Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 99

Jésù La Ojú Àwọn Afọ́jú, Ó sì Ran Sákéù Lọ́wọ́

Jésù La Ojú Àwọn Afọ́jú, Ó sì Ran Sákéù Lọ́wọ́

MÁTÍÙ 20:29-34 MÁÀKÙ 10:46-52 LÚÙKÙ 18:35–19:10

  • JÉSÙ LA OJÚ ÀWỌN AFỌ́JÚ NÍ JẸ́RÍKÒ

  • AGBOWÓ ORÍ KAN TÓ Ń JẸ́ SÁKÉÙ RONÚ PÌWÀ DÀ

Jésù dé Jẹ́ríkò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ ń lọ. Látibẹ̀, ìrìn ọjọ́ kan ló máa gbà wọ́n kí wọ́n tó dé Jerúsálẹ́mù. Ìlú méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń jẹ́ Jẹ́ríkò nígbà yẹn, èyí àtijọ́ tó jẹ́ tàwọn Júù wà ní nǹkan bíi máìlì kan sí ìlú Jẹ́ríkò tuntun ti àwọn ará Róòmù. Bí Jésù àtàwọn èèyàn ṣe ń kúrò ní ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí bọ́ sí ìkejì, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì kan tó ń ṣagbe gbọ́ ìró àwọn èèyàn tó ń kọjá. Báátíméù lorúkọ ọ̀kan lára àwọn afọ́jú yìí.

Nígbà tí Báátíméù àti èkejì rẹ̀ gbọ́ pé Jésù ń kọjá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: “Olúwa, ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì!” (Mátíù 20:30) Àwọn kan lára àwọn èrò tó wà níbẹ̀ jágbe mọ́ wọn pé kí wọ́n dákẹ́, àmọ́ ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń pariwo. Nígbà tí Jésù gbọ́ ariwo yẹn, ó dúró. Ó sì ní kí wọ́n pe ẹni tó ń pariwo wá. Ni wọ́n bá lọ bá àwọn afọ́jú náà, wọ́n sì sọ fún ọ̀kan nínú wọn pé: “Mọ́kàn le! Dìde; ó ń pè ọ́.” (Máàkù 10:49) Inú ọkùnrin afọ́jú náà dùn gan-an, ló bá bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ dà nù, ó fò dìde, ó sì lọ bá Jésù.

Jésù bi wọ́n pé: “Kí lẹ fẹ́ kí n ṣe fún yín?” Àwọn méjèèjì bẹ̀bẹ̀ pé: “Olúwa, jẹ́ kí ojú wa là.” (Mátíù 20:32, 33) Jésù wá káàánú wọn, ó sì fọwọ́ kan ojú wọn, àmọ́ ó sọ fún ọ̀kan nínú wọn pé: “Máa lọ. Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.” (Máàkù 10:52) Àwọn afọ́jú náà ríran, ó sì dájú pé wọ́n yin Ọlọ́run lógo. Nígbà táwọn èèyàn rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, àwọn náà yin Ọlọ́run. Àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Jésù.

Bí Jésù ṣe ń gba Jẹ́ríkò kọjá, àwọn èrò ń wọ́ tẹ̀ lé e, torí gbogbo èèyàn ló fẹ́ mọ ẹni tó la ojú àwọn afọ́jú yẹn. Ṣe ni wọ́n há mọ́ Jésù gádígádí débi pé àwọn kan ò tiẹ̀ lè rí i rárá, irú bíi Sákéù. Òun ni ọ̀gá gbogbo àwọn agbowó orí ní Jẹ́ríkò àti agbègbè ẹ̀. Àmọ́ torí pé ó kúrú, kò ṣeé ṣe fún un láti rí ohun tó ń lọ. Ló bá sáré lọ gun igi síkámórè (tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ mọ́líbẹ́rì) tó wà lójú ọ̀nà ibi tí Jésù ń gbà. Orí igi yẹn ni Sákéù ti wá rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ dáadáa. Nígbà tí Jésù rìn dé tòsí ibi tí Sákéù wà, tó sì rí i lórí igi, ó sọ fún un pé: “Sákéù, tètè sọ̀ kalẹ̀, torí mo gbọ́dọ̀ dé sí ilé rẹ lónìí.” (Lúùkù 19:5) Ni Sákéù bá sọ̀ kalẹ̀, ó sì sáré lọlé kó lè ṣètò bó ṣe máa gba àlejò pàtàkì yìí.

Gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kùn. Wọ́n ronú pé kò yẹ kí Jésù lọ kí ọkùnrin táwọn èèyàn kà sí ẹlẹ́ṣẹ̀. Ọ̀nà èrú ni Sákéù gbà di olówó, ṣe ló máa ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì tó bá fẹ́ gba owó orí lọ́wọ́ wọn.

Nígbà tí Jésù dé ilé Sákéù, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé pé: “Ọ̀dọ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ló lọ dé sí.” Àmọ́ Jésù rí i pé Sákéù lẹ́mìí ìrònúpìwàdà. Ó sì ronú pìwà dà lóòótọ́. Ó dìde, ó sì sọ fún Jésù pé: “Wò ó! Olúwa, ìdajì àwọn ohun ìní mi ni màá fún àwọn aláìní, ohunkóhun tí mo bá sì fipá gbà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ni màá dá pa dà ní ìlọ́po mẹ́rin.”—Lúùkù 19:7, 8.

Ohun tí Sákéù ṣe yẹn dáa gan-an torí ó fi hàn pé òun ti ronú pìwà dà lóòótọ́! Àkọsílẹ̀ owó orí tó ti gbà tẹ́lẹ̀ lè jẹ́ kó mọ iye tó gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn, ó sì ṣèlérí pé òun máa san án pa dà ní ìlọ́po mẹ́rin. Kódà, iye tó fẹ́ dá pa dà ju ohun tí Òfin Mósè béèrè lọ. (Ẹ́kísódù 22:1; Léfítíkù 6:2-5) Sákéù tún ṣèlérí pé òun máa pín àwọn ohun ìní òun sí méjì, òun á sì fún àwọn aláìní ní ìdajì.

Ohun tí Sákéù ṣe láti fi hàn pé òun ronú pìwà dà múnú Jésù dùn, Jésù sì sọ fún un pé: “Lónìí, ìgbàlà ti wọnú ilé yìí, torí pé ọmọ Ábúráhámù ni òun náà. Torí Ọmọ èèyàn wá, kó lè wá ohun tó sọ nù, kó sì gbà á là.”—Lúùkù 19:9, 10.

Kò tíì pẹ́ sígbà yẹn tí Jésù sọ àpèjúwe ọmọkùnrin tó sọ nù. (Lúùkù 15:11-24) Àmọ́ ní báyìí, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sákéù ti jẹ́ káwọn èèyàn rí àpẹẹrẹ ohun tí Jésù sọ nípa ọmọ tó sọ nù, tí wọ́n sì pa dà rí. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn ọmọlẹ́yìn wọn lè máa bínú pé Jésù ń sún mọ́ irú àwọn èèyàn bíi Sákéù. Síbẹ̀, Jésù ò ṣíwọ́ láti máa wá irú àwọn ọmọ Ábúráhámù tó sọ nù yìí kí wọ́n lè pa dà wálé.