Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ṣé o rò pé . . .

  • ohun tó wà lọ́kàn èèyàn ni?

  • àbí àkànlò èdè?

  • àbí ìjọba kan ní ọ̀run?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé.”​—Dáníẹ́lì 2:44, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

“A ti fún wa ní ọmọkùnrin kan; ìjọba sì máa wà ní èjìká rẹ̀.”​—Àìsáyà 9:6; àlàyé ìsàlẹ̀.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ

  • Ìjọba kan tó ń fi òdodo ṣàkóso tó máa ṣe ìwọ fúnra rẹ láǹfààní.​—Àìsáyà 48:17, 18.

  • Nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, gbogbo èèyàn máa ní ìlera tó pé, wọ́n á sì láyọ̀.​—Ìfihàn 21:3, 4.

ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Jésù jẹ́ ká rí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí àwọn èèyàn sì máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ayé. (Mátíù 6:9, 10) Jésù ṣe ohun tó jẹ́ ká rí bí Ọlọ́run ṣe máa dáhùn àdúrà yẹn.

    Nígbà tí Jésù wà láyé, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó sì jí òkú dìde! (Mátíù 15:29-38; Jòhánù 11:38-44) Torí pé Jésù ló máa jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó jẹ́ ká rí ohun tí Ìjọba náà máa ṣe fún àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀.​—Ìfihàn 11:15.

  • Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí jẹ́ ẹ̀rí pé Ìjọba Ọlọ́run kò ní pẹ́ dé. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá kù díẹ̀ kí Ìjọba Ọlọ́run mú kí àlàáfíà jọba ní ayé, ogun, ìyàn àti ìmìtìtì ilẹ̀ kò ní jẹ́ kí aráyé gbádùn.​—Mátíù 24:3, 7.

    Ohun tí à ń rí tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ayé báyìí nìyẹn. Torí náà, ó dá wa lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo ìṣòro yìí.

RÒ Ó WÒ NÁ

Báwo ni ìgbésí ayé ṣe máa rí tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé SÁÀMÙ 37:29 àti ÀÌSÁYÀ 65:21-23.