Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 97

Àpèjúwe Àwọn Òṣìṣẹ́ Ọgbà Àjàrà

Àpèjúwe Àwọn Òṣìṣẹ́ Ọgbà Àjàrà

MÁTÍÙ 20:1-16

  • ÀWỌN TÓ DÉ ‘KẸ́YÌN’ MÁA DI “ẸNI ÀKỌ́KỌ́”

Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀ ní Pèríà pé “ọ̀pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ máa di ẹni ìkẹyìn, àwọn ẹni ìkẹyìn sì máa di ẹni àkọ́kọ́.” (Mátíù 19:30) Kí ohun tó ń sọ lè túbọ̀ yé wọn, ó sọ àpèjúwe kan nípa àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà àjàrà, ó ní:

“Ìjọba ọ̀run dà bíi baálé ilé kan tó jáde lọ ní àárọ̀ kùtù láti gba àwọn òṣìṣẹ́ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. Lẹ́yìn tó bá àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣàdéhùn pé òun máa fún wọn ní owó dínárì kan fún ọjọ́ kan, ó ní kí wọ́n lọ sínú ọgbà àjàrà òun. Ó tún jáde ní nǹkan bíi wákàtí kẹta, ó sì rí àwọn míì tí wọ́n dúró ní ibi ọjà, tí wọn ò ríṣẹ́ ṣe; ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà, màá sì fún yín ní ohunkóhun tó bá tọ́.’ Torí náà, wọ́n lọ. Ó tún jáde ní nǹkan bíi wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsàn-án, ó sì ṣe ohun kan náà. Níkẹyìn, ní nǹkan bíi wákàtí kọkànlá, ó jáde lọ, ó sì rí àwọn míì tí wọ́n dúró, ó sọ fún wọn pé, ‘Kí ló dé tí ẹ dúró síbí látàárọ̀, tí ẹ ò ríṣẹ́ ṣe?’ Wọ́n sọ fún un pé, ‘Torí kò sẹ́ni tó gbà wá síṣẹ́ ni.’ Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà.’”—Mátíù 20:1-7.

Ó ṣeé ṣe káwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù ronú kan Jèhófà Ọlọ́run nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “Ìjọba ọ̀run” àti “baálé ilé kan.” Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló ni ọgbà àjàrà yẹn, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló sì dúró fún ọgbà àjàra náà. (Sáàmù 80:8, 9; Àìsáyà 5:3, 4) Àwọn tó wà nínú Májẹ̀mú Òfin ni Ìwé Mímọ́ fi wé òṣìṣẹ́ ọgbà àjàrà. Àmọ́, àwọn kọ́ ni àpèjúwe Jésù yìí bá wí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó wà láyé lásìkò tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló ń sọ.

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbà pé àwọn ń ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run láìdáwọ́ dúró, irú bí àwọn Farisí tó wá dán Jésù wò láìpẹ́ sígbà yẹn lórí ọ̀rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀. Àwọn ló dà bí àwọn òṣìṣẹ́ tó ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ tí wọ́n sì ń retí àtigba dínárì kan tó jẹ́ owó táwọn òṣìṣẹ́ máa ń gbà lójúmọ́.

Àwọn àlùfáà àtàwọn míì bíi tiwọn gbà pé àwọn yòókù ò ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run tó àwọn, pé wákàtí mélòó kan péré ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà Ọlọ́run dípò kí wọ́n ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Nínú àpèjúwe Jésù, àwọn Júù tó kù yẹn ni Jésù fi wé àwọn ọkùnrin tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ “ní nǹkan bíi wákàtí kẹta” (9:00 àárọ̀) tàbí wákàtí kẹfà, wákàtí kẹsàn-án àti níkẹyìn wákàtí kọkànlá (5:00 ìrọ̀lẹ́).

“Ẹni ègún” làwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ka àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sí. (Jòhánù 7:49) Torí pé èyí tó pọ̀ jù nígbèésí ayé wọn ni wọ́n fi ṣiṣẹ́ apẹja tàbí àwọn iṣẹ́ míì. Nígbà tó wá di ọwọ́ ìparí ọdún 29 S.K., “ẹni tó ni ọgbà àjàrà” yìí rán Jésù pé kó pe àwọn ẹni rírẹlẹ̀ yẹn kí wọ́n lè wá ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àwọn ni “ẹni ìkẹyìn” tí Jésù sọ pé wọ́n wá ṣiṣẹ́ nínu ọgbà àjàrà náà ní wákàtí kọkànlá.

Nígbà tí Jésù máa parí àpèjúwe rẹ̀, ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí iṣẹ́ ọjọ́ náà parí, ó sọ pé: “Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún ọkùnrin tó fi ṣe alábòójútó pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o sì san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn tó dé kẹ́yìn títí dórí àwọn ẹni àkọ́kọ́.’ Nígbà tí àwọn ọkùnrin tó dé ní wákàtí kọkànlá wá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan. Nígbà tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wá dé, wọ́n rò pé àwọn máa gbà jù bẹ́ẹ̀ lọ, àmọ́ owó dínárì kan ni wọ́n san fún àwọn náà. Nígbà tí wọ́n gbà á, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé fún baálé ilé náà, wọ́n sì sọ pé, ‘Iṣẹ́ wákàtí kan ni àwọn tó dé kẹ́yìn yìí ṣe; síbẹ̀ iye kan náà lo fún àwa tí a ṣiṣẹ́ kára látàárọ̀ nínú ooru tó mú gan-an!’ Àmọ́ ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀gbẹ́ni, mi ò hùwà àìtọ́ sí ọ. Àdéhùn owó dínárì kan la jọ ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Gba ohun tó jẹ́ tìrẹ, kí o sì máa lọ. Iye tí mo fún ẹni tó dé kẹ́yìn yìí náà ni màá fún ọ. Ṣé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti fi àwọn nǹkan mi ṣe ohun tó wù mí ni? Àbí ṣé ojú rẹ ń ṣe ìlara torí mo jẹ́ ẹni rere ni?’ Lọ́nà yìí, àwọn ẹni ìkẹyìn máa di ẹni àkọ́kọ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì máa di ẹni ìkẹyìn.”—Mátíù 20:8-16.

Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù sọ lọ́wọ́ ìparí àpèjúwe yìí má fi bẹ́ẹ̀ yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Wọ́n lè máa ronú pé: Báwo làwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù, tí wọ́n gbà pé “ẹni àkọ́kọ́” làwọn ṣe máa di “ẹni ìkẹyìn”? Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe máa wá di “ẹni àkọ́kọ́”?

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù táwọn Farisí àtàwọn míì kà sí “ẹni ìkẹyìn” ló máa wá di “ẹni àkọ́kọ́,” tí wọ́n á sì gba owó iṣẹ́ ọjọ́ kan. Lẹ́yìn tí Jésù bá kú, Ọlọ́run máa pa Jerúsálẹ́mù tì, ó sì máa yan orílẹ̀-èdè tuntun, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16; Mátíù 23:38) Àwọn yìí ni Jòhánù Arinibọmi ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Ọlọ́run máa fi ẹ̀mí mímọ́ batisí wọn. Àwọn tí aráyé kà sí ẹni “ìkẹyìn” yìí ni Ọlọ́run máa kọ́kọ́ fi ẹ̀mí mímọ́ batisí, tí wọ́n á sì láǹfààní láti jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jésù “títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:5, 8; Mátíù 3:11) Táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá lóye ìyípadà tí Jésù ń sọ yìí, wọ́n á rí i pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tó máa di ẹni “ìkẹyìn” máa fojú àwọn rí màbo.