Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸRIN

Ta Ni Jésù Kristi?

Ta Ni Jésù Kristi?

1, 2. (a) Ṣé o lè sọ pé o mọ olókìkí èèyàn kan dáadáa tó bá jẹ́ orúkọ rẹ̀ nìkan lo mọ̀? Ṣàlàyé. (b) Kí ni àwọn èèyàn kan gbà gbọ́ nípa Jésù?

Ọ̀PỌ̀ olókìkí èèyàn ló wà láyé. Ó ṣeé ṣe kó o mọ orúkọ ẹnì kan tó lókìkí. Àmọ́, ti pé o mọ orúkọ rẹ̀ kò túmọ̀ sí pé o mọ ẹni náà dáadáa tàbí pé o mọ gbogbo nǹkan nípa ìgbésí ayé rẹ̀ àti irú ẹni tó jẹ́.

2 Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ nípa Jésù Kristi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn ló gbé ayé. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ irú ẹni tí Jésù jẹ́ gangan. Àwọn kan sọ pé èèyàn rere ni, àwọn míì pè é ní wòlíì, àwọn míì sì gbà pé òun ni Ọlọ́run. Kí lèrò rẹ?​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 12.

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o mọ Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi?

3 Ó ṣe pàtàkì kó o mọ òtítọ́ nípa Jésù. Kí nìdí? Bíbélì sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.(Jòhánù 17:3) Ó dájú pé tó o bá mọ òtítọ́ nípa Jèhófà àti Jésù, wàá lè máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè. (Jòhánù 14:6) Bákan náà, ó máa dáa kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù torí pé ó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa àti bó ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn èèyàn. (Jòhánù 13:​34, 35) Orí 1 kọ́ wa ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Ní báyìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù nínú Bíbélì.

A TI RÍ MÈSÁYÀ NÁÀ!

4. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “Mèsáyà” àti “Kristi” túmọ̀ sí?

4 Ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó bí Jésù, Jèhófà ṣèlérí nínú Bíbélì pé òun máa rán Mèsáyà tó tún ń jẹ́ Kristi wá. Ọ̀rọ̀ náà “Mèsáyà” wá láti inú èdè Hébérù, àmọ́ láti inú èdè Gíríìkì ni ọ̀rọ̀ náà, “Kristi” ti wá. Àwọn orúkọ oyè yìí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run máa yan Mèsáyà tó ṣèlérí, á sì fún un ní ipò àrà ọ̀tọ̀ kan. Mèsáyà náà máa mú gbogbo ìlérí Ọlọ́run ṣẹ. Ní báyìí, Jésù lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àmọ́ kí wọ́n tó bí Jésù, ọ̀pọ̀ ló ń béèrè pé, ‘Ta ló máa jẹ́ Mèsáyà náà?’

5. Ṣé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbà pé òun ni Mèsáyà?

5 Ó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lójú pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jòhánù 1:41) Bí àpẹẹrẹ, Símónì Pétérù sọ fún Jésù pé: “Ìwọ ni Kristi náà.” (Mátíù 16:16) Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jésù ni Mèsáyà?

6. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí àwọn olóòótọ́ èèyàn dá Mèsáyà náà mọ̀?

6 Ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó bí Jésù, àwọn wòlíì Ọlọ́run kọ ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ tó máa jẹ́ kó rọrùn fún àwọn èèyàn láti dá Mèsáyà mọ̀. Báwo ni èyí ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́? Ká sọ pé wọ́n rán ẹ pé kó o lọ pàdé ẹnì kan tí o kò mọ̀ rí ní ibùdókọ̀ tí àwọn èèyàn pọ̀ sí. Tí ẹnì kan bá júwe bí onítọ̀hún ṣe rí fún ẹ dáadáa, èyí á jẹ́ kó o lè dá ẹni náà mọ̀. Lọ́nà kan náà, Jèhófà lo àwọn wòlíì rẹ̀ láti sọ fún wa nípa ohun tí Mèsáyà máa ṣe àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i. Bí gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ jẹ́ kí àwọn olóòótọ́ èèyàn mọ̀ dájú pé Jésù ni Mèsáyà náà.

