Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 119

Jésù Ni Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè

Jésù Ni Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè

JÒHÁNÙ 14:1-31

  • JÉSÙ FẸ́ LỌ PÈSÈ IBI KAN SÍLẸ̀ DE ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN RẸ̀

  • Ó ṢÈLÉRÍ OLÙRÀNLỌ́WỌ́ KAN FÁWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN RẸ̀

  • BABA TÓBI JU JÉSÙ LỌ

Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ò tíì kúrò nínú yàrá tó wà lókè níbi tí wọ́n ti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Jésù wá gbà wọ́n níyànjú, ó ní: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín. Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run; ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú èmi náà.”—Jòhánù 13:36; 14:1.

Jésù ò fẹ́ káwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ yẹn máa ṣàníyàn nígbà tóun bá lọ, torí náà ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùgbé ló wà. . . . Tí mo bá lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, màá tún pa dà wá, màá sì gbà yín sílé sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ̀yin náà lè wà ní ibi tí mo wà.” Àmọ́, ọ̀rọ̀ yẹn ò yé wọn, wọn ò mọ̀ pé ọ̀run ni Jésù sọ pé òun ń lọ. Ni Tọ́másì bá béèrè pé: “Olúwa, a ò mọ ibi tó ò ń lọ. Báwo la ṣe fẹ́ mọ ọ̀nà ibẹ̀?”—Jòhánù 14:2-5.

Jésù dá a lóhùn pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.” Ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà wọ ilé Baba Jésù tó wà lọ́run ni pé kéèyàn gba Jésù gbọ́ àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, kéèyàn sì máa ṣe bíi ti Jésù. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.”—Jòhánù 14:6.

Fílípì ń fọkàn sí ohun tí Jésù sọ, torí náà ó sọ pé: “Olúwa, fi Baba hàn wá, ìyẹn sì máa tó wa.” Ó jọ pé ṣe ló ń wu Fílípì láti rí àmì ńlá kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, irú èyí tí Mósè, Èlíjà àti Àìsáyà rí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun táwọn àpọ́sítélì yìí rí ju ohun táwọn wòlíì yẹn rí lọ. Kí wọ́n lè mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, Jésù sọ pé: “Fílípì, pẹ̀lú bó ṣe pẹ́ tó tí mo ti wà pẹ̀lú yín, ṣé o ò tíì mọ̀ mí ni? Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” Jésù gbé ìwà Baba rẹ̀ yọ gẹ́lẹ́; torí náà bí wọ́n ṣe ń rí Jésù, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n rí Baba rẹ̀. Àmọ́ o, Baba tóbi ju Ọmọ lọ, ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Kì í ṣe èrò ara mi ni àwọn nǹkan tí mò ń sọ fún yín.” (Jòhánù 14:8-10) Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń jẹ́ káwọn àpọ́sítélì yẹn rí i pé ọ̀dọ̀ Baba ni ohun tóun fi ń kọ́ni ti wá.

Àwọn àpọ́sítélì yẹn ti rí bí Jésù ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu àti bó ṣe ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi náà máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; ó sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.” (Jòhánù 14:12) Jésù ò sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe iṣẹ́ ìyanu tó pọ̀ ju èyí tóun ṣe lọ. Àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé àsìkò tí wọ́n máa lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa pọ̀ ju tòun lọ, wọ́n máa wàásù dé ibi tó jìnnà gan-an, àwọn tí wọ́n máa wàásù fún sì máa pọ̀ ju tòun lọ.

Bí Jésù ò tiẹ̀ sí láàárín wọn mọ́, kò ní pa wọ́n tì, torí ó ṣèlérí fún wọn pé: “Tí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, màá ṣe é.” Àmọ́ ó tún sọ pé: “Màá béèrè lọ́wọ́ Baba, ó sì máa fún yín ní olùrànlọ́wọ́ míì tó máa wà pẹ̀lú yín títí láé, ẹ̀mí òtítọ́.” (Jòhánù 14:14, 16, 17) Ẹ̀mí mímọ́ ni olùrànlọ́wọ́ míì tí Jésù ń sọ, ó sì fi dá wọn lójú pé wọ́n máa gba ẹ̀mí mímọ́ yìí. Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ni wọ́n sì gbà á.

Jésù wá sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ayé ò ní rí mi mọ́, àmọ́ ẹ máa rí mi, torí pé mo wà láàyè, ẹ sì máa wà láàyè.” (Jòhánù 14:19) Kì í ṣe pé Jésù máa fara hàn wọ́n lẹ́yìn tó bá jíǹde nìkan ni, kódà tó bá yá, ó máa jí àwọn náà dìde sí ọ̀run, wọ́n sì máa di ẹ̀dá ẹ̀mí.

Lẹ́yìn náà, Jésù sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan fún wọn, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní àwọn àṣẹ mi, tó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi. Lọ́wọ́ kejì, ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ mi, Baba mi máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èmi náà máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, màá sì fi ara mi hàn án kedere.” Ni ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì tó ń jẹ́ Júdásì, tí wọ́n tún ń pè ní Tádéọ́sì bá bi í pé: “Olúwa, kí ló ṣẹlẹ̀ tó fi jẹ́ pé àwa lo fẹ́ fi ara rẹ hàn kedere sí, tí kì í ṣe ayé?” Jésù dá a lóhùn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, ó máa pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Baba mi sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ . . . Ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ mi kì í pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́.” (Jòhánù 14:21-24) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ pé Jésù ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè, àmọ́ àwọn èèyàn tó wà láyé ò mọ̀.

Ní báyìí tí Jésù ti fẹ́ fi wọ́n sílẹ̀, báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe máa rántí gbogbo ohun tó ti kọ́ wọn? Jésù ṣàlàyé pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, tí Baba máa rán ní orúkọ mi, máa kọ́ yín ní gbogbo nǹkan, ó sì máa rán yín létí gbogbo ohun tí mo sọ fún yín.” Àwọn àpọ́sítélì ti rí bí ẹ̀mí mímọ́ yìí ṣe lágbára tó, torí náà ọkàn wọn balẹ̀. Jésù wá fi kún un pé: “Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín; mo fún yín ní àlàáfíà mi. . . . Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín, kí ìbẹ̀rù má sì mú kí ọkàn yín dà rú.” (Jòhánù 14:26, 27) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà rí i pé ó yẹ káwọn fọkàn balẹ̀ torí àwọn ṣì máa gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ Baba Jésù, á sì dáàbò bò àwọn.

Wọ́n máa tó rí ẹ̀rí pé Ọlọ́run máa dáàbò bò wọ́n. Jésù sọ pé: “Alákòóso ayé ń bọ̀, kò sì ní agbára kankan lórí mi.” (Jòhánù 14:30) Èṣù ráyè wọnú Júdásì, ó sì rí Júdásì lò. Àmọ́ kò sí èrò burúkú kankan lọ́kàn Jésù tí Sátánì lè lò láti mú kó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ sì ni Èṣù ò lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ láti jí Jésù dìde. Kí nìdí tí kò fi lè ṣe bẹ́ẹ̀? Jésù sọ ìdí, ó ní: “Ohun tí Baba pa láṣẹ fún mi pé kí n ṣe gẹ́lẹ́ ni mò ń ṣe.” Ó dá Jésù lójú pé Baba òun máa jí òun dìde.—Jòhánù 14:31.