Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 74

Ẹ̀kọ́ Nípa Aájò Àlejò àti Àdúrà

Ẹ̀kọ́ Nípa Aájò Àlejò àti Àdúrà

LÚÙKÙ 10:38–11:13

  • JÉSÙ LỌ KÍ MÀTÁ ÀTI MÀRÍÀ NÍLÉ

  • Ó ṢE PÀTÀKÌ KÉÈYÀN MÁA GBÀDÚRÀ LÉRALÉRA

Abúlé kan wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìlà oòrùn Òkè Ólífì, kò ju nǹkan bíi máìlì méjì sí Jerúsálẹ́mù, Bẹ́tánì lorúkọ ibẹ̀. (Jòhánù 11:18) Jésù rìnrìn àjò lọ síbẹ̀, ó sì dé sílé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan tí wọ́n ń jẹ́ Màtá àti Màríà. Ọ̀rẹ́ Jésù làwọn méjèèjì àti Lásárù arákùnrin wọn, inú wọn sì dùn gan-an láti gba Jésù lálejò.

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wọn láti gba Mèsáyà lálejò. Ara Màtá ti wà lọ́nà láti tọ́jú Jésù, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í filé pọntí fọ̀nà rokà kó lè ṣètò àsè rẹpẹtẹ fún un. Bí Màtá ṣe ń ṣe gbogbo ìyẹn, ṣe ni Màríà ní tiẹ̀ jókòó síbi ẹsẹ̀ Jésù tó sì ń fetí sí ohun tó ń sọ. Nígbà tó yá, Màtá sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ṣé o ò rí i bí arábìnrin mi ṣe fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan ni? Sọ fún un pé kó wá ràn mí lọ́wọ́.”—Lúùkù 10:40.

Dípò kí Jésù bá Màríà wí, ṣe ló fún Màtá nímọ̀ràn pé kó má ṣàníyàn jù nípa àwọn nǹkan tara, ó ní: “Màtá, Màtá, ò ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa nǹkan tó pọ̀. Nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo la nílò. Màríà ní tiẹ̀, yan ìpín rere, a ò sì ní gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 10:41, 42) Jésù jẹ́ kí Màtá rí i pé kò pọn dandan kó se oúnjẹ tó pọ̀. Ó jẹ́ kó mọ̀ pé oúnjẹ díẹ̀ làwọn nílò.

Ohun tó dáa ni Màtá ní lọ́kàn láti ṣe, ó fẹ́ ṣe Jésù lálejò ni. Àmọ́ bó ṣe ń ṣàníyàn jù nípa iná tó fẹ́ dá, ó ti ń pàdánù ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù Ọmọ Ọlọ́run ń kọ́ wọn. Jésù jẹ́ ká rí i pé ohun tó dáa jù ni Màríà ṣe ní tiẹ̀, ìpinnu tó ṣe yẹn sì ṣe é láǹfààní. Àwa náà lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn.

Lásìkò míì, Jésù tún kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe máa gbàdúrà, bí Jòhánù náà ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.” (Lúùkù 11:1) Jésù ti kọ́ wọn tẹ́lẹ̀ ní nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ sẹ́yìn nínú Ìwàásù Lórí Òkè. (Mátíù 6:9-13) Àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ọmọ ẹ̀yìn tó béèrè ìbéèrè yẹn má sí níbẹ̀ nígbà yẹn, torí náà Jésù tún sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó tó ti kọ́ wọn tẹ́lẹ̀. Ó wá sọ àpèjúwe kan fún wọn kí wọ́n lè mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì kí wọ́n máa gbàdúrà léraléra.

Ó sọ pé: “Ká sọ pé ọ̀kan nínú yín ní ọ̀rẹ́ kan, o wá lọ bá a ní ọ̀gànjọ́ òru, o sì sọ fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní búrẹ́dì mẹ́ta, torí pé ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sọ́dọ̀ mi láti ìrìn àjò, mi ò sì ní nǹkan kan tí mo lè fún un.’ Àmọ́ ẹni yẹn fèsì látinú ilé, ó ní: ‘Yéé dà mí láàmú. Mo ti ti ilẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi kéékèèké sì wà lọ́dọ̀ mi lórí ibùsùn. Mi ò lè dìde wá fún ọ ní ohunkóhun.’ Mò ń sọ fún yín, bí kò bá tiẹ̀ ní dìde, kó sì fún un ní nǹkan kan torí pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó dájú pé torí pé ó ń fi ìgboyà béèrè léraléra, ó máa dìde, ó sì máa fún un ní ohunkóhun tó bá nílò.”—Lúùkù 11:5-8.

Jésù ò sọ pé Jèhófà ń lọ́ra láti dáhùn àdúrà wa bíi ti ọ̀rẹ́ inú àpèjúwe yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé tí ọ̀rẹ́ wa kan tó ń lọ́ra láti fún wa ní ohun kan bá pa dà fún wa nítorí pé à ń béèrè léraléra, ó dájú pé Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa máa dáhùn àdúrà tí àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ bá gbà sí i tọkàntọkàn! Jésù wá sọ pé: “Mò ń sọ fún yín, ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín. Torí gbogbo ẹni tó bá ń béèrè máa rí gbà, gbogbo ẹni tó bá ń wá kiri máa rí, gbogbo ẹni tó bá sì ń kan ilẹ̀kùn la máa ṣí i fún.”—Lúùkù 11:9, 10.

Kí Jésù lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tó ń sọ túbọ̀ yé wọn, ó fi Jèhófà wé bàbá kan, ó sọ pé: “Bàbá wo ló wà láàárín yín tó jẹ́ pé, tí ọmọ rẹ̀ bá béèrè ẹja, ó máa fún un ní ejò dípò ẹja? Tàbí tó bá tún béèrè ẹyin, tó máa fún un ní àkekèé? Torí náà, tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn tó dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín, mélòómélòó wá ni Baba yín tó wà ní ọ̀run, ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:11-13) Inú wa dùn láti mọ̀ pé Baba wa ọ̀run ṣe tán láti gbọ́ àdúrà wa kó sì tún fún wa láwọn ohun tá a nílò!