Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 78

Jésù Ní Kí Ìríjú Olóòótọ́ Náà Múra Sílẹ̀

Jésù Ní Kí Ìríjú Olóòótọ́ Náà Múra Sílẹ̀

LÚÙKÙ 12:35-59

  • ÌRÍJÚ OLÓÒÓTỌ́ NÁÀ GBỌ́DỌ̀ MÚRA SÍLẸ̀

  • JÉSÙ WÁ KÓ LÈ FA ÌPINYÀ

Jésù ṣàlàyé pé “agbo kékeré” nìkan ló máa wọ Ìjọba ọ̀run. (Lúùkù 12:32) Àmọ́ ó yẹ kẹ́ni tó bá máa nírú àǹfààní yìí fọwọ́ pàtàkì mú un. Kódà, Jésù tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì kí ẹnì kan ní èrò tó tọ́ tó bá fẹ́ wà nínú Ìjọba náà.

Torí náà, Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n múra sílẹ̀ dìgbà tóun máa pa dà dé. Ó sọ pé: “Ẹ múra, kí ẹ sì wà ní sẹpẹ́, kí ẹ jẹ́ kí àwọn fìtílà yín máa jó, kí ẹ sì dà bí àwọn ọkùnrin tó ń dúró de ọ̀gá wọn pé kó pa dà dé láti ibi ìgbéyàwó, kó lè jẹ́ pé tó bá dé, tó sì kan ilẹ̀kùn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n á ṣílẹ̀kùn fún un. Aláyọ̀ ni àwọn ẹrú tí ọ̀gá náà rí i pé wọ́n ń ṣọ́nà nígbà tó dé!”—Lúùkù 12:35-37.

Ó dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn máa lóye àpèjúwe tí Jésù ṣe. Àwọn ẹrú tó sọ̀rọ̀ nípa wọn wà ní sẹpẹ́, wọ́n sì ń dúró de ọ̀gá wọn títí tó fi máa dé. Jésù wá sọ pé: Tí ọ̀gá náà “bá sì dé ní ìṣọ́ kejì [ìyẹn láti nǹkan bí aago mẹ́sàn-án alẹ́ sí ọ̀gànjọ́ òru], kódà kó jẹ́ ìkẹta [láti ọ̀gànjọ́ òru sí nǹkan bí aago mẹ́ta àárọ̀], tó sì rí i pé wọ́n wà ní sẹpẹ́, aláyọ̀ ni wọ́n!”—Lúùkù 12:38.

Ìmọ̀ràn yìí kọjá kí ẹrú kan mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́ tàbí kó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára. Èyí ṣe kedere nígbà tí Jésù tó jẹ́ Ọmọ èèyàn jẹ́ kí wọ́n rí bí àpèjúwe náà ṣe kan òun fúnra rẹ̀. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ẹ̀yin náà, ẹ múra sílẹ̀, torí pé wákàtí tí ẹ ò rò pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀.” (Lúùkù 12:40) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, òun máa pa dà wá lọ́jọ́ ìwájú. Torí náà, ó fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun múra sílẹ̀, pàápàá jù lọ àwọn “agbo kékeré.”

Pétérù fẹ́ kí ọ̀rọ̀ Jésù yé òun dáadáa, torí náà ó bi í pé: “Olúwa, ṣé àwa nìkan lò ń sọ àpèjúwe yìí fún àbí gbogbo èèyàn?” Dípò kí Jésù dáhùn ìbéèrè Pétérù ní tààràtà, ṣe ló fi àpèjúwe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó ní: “Ní tòótọ́, ta ni ìríjú olóòótọ́ náà, tó jẹ́ olóye, tí ọ̀gá rẹ̀ máa yàn pé kó bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kó máa fún wọn ní ìwọ̀n oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ? Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn tí ọ̀gá rẹ̀ bá dé, tó sì rí i tó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Mò ń sọ fún yín ní tòótọ́, ó máa yàn án pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀.”—Lúùkù 12:41-44.

Nínú àpèjúwe àkọ́kọ́, ó dájú pé Jésù tó jẹ́ Ọmọ èèyàn ni “ọ̀gá náà” dúró fún. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé “ìríjú olóòótọ́ náà” máa jẹ́ díẹ̀ lára àwọn “agbo kékeré” tí Ọlọ́run máa fún ní Ìjọba náà. (Lúùkù 12:32) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn kan lára agbo kékeré yìí á máa fún “àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀” ní “ìwọ̀n oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ.” Torí náà, Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù, ìyẹn àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ń gba ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ Jésù máa gbà pé Jésù tó jẹ́ Ọmọ èèyàn ṣì máa pa dà wá lọ́jọ́ iwájú. Tó bá sì dìgbà yẹn, Jésù tó jẹ́ Ọ̀gá náà máa ṣètò bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn “àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀” á ṣe máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí.

Jésù tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wà lójúfò kí wọ́n sì máa kíyè sára. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tí wọn ò bá ṣọ́ra, wọ́n lè dẹra nù kí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ̀yìn síra wọn, ó ní: “Àmọ́ tí ẹrú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi ò tètè dé,’ tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, tó ń jẹ, tó ń mu, tó sì mutí yó, ọ̀gá ẹrú yẹn máa dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀ àti wákàtí tí kò mọ̀, ó máa fi ìyà tó le jù lọ jẹ ẹ́, ó sì máa kà á mọ́ àwọn aláìṣòótọ́.”—Lúùkù 12:45, 46.

Jésù sọ pé òun wá “láti dá iná kan ní ayé.” Àti pé ọ̀rọ̀ òun máa fa èdèkòyédè tó lágbára láàárín àwọn èèyàn, ìyẹn sì máa fòpin sí ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Kódà, ó máa le débi pé àwọn èèyàn tó yẹ kí wọ́n wà níṣọ̀kan máa kẹ̀yìn síra wọn, ìpínyà á wà láàárín “bàbá sí ọmọkùnrin àti ọmọkùnrin sí bàbá, ìyá sí ọmọbìnrin àti ọmọbìnrin sí ìyá, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ rẹ̀ àti ìyàwó sí ìyá ọkọ rẹ̀.”—Lúùkù 12:49, 53.

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn gan-an ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀. Ó wá yíjú sáwọn tó wà níbẹ̀. Ó ṣe tán, ṣáájú ìgbà yẹn lèyí tó pọ̀ jù lára wọn ò ti gbà pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá rí i tí ojú ọ̀run ṣú ní ìwọ̀ oòrùn, kíá lẹ máa sọ pé, ‘Ìjì ń bọ̀,’ ó sì máa ń rí bẹ́ẹ̀. Tí ẹ bá sì rí i pé atẹ́gùn ń fẹ́ láti gúúsù, ẹ máa sọ pé, ‘Ooru máa mú,’ ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ẹ̀yin alágàbàgebè, ẹ mọ bí wọ́n ṣe ń ṣàyẹ̀wò bí ayé àti òfúrufú ṣe rí, àmọ́ kí nìdí tí ẹ ò fi mọ bí ẹ ṣe máa ṣàyẹ̀wò àkókò yìí gan-an?” (Lúùkù 12:54-56) Ká sòótọ́, àwọn èèyàn yẹn ò múra sílẹ̀.