Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 134

Ọlọ́run Ti Jí Jésù Dìde, Ibojì Rẹ̀ sì Ti Ṣófo!

Ọlọ́run Ti Jí Jésù Dìde, Ibojì Rẹ̀ sì Ti Ṣófo!

MÁTÍÙ 28:3-15 MÁÀKÙ 16:5-8 LÚÙKÙ 24:4-12 JÒHÁNÙ 20:2-18

  • ỌLỌ́RUN TI JÍ JÉSÙ DÌDE

  • OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ NÍGBÀ TÀWỌN ÈÈYÀN DÉ IBI TÍ WỌ́N SIN JÉSÙ SÍ

  • JÉSÙ FARA HAN ONÍRÚURÚ ÈÈYÀN

Nígbà táwọn obìnrin tó lọ síbi tí wọ́n tẹ́ òkú Jésù sí débẹ̀, wọ́n rí i pé ibojì náà ṣófo. Ẹ wo bí ẹ̀rù ṣe máa bà wọ́n tó! Màríà Magidalénì wá sáré lọ bá “Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn kejì, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́ gan-an,” ìyẹn àpọ́sítélì Jòhánù. (Jòhánù 20:2) Àmọ́ àwọn obìnrin tó kù dúró síbi ibojì náà, wọ́n sì rí áńgẹ́lì kan, wọ́n tún rí áńgẹ́lì míì tó “wọ aṣọ funfun” nínú ibojì náà.—Máàkù 16:5.

Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì yẹn sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù, torí mo mọ̀ pé Jésù tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ̀ ń wá. Kò sí níbí, torí a ti jí i dìde, bó ṣe sọ gẹ́lẹ́. Ẹ wá wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí. Kí ẹ tètè lọ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé a ti jí i dìde, torí ẹ wò ó! ó ń lọ sí Gálílì ṣáájú yín.” (Mátíù 28:5-7) ‛Jìnnìjìnnì bo àwọn obìnrin náà, wọn ò sì mọ ohun tí wọn ì bá ṣe,’ ni wọ́n bá sáré lọ ròyìn ohun tójú wọn rí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù.—Máàkù 16:8.

Màríà ti sáré dé ọ̀dọ̀ Pétérù àti Jòhánù ní tiẹ̀. Ṣe ló ń mí hẹlẹhẹlẹ, ó wá sọ fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, a ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” (Jòhánù 20:2) Ojú ẹsẹ̀ ni Pétérù àti Jòhánù sáré lọ síbi ibojì náà. Ẹsẹ̀ Jòhánù yá ju ti Pétérù lọ, torí náà òun ló kọ́kọ́ dé ibojì yẹn. Kò wọnú ibojì náà, ó ń wò ó láti ìta, ó sì rí aṣọ tí wọ́n fi di òkú Jésù níbẹ̀.

Bí Pétérù ṣe débẹ̀, ṣe ló sáré wọnú ibojì náà lọ. Ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ àti aṣọ tí wọ́n fi di orí Jésù. Jòhánù wá wọlé sínú ibojì náà, ó sì gbà pé òótọ́ lohun tí Màríà sọ fún wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé onírúurú nǹkan ni Jésù ti sọ fún wọn kó tó kú, kò yé wọn pé ṣe ni Ọlọ́run jí Jésù dìde. (Mátíù 16:21) Gbogbo ohun tí wọ́n rí yà wọ́n lẹ́nu, ni wọ́n bá gbọ̀nà ilé wọn lọ. Àmọ́ Màríà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé síbi ibojì náà ò kúrò níbẹ̀ ní tiẹ̀.

Àwọn obìnrin tó kù ti ń sáré lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kí wọ́n lè sọ fún wọn pé Ọlọ́run ti jí Jésù dìde. Bí wọ́n ṣe ń lọ, Jésù pàdé wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ǹlẹ́ o!” Làwọn obìnrin yẹn bá di ẹsẹ̀ Jésù mú, wọ́n sì “tẹrí ba fún un.” Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù! Ẹ lọ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi, kí wọ́n lè lọ sí Gálílì, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa rí mi.”—Mátíù 28:9, 10.

Ṣáájú ìgbà yẹn, ìmìtìtì ilẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ níbi ibojì yìí, àwọn áńgẹ́lì sì wá síbẹ̀. Àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà níbẹ̀ rí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, torí náà “jìnnìjìnnì bá wọn, wọ́n sì kú sára.” Nígbà tára wọn balẹ̀, wọ́n wọnú ìlú lọ, wọ́n sì “ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn olórí àlùfáà.” Àwọn olórí àlùfáà wá fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn àgbààgbà Júù. Gbogbo wọn gbà láti fún àwọn ọmọ ogun yẹn lówó, kí wọ́n má bàa sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí gẹ́lẹ́ fáwọn èèyàn, àmọ́ wọ́n ní kí wọ́n máa sọ pé: “Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá jí i gbé ní òru nígbà tí à ń sùn.”—Mátíù 28:4, 11, 13.

Ìjọba Róòmù lè pa ọmọ ogun kan tó bá ń sùn lẹ́nu iṣẹ́, torí náà àwọn àlùfáà yẹn ṣèlérí fáwọn ọmọ ogun yẹn pé: “Tí èyí [ìyẹn irọ́ tí wọ́n pa pé àwọn ń sùn lẹ́nu iṣẹ́] bá . . . dé etí gómìnà, a máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún un, kò ní sídìí láti da ara yín láàmú.” (Mátíù 28:14) Làwọn ọmọ ogun yẹn bá gba owó, wọ́n sì ṣe ohun táwọn àlùfáà ní kí wọ́n ṣe. Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fáwọn èèyàn pé ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá jí òkú ẹ̀ gbé, irọ́ yìí sì tàn káàkiri láàárín àwọn Júù.

Màríà Magidalénì ṣì wà níbi ibojì yẹn tó ń sunkún. Bó ṣe yọjú wo inú ibojì náà, ó rí áńgẹ́lì méjì tí wọ́n wọ aṣọ funfun! Àwọn méjèèjì jókòó síbi tí wọ́n tẹ́ Jésù sí tẹ́lẹ̀, ọ̀kan wà níbi orí, èkejì sì wà níbi ẹsẹ̀. Wọ́n wá bi Màríà pé: “Obìnrin yìí, kí ló dé tó ò ń sunkún?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa mi lọ, mi ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” Lẹ́yìn náà ó yíjú pa dà, ó tún rí ẹnì kan níwájú rẹ̀. Ẹni náà béèrè ìbéèrè táwọn áńgẹ́lì yẹn kọ́kọ́ bi í, ó wá fi kún un pé: “Ta lò ń wá?” Màríà rò pé ẹni tó ń tọ́jú ọgbà ni, torí náà ó dá a lóhùn pé: “Ọ̀gá, tó bá jẹ́ ìwọ lo gbé e kúrò, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, màá sì gbé e lọ.”—Jòhánù 20:13-15.

Màríà ò mọ̀ pé Jésù tí Ọlọ́run jí dìde lòun ń bá sọ̀rọ̀. Àmọ́ nígbà tí Jésù sọ pé: “Màríà!” ojú ẹsẹ̀ ni Màríà dá Jésù mọ̀, ó rántí bí Jésù ṣe máa ń pe òun. Inú Màríà dùn gan-an, òun náà wá pe Jésù, ó ní: “Rábónì!” (tó túmọ̀ sí “Olùkọ́!”). Àmọ́, Màríà ń bẹ̀rù pé Jésù ò ní pẹ́ fi òun sílẹ̀, torí náà ó rọ̀ mọ́ ọn. Ni Jésù bá sọ fún un pé: “Má rọ̀ mọ́ mi mọ́, torí mi ò tíì gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba. Àmọ́ lọ bá àwọn arákùnrin mi, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín.’ ”—Jòhánù 20:16, 17.

Màríà wá sáré lọ síbi táwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù kóra jọ sí. Ó sọ fún wọn pé: “Mo ti rí Olúwa!” Ohun tó sọ yìí ò yàtọ̀ sóhun táwọn obìnrin tó kù ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀. (Jòhánù 20:18) Àmọ́, ṣe ni gbogbo ohun tí wọ́n sọ yẹn ‘dà bí ìsọkúsọ létí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù.’—Lúùkù 24:11.