Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 139

Jésù Parí Iṣẹ́ Rẹ̀, Ó sì Máa Sọ Ayé Di Párádísè

Jésù Parí Iṣẹ́ Rẹ̀, Ó sì Máa Sọ Ayé Di Párádísè

1 KỌ́RÍŃTÌ 15:24-28

  • OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ SÁWỌN ÀGÙNTÀN ÀTÀWỌN EWÚRẸ́

  • Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN LÓ MÁA GBÁDÙN PÁRÁDÍSÈ

  • JÉSÙ ṢE OHUN TÓ FI HÀN PÉ ÒUN NI Ọ̀NÀ, ÒTÍTỌ́ ÀTI ÌYÈ

Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, kó tiẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ rárá ni ọ̀tá kan ti gbìyànjú láti dí i lọ́wọ́ kó má bàa ṣàṣeyọrí. Léraléra ni Èṣù gbìyànjú láti dán Jésù wò. Nígbà tó yá, Jésù sọ ohun kan nípa ẹni burúkú yẹn, ó ní: “Alákòóso ayé ń bọ̀, kò sì ní agbára kankan lórí mi.”—Jòhánù 14:30.

Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ‘dírágónì ńlá náà, ejò àtijọ́ náà, tí à ń pè ní Èṣù àti Sátánì.’ Ìkà ni ọ̀tá yìí, ó sì kórìíra gbogbo èèyàn, lẹ́yìn tí wọ́n lé e kúrò lọ́run, ṣe ló “ń bínú gidigidi, ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun.” (Ìfihàn 12:9, 12) Ó yẹ káwọn Kristẹni mọ̀ pé “ìgbà díẹ̀” yẹn là ń gbé báyìí àti pé láìpẹ́ wọ́n máa fi “dírágónì náà . . . ejò àtijọ́ náà,” sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, níbi tí kò ti ní lè ṣe ohunkóhun fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún, Jésù á sì máa ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run.—Ìfihàn 20:1, 2.

Láàárín àkókò yẹn, kí ló máa ṣẹlẹ̀ ní ayé tó jẹ́ ilé àwa èèyàn? Àwọn wo lá máa gbé ayé, báwo ni nǹkan sì ṣe máa rí nígbà yẹn? Jésù fúnra rẹ̀ dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Nínú àpèjúwe tó ṣe nípa àgùntàn àti ewúrẹ́, ó ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú sáwọn olódodo tó fi wé àgùntàn, ìyẹn àwọn tó ṣe rere sáwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n sì tì wọ́n lẹ́yìn. Ó tún ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn, ìyẹn àwọn tó fi wé ewúrẹ́. Jésù sọ pé: “Àwọn yìí [ìyẹn àwọn ewúrẹ́] máa lọ sínú ìparun àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo [ìyẹn àwọn àgùntàn] sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 25:46.

Ọ̀rọ̀ Jésù yìí jẹ́ ká lóye ohun tí Jésù sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kì í ṣe ìlérí tí Jésù ṣe fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ ló ṣe fún ọkùnrin yẹn, kò sọ fún un pé ó máa wà pẹ̀lú òun ní Ìjọba ọ̀run. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ fún ọ̀daràn tó ti ronú pìwà dà náà pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Èyí fi hàn pé ó máa ṣeé ṣe fún ọkùnrin náà láti wà nínú Párádísè, ìyẹn ibi tó lẹ́wà gan-an, tó sì tura. Bákan náà, gbogbo àwọn tó bá jẹ́ ẹni bí àgùntàn lónìí, tí wọ́n sì láǹfààní láti lọ “sínú ìyè àìnípẹ̀kun” ló máa wà nínú Párádísè yẹn.

Ohun tí Jésù sọ yẹn jọra pẹ̀lú àlàyé tí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe nípa bí nǹkan ṣe máa rí láyé. Jòhánù sọ pé: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, á máa bá wọn gbé, wọ́n á sì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa wà pẹ̀lú wọn. Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìfihàn 21:3, 4.

Kí ọkùnrin tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù yẹn tó lè wà nínú Párádísè, Ọlọ́run máa ní láti jí i dìde. Òun nìkan kọ́ ni Ọlọ́run sì máa jí dìde. Ohun tí Jésù sọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀, tí wọ́n á sì jáde wá, àwọn tó ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.”—Jòhánù 5:28, 29.

Àmọ́ kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ àtàwọn èèyàn bíi mélòó kan tó máa wà pẹ̀lú Jésù lọ́run? Bíbélì sọ pé: “Wọ́n máa jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọ́n sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà.” (Ìfihàn 20:6) Àwọn tó máa bá Jésù jọba yẹn ti fìgbà kan rí wà láyé. Torí náà, ó máa rọrùn fún wọn láti gba tàwọn èèyàn rò, kí wọ́n sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí.—Ìfihàn 5:10.

Àwọn èèyàn tó wà láyé máa jàǹfààní ẹbọ ìràpadà tí Jésù san, ìyẹn á sì mú kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n jogún. Jésù àtàwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ máa mú kí àwọn olóòótọ́ èèyàn di pípé. Ayé á wá rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀, ìyẹn nígbà tó sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n máa bímọ, kí wọ́n pọ̀, kí wọ́n sì kún ayé. Kódà, ikú tí à ń kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ò ní sí mọ́!

Nígbà yẹn, Jésù á ti parí gbogbo ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Ní ìparí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso yẹn, Jésù máa dá Ìjọba pa dà fún Baba rẹ̀, Ọlọ́run á sì máa ṣàkóso àwọn èèyàn pípé. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, ìgbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ á fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún kálukú.”—1 Kọ́ríńtì 15:28.

Ó ṣe kedere pé ipa kékeré kọ́ ni Jésù kó kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ. Ó dájú pé títí láé làwa èèyàn á túbọ̀ máa lóye ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé yìí, ní gbogbo àsìkò yẹn, á túbọ̀ ṣe kedere sí wa pé òótọ́ lohun tí Jésù sọ nípa ara rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.”—Jòhánù 14:6.