́ Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ ìwọ ni, pàṣẹ fún mi pé kí n wá bá ọ lórí omi.” Jésù sọ fún un pé: “Máa bọ̀!” Ni Pétérù bá bọ́lẹ̀ látinú ọkọ̀, ó wá ń rìn lórí omi lọ bá Jésù. Àmọ́ ẹ̀rù bà á nígbà tó ń wo ìjì náà, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ló bá figbe ta pé: “Olúwa, gbà mí là!” Jésù wá na ọwọ́ rẹ̀, ó sì di Pétérù mú, ó wá sọ fún un pé: “Ìwọ tí ìgbàgbọ́ rẹ kéré, kí ló dé tí o fi ṣiyèméjì?”—Mátíù 14:27-31.

Lẹ́yìn náà, Pétérù àti Jésù wọnú ọkọ̀, ìjì náà sì dáwọ́ dúró. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́nu gan-an, àmọ́ ṣé ó yẹ kó yà wọ́n lẹ́nu? Ká sọ pé wọ́n “mọ ohun tí búrẹ́dì náà túmọ̀ sí,” ìyẹn bí Jésù ṣe bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní wákàtí mélòó kan ṣáájú àsìkò yẹn, kò yẹ kó yà wọ́n lẹ́nu pé ó ń rìn lórí omi àti pé ó dá ìjì dúró. Torí náà, wọ́n tẹrí ba fún un, wọ́n sì sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ọ́ lóòótọ́.”—Máàkù 6:52; Mátíù 14:33.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sárẹ́tì ní apá gúúsù ìlú Kápánáúmù. Wọ́n mú kí ọkọ̀ náà gúnlẹ̀, wọ́n sì lọ sí èbúté. Àwọn tó wà níbẹ̀ dá Jésù mọ̀, ni gbogbo wọn títí kan àwọn ará ìlú tó wà ní àyíká ibẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Bí gbogbo wọn ṣe ń fọwọ́ kan etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lara wọn ń yá.

Lákòókò yìí kan náà, àwọn èèyàn tó wà níbi tí Jésù ti bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn kíyè sí i pé Jésù ti lọ. Torí náà, nígbà táwọn ọkọ̀ ojú omi láti Tìbéríà dé ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n wọ ọkọ̀ lọ sí Kápánáúmù kí wọ́n lè lọ wá Jésù. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n bi í pé: “Rábì, ìgbà wo lo débí?” (Jòhánù 6:25) Àmọ́ Jésù bá wọn wí, ó sì nídìí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ bá a ṣe máa rí i nínú orí tó kàn.