7. Àsọtẹ́lẹ̀ méjì wo ló fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà náà?

7 Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà. Àkọ́kọ́, ní ọgọ́rùn-ún méje (700) ọdún kí wọ́n tó bí Jésù, wòlíì Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó jẹ́ ìlú kékeré kan ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí. (Míkà 5:2) Ibẹ̀ gangan ni wọ́n sì bí Jésù sí! (Mátíù 2:​1, 3-9) Ìkejì, wòlíì Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà náà máa fara hàn ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. (Dáníẹ́lì 9:25) Èyí wulẹ̀ jẹ́ méjì péré lára ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó fi hàn kedere pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí.​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 13.

Nígbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi, ó di Mèsáyà tàbí Kristi

8, 9. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi tó fi hàn pé òun ni Mèsáyà náà?

8 Jèhófà mú kó hàn kedere pé Jésù ni Mèsáyà náà. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fún Jòhánù Onírìbọmi ní àmì tó máa jẹ́ kó mọ ẹni tí Mèsáyà náà jẹ́. Nígbà tí Jésù lọ bá Jòhánù pé kó ṣèrìbọmi fún òun nínú odò Jọ́dánì lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, Jòhánù rí àmì yẹn. Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, ó jáde látinú omi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí i tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀. Wò ó! Ohùn kan tún dún láti ọ̀run pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’” (Mátíù 3:16, 17) Nígbà tí Jòhánù rí àmì yìí, ó mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà náà. (Jòhánù 1:32-34) Lọ́jọ́ yẹn, Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí Jésù, ó sì di Mèsáyà. Òun ni ẹni tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ Aṣáájú àti Ọba.​—Àìsáyà 55:4.

9 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ àti àmì tó fi hàn nígbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi, jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà. Àmọ́, ibo ni Jésù ti wá? Irú ẹni wo sì ni? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ.

IBO NI JÉSÙ TI WÁ?

10. Kí ni Bíbélì sọ nípa Jésù kó tó wá sáyé?

10 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Jésù fi wà lọ́run kó tó wá sáyé. Míkà sọ pé Mèsáyà ti wà “láti ìgbà àtijọ́.” (Míkà 5:2) Jésù fúnra rẹ̀ sọ lọ́pọ̀ ìgbà pé òun ti wà lọ́run kí wọ́n tó bí òun sáyé. (Ka Jòhánù 3:13; 6:38, 62; 17:4, 5.) Kí Jésù tó wá sáyé ló ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.

11. Kí nìdí tí Jésù fi ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà?

11 Jésù ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Kí nìdí? Torí pé òun ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá kó tó dá ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” * (Kólósè 1:15) Jésù tún ṣeyebíye lójú Jèhófà torí pé òun nìkan ni Jèhófà fọwọ́ ara rẹ̀ dá ní tààràtà. Abájọ tí Bíbélì fi pè é ní ‘Ọmọ bíbí kan ṣoṣo.’ (Jòhánù 3:16) Òun ni ẹnì kan ṣoṣo tí Jèhófà lò láti dá gbogbo àwọn nǹkan tó kù. (Kólósè 1:16) Yàtọ̀ sí ìyẹn, Jésù nìkan ni Bíbélì pè ní “Ọ̀rọ̀ náà,” torí pé òun ni Jèhófà máa ń rán láti fún àwọn áńgẹ́lì àti àwa èèyàn ní ìsọfúnni àti ìtọ́ni.​—Jòhánù 1:14.

12. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù àti Ọlọ́run kì í ṣe ẹnì kan náà?

12 Àwọn kan gbà gbọ́ pé ẹnì kan náà ni Jésù àti Ọlọ́run. Àmọ́ Bíbélì kò sọ bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló dá Jésù, ìyẹn fi hàn pé Jésù ní ìbẹ̀rẹ̀. Àmọ́ Jèhófà kò ní ìbẹ̀rẹ̀ torí pé òun ló dá ohun gbogbo. (Sáàmù 90:2) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, kò ronú rárá láