Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 75

Jésù Sọ Ohun Tó Ń Fúnni Láyọ̀

Jésù Sọ Ohun Tó Ń Fúnni Láyọ̀

LÚÙKÙ 11:14-36

  • JÉSÙ FI “ÌKA ỌLỌ́RUN” LÉ ÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ JÁDE

  • OHUN TÓ Ń FÚNNI NÍ AYỌ̀ TÒÓTỌ́

Jésù ti sọ̀rọ̀ nípa àdúrà tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó tún sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Kì í sì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tó máa ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn kókó míì tó ti sọ tẹ́lẹ̀. Nígbà tó ṣe iṣẹ́ ìyanu kan ní Gálílì, àwọn èèyàn fẹ̀sùn kàn án pé agbára alákòóso ẹ̀mí èṣù ló fi ṣe iṣẹ́ ìyanu náà. Nígbà tó dé Jùdíà, ẹ̀sùn yẹn ni wọ́n tún fi kàn án.

Nígbà tí Jésù lé ẹ̀mí èṣù tí kò jẹ́ kí ọkùnrin kan lè sọ̀rọ̀ jáde, ẹnu ya àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀. Àmọ́ kò jọ àwọn alátakò rẹ̀ lójú rárá. Ṣe ni wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kàn án pé: “Agbára Béélísébúbù, alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù, ló fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” (Lúùkù 11:15) Àwọn kan lára wọn ń fẹ́ kí Jésù fún wọn ní ẹ̀rí sí i kí wọ́n lè gbà pé òun ni Mèsáyà, torí náà wọ́n ní kó fún àwọn ní àmì kan láti ọ̀run.

Jésù mọ̀ pé wọ́n kàn fẹ́ dán òun wò ni, ló bá fún wọn nírú èsì tó fún àwọn tó ta kò ó ní Gálílì. Ó sọ pé gbogbo ìjọba tó bá pínyà sí ara rẹ̀ máa pa run, tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, “Tí Sátánì náà bá pínyà sí ara rẹ̀, báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe máa dúró?” Jésù wá sọ fún wọn ní tààràtà pé: “Tó bá jẹ́ ìka Ọlọ́run ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, Ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín lójijì lóòótọ́.”—Lúùkù 11:18-20.

Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù sọ nípa “ìka Ọlọ́run” rán àwọn olùgbọ́ rẹ̀ létí ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyé àtijọ́. Iṣẹ́ ìyanu tí Mósè ṣe láàfin Fáráò ya àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́nu, torí náà wọ́n sọ pé: “Ìka Ọlọ́run nìyí!” Bákan náà, “ìka Ọlọ́run” yìí ló kọ Òfin Mẹ́wàá sára àwọn wàláà òkúta méjì. (Ẹ́kísódù 8:19; 31:18) “Ìka Ọlọ́run” yìí kan náà, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ tàbí agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ló mú kó ṣeé ṣe fún Jésù láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, kó sì wo àwọn aláìsàn sàn. Torí náà, Ìjọba Ọlọ́run ti dé bá àwọn alátakò yẹn lójijì lóòótọ́, torí pé Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba náà ló ń ṣe iṣẹ́ ìyanu táwọn èèyàn náà rí.

Bí Jésù ṣe lágbára láti lé ẹ̀mí èṣù jáde jẹ́ ẹ̀rí pé ó lágbára ju Sátánì lọ, ṣe ló dà bí ìgbà tí ọkùnrin alágbára kan kápá ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ ààfin kan, tó sì borí rẹ̀. Jésù wá lo àpèjúwe ẹ̀mí àìmọ́ tó jáde lára ọkùnrin kan. Tí ọkùnrin náà ò bá fi ohun tó dáa kún àyè tó ṣí sílẹ̀, ẹ̀mí yẹn máa pa dà, á sì tún mú ẹ̀mí méje míì dání, ìyẹn á wá mú kí ipò ọkùnrin náà burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. (Mátíù 12:22, 25-29, 43-45) Bí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe rí nìyẹn.

Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ya obìnrin kan lẹ́nu, ló bá sọ pé: “Aláyọ̀ ni ilé ọlẹ̀ tó gbé ọ àti ọmú tí o mu!” Ó máa ń wu àwọn obìnrin Júù láti jẹ́ ìyá wòlíì, pàápàá tó bá lọ jẹ́ Mèsáyà. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí obìnrin yìí máa ronú pé inú Màríà á máa dùn bó ṣe jẹ́ pé òun ló bí irú olùkọ́ yìí. Àmọ́ èrò yẹn ò tọ̀nà, Jésù jẹ́ kó mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!” (Lúùkù 11:27, 28) Jésù ò fìgbà kan rí sọ pé káwọn èèyàn máa bọlá fún Màríà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn la máa tó ní ayọ̀ tòótọ́, kì í ṣe torí pé a tan mọ́ ẹnì kan tàbí torí àṣeyọrí tá a ṣe.

Jésù bá àwọn èèyàn náà wí nígbà tí wọ́n béèrè fún àmì kan láti ọ̀run, bó sì ṣe bá àwọn ará Gálílì wí nìyẹn nígbà tí wọ́n béèrè fún ohun kan náà. Ó sọ fún wọn pé òun ò ní fún wọn ní àmì kankan àfi “àmì Jónà.” Ọ̀nà méjì ni Jónà gbà jẹ́ àmì. Lákọ̀ọ́kọ́, ó wà nínú ikùn ẹja fún ọjọ́ mẹ́ta, ó tún fìgboyà kéde ìdájọ́ Ọlọ́run fún àwọn ará ìlú Nínéfè, ìyẹn sì mú kí wọ́n ronú pìwà dà. Jésù wá sọ pé: “Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Jónà lọ wà níbí.” (Lúùkù 11:29-32) Jésù tún ju Sólómọ́nì lọ, ìyẹn ẹni tí ọbabìnrin Ṣébà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ̀.

Jésù fi kún un pé: “Tí ẹnì kan bá tan fìtílà, kò ní gbé e síbi tó fara pa mọ́ tàbí sábẹ́ apẹ̀rẹ̀, àmọ́ orí ọ̀pá fìtílà ló máa gbé e sí.” (Lúùkù 11:33) Ohun tó ṣeé ṣe kí Jésù ní lọ́kàn ni pé bí òun ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn yìí tóun sì ń ṣe iṣẹ́ ìyanu dà bí ìgbà téèyàn tan fìtílà tó wá gbé e pa mọ́. Torí pé ọ̀tọ̀ nibi tọ́kàn àwọn èèyàn náà wà, wọn ò lóye ìdí tí Jésù fi ń ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣe.

Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ọkùnrin kan ni, ìyẹn sì mú kí ọkùnrin tí kò lè sọ̀rọ̀ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Ó yẹ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú káwọn èèyàn fògo fún Jèhófà kí wọ́n sì máa ròyìn ohun tí Jésù ń ṣe fáwọn míì. Àmọ́ Jésù kìlọ̀ fáwọn tó ń ta kò ó, ó ní: “Torí náà, wà lójúfò, kí ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ má bàa jẹ́ òkùnkùn. Nítorí náà, tí gbogbo ara rẹ bá mọ́lẹ̀ yòò, tí kò sí apá kankan níbẹ̀ tó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ máa mọ́lẹ̀ yòò bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànṣán rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ.”—Lúùkù 11:35, 36.