Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 90

“Àjíǹde àti Ìyè”

“Àjíǹde àti Ìyè”

JÒHÁNÙ 11:17-37

  • JÉSÙ DÉ LẸ́YÌN TÍ LÁSÁRÙ KÚ

  • “ÀJÍǸDE ÀTI ÌYÈ”

Bí Jésù ṣe ń bọ̀ láti Pèríà, ó dé sítòsí Bẹ́tánì, abúlé kan tó wà ní nǹkan bíi máìlì méjì sí ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù. Màríà àti Màtá ń sunkún torí pé Lásárù arákùnrin wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ kú ni, àwọn èèyàn sì ń wá láti tù wọ́n nínú.

Ẹnì kan wá sọ fún Màtá pé Jésù ti ń bọ̀, ni Màtá bá sáré lọ pàdé rẹ̀. Nígbà tí Màtá rí Jésù, ó sọ fún un pé: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tóun àti àbúrò ẹ̀ ti jọ ń sọ láti ọjọ́ mẹ́rin nìyẹn. Àmọ́ kì í ṣe pé ó ti sọ̀rètí nù, torí ó sọ pé: “Mo ṣì mọ̀ pé ohunkóhun tí o bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run máa fún ọ.” (Jòhánù 11:21, 22) Ó mọ̀ pé Jésù ṣì lè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà.

Jésù wá sọ pé: “Arákùnrin rẹ máa dìde.” Màtá rò pé ọ̀rọ̀ àjíǹde tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni Jésù ń sọ, nígbà tí Ábúráhámù àtàwọn míì máa jíǹde. Ohun tí Màtá sọ fi hàn pé ọ̀rọ̀ àjíǹde yẹn dá a lójú, ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé ó máa dìde nígbà àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”—Jòhánù 11:23, 24.

Síbẹ̀, ṣé ó ṣeé ṣe kí Jésù ṣe ohun tó máa mára tù wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Jésù rán Màtá létí pé Ọlọ́run ti fún òun lágbára lórí ikú, ó ní: “Ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, tó bá tiẹ̀ kú, ó máa yè; gbogbo ẹni tó bá wà láàyè, tó sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi kò ní kú láé.”—Jòhánù 11:25, 26.

Jésù ò sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò ní kú. Kódà, òun fúnra ẹ̀ gan-an ṣì máa kú, bó ṣe sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 16:21; 17:22, 23) Àmọ́, ohun tó ń sọ ni pé ẹni tó bá gba òun gbọ́ máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kú, ó dìgbà tí wọ́n bá jíǹde kí wọ́n tó lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn olóòótọ́ tó bá ṣì wà láàyè ní àkókò òpin má kú rárá. Èyí ó wù kó jẹ́, ó dájú pé gbogbo ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, bí wọ́n tiẹ̀ kú, wọ́n á jíǹde.

Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún wọn pé òun “ni àjíǹde àti ìyè.” Àmọ́, ṣé á lè jí Lásárù tó ti kú láti ọjọ́ mẹ́rin dìde? Jésù bi Màtá pé: “Ṣé o gba èyí gbọ́?” Màtá dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, mo ti gbà gbọ́ pé ìwọ ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tó ń bọ̀ wá sí ayé.” Màtá gbà pé Jésù máa ṣe nǹkan kan lọ́jọ́ yẹn, ló bá sáré lọ sílé lọ bá àbúrò rẹ̀, ó sì rọra sọ fún un pé: “Olùkọ́ ti dé, ó ń pè ọ́.” (Jòhánù 11:25-28) Torí náà, Màríà kúrò nílé, àmọ́ àwọn èèyàn tẹ̀ lé e torí wọ́n rò pé ibi tí wọ́n sin Lásárù sí ló ń lọ.

Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jésù ni Màríà lọ, ó kúnlẹ̀ síwájú Jésù, ó sì ń sunkún. Ọ̀rọ̀ tí ẹ̀gbọ́n ẹ̀ sọ lẹ́ẹ̀kan lòun náà sọ, ó ní: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” Bí Jésù ṣe rí i tí Màríà àtàwọn èèyàn ń sunkún, ó dun òun náà, ó banú jẹ́, omi sì bọ́ lójú ẹ̀. Ohun tó ṣe yẹn ya àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́nu. Àmọ́ àwọn kan ń sọ pé: ‘Tí Jésù bá lè la ojú ọkùnrin tí wọ́n bí ní afọ́jú, ṣé kò lè ṣe é kí ọkùnrin yìí má kú ni?’—Jòhánù 11:32, 37.