Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Wa?

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Wa?

TÓ O bá ka ìwé ìròyìn, tó o wo tẹlifíṣọ̀n tàbí tó o gbọ́ rédíò, wàá rí ìwà ọ̀daràn àti ogun tó ń ṣẹlẹ̀, wàá sì tún rí ọṣẹ́ táwọn afẹ̀míṣòfò ń ṣe. Ó ṣeé ṣe kí àìsàn ti fi ojú rẹ rí màbo tàbí kí ikú ẹnì kan tó o fẹ́ràn máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ.

Bi ara rẹ pé:

  • Ṣé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí èmi àti ìdílé mi rèé?

  • Ibo ni mo ti lè rí ìrànlọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro mi?

  • Ṣé àlàáfíà tòótọ́ ṣì máa wà láyé?

Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn.

BÍBÉLÌ KỌ́ WA PÉ ỌLỌ́RUN MÁA ṢE ÀWỌN OHUN ÌYANU LÁYÉ.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ WÀÁ RÍ TÓ O BÁ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé àlá tí ò lè ṣẹ làwọn àyípadà tó o kẹ́kọ̀ọ́ pé ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ láyé yìí. Àmọ́, Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa ṣe àwọn àyípadà yẹn láìpẹ́, Bíbélì sì ṣàlàyé bó ṣe máa ṣe é.

Bíbélì tún sọ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sọ ohun tó yẹ ká mọ̀ ká lè ní ayọ̀ tòótọ́, ká sì lè gbádùn ayé wa ní báyìí. Tiẹ̀ ronú nípa àwọn nǹkan tó máa ń mú kó o ní ìdààmú ọkàn. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ owó, ìṣòro ìdílé, àìlera tàbí ikú ẹni tó o fẹ́ràn. Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àwọn ìṣòro yìí, á sì tù ẹ́ nínú tó o bá mọ bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè bíi:

Bó o ṣe ń ka ìwé yìí fi hàn pé ó wù ẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì kọ́ wa. Ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an. Àwọn ìbéèrè tó wà fún àwọn ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Bíbélì dáadáa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì gbádùn ẹ̀. A retí pé ìwọ náà máa gbádùn ẹ̀. Àdúrà wa ni pé kí Ọlọ́run bù kún ẹ bó o ṣe ń sapá láti mọ ohun tí Bíbélì kọ́ wa!