Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 4

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Pa Dà Ṣe ní Jùdíà

“Ẹ bẹ ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde.”—Lúùkù 10:2

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Pa Dà Ṣe ní Jùdíà

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 66

Jésù Lọ sí Jerúsálẹ́mù Nígbà Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn

Kí lo lè mú káwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù rò pé ó lẹ́mìí èṣù?

ORÍ 67

“Èèyàn Kankan Ò Sọ̀rọ̀ Báyìí Rí”

Gbogbo àwọn tó wà nílé ẹjọ́ gíga àwọn Júù ló ń ta ko Jésù, àmọ́ ọ̀kan lára wọn gbìyànjú láti gbèjà rẹ̀.

ORÍ 68

Ọmọ Ọlọ́run Ni “Ìmọ́lẹ̀ Ayé”

Jésù sọ pé “òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.” Òmìnira lọ́wọ́ kí ni?

ORÍ 69

Ṣé Ábúráhámù Ni Bàbá Wọn Àbí Èṣù?

Jésù ṣàlàyé bá a ṣe lè mọ ẹni tó jẹ́ ọmọ Ábúráhámù lóòótọ́, ó sì sọ òtítọ́ nípa ẹni tí Baba rẹ̀ jẹ́.

ORÍ 70

Jésù La Ojú Ọkùnrin Kan Tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù béèrè ìdí tí ọkùnrin yìí fi fọ́ lójú. Ṣé ọkùnrin náà ló ṣẹ̀ ni? Ṣe àwọn òbí ẹ̀ ló ṣẹ̀? Èrò àwọn èèyàn ò ṣọ̀kan nígbà tí Jésù wò ó sàn.

ORÍ 71

Àwọn Farisí Gbọ́ Tẹnu Ọkùnrin Afọ́jú Náà

Ọ̀rọ̀ tó gba àròjinlẹ̀ tí ọkùnrin afọ́jú náà sọ bí àwọn Farisí nínú. Ohun táwọn òbí rẹ̀ ń bẹ̀rù pé ó lè ṣẹlẹ̀ ló pa dà ṣẹlẹ̀, ṣe ni wọ́n lé ọkùnrin náà kúrò nínú sínágọ́gù.

ORÍ 72

Jésù Rán Àádọ́rin (70) Ọmọ Ẹ̀yìn Jáde Lọ Wàásù

Ní Jùdíà, Jésù rán àádọ́rin (70) ọmọ ẹ̀yìn jáde lọ wàásù, ó pín wọn ní méjì-méjì. Ibo làwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ti máa rí àwọn tí wọ́n fẹ́ wàásù fún, ṣé inú sínágọ́gù ni àbí wọ́n máa lọ sílé àwọn èèyàn?

ORÍ 73

Ará Samáríà Kan Fi Hàn Pé Òun Láàánú

Báwo ni Jésù ṣe lo àkàwé nípa ará Samáríà tàbí “aláàánú ará Samáríà” láti kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan?

ORÍ 74

Ẹ̀kọ́ Nípa Aájò Àlejò àti Àdúrà

Jésù lọ kí Màríà àti Màtá nílé wọn. Kí ló kọ́ wọn nípa aájò àlejò? Báwo ló sì ṣe kọ́ wọn ní ohun tó yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà fún lẹ́yìn náà?

ORÍ 75

Jésù Sọ Ohun Tó Ń Fúnni Láyọ̀

Jésù dá àwọn alátakò rẹ̀ lóhùn, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa “ìka Ọlọ́run” àti bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe dé bá wọn lójijì. Ó tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe lè rí ayọ̀ tòótọ́.

ORÍ 76

Farisí Kan Gba Jésù Lálejò

Jésù tú àṣírí ìwà àgàbàgebè àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin. Ẹrù tó wúwo wo ni wọ́n ń fi dandan mú àwọn èèyàn láti máa gbé?

ORÍ 77

Jésù Sọ̀rọ̀ Nípa Ọrọ̀

Jésù sọ àpèjúwe nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó kọ́ ilé ìkẹ́rùsí tó tóbi fún ara ẹ̀. Ewu wo ni Jésù tún tẹnu mọ́ nípa kéèyàn máa kó ọrọ̀ jọ?

ORÍ 78

Jésù Ní Kí Ìríjú Olóòótọ́ Náà Múra Sílẹ̀

Jésù fi hàn pé ọ̀rọ̀ báwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣe máa sún mọ́ Ọlọ́run jẹ òun lọ́kàn. Kí ni ìríjú náà máa ṣe kí wọ́n lè máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí lásìkò tó yẹ? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé ká múra sílẹ̀?

ORÍ 79

Ìdí Táwọn Èèyàn Náà Fi Máa Pa Run

Jésù sọ pé táwọn èèyàn náà ò bá ronú pìwà dà, wọ́n máa pa run láìpẹ́. Ṣé wọ́n máa fi ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wọn sílò pé kí wọ́n ronú nípa bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?

ORÍ 80

Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà àti Agbo Àgùntàn

Àjọṣe tó wà láàárín olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn àgùntàn rẹ̀ jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe jẹ ẹ́ lógún tó. Ṣé wọ́n máa gba ohun tí Jésù ń kọ́ wọn, tí wọ́n á sì tẹ̀ lé e?

ORÍ 81

Ọ̀kan Ni Jésù àti Baba, Àmọ́ Jésù Kì Í Ṣe Ọlọ́run

Àwọn kan lára àwọn tó ń ta ko Jésù fẹ̀sùn kàn án pé ó ń pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run. Báwo ni Jésù ṣe fọgbọ́n já irọ́ wọn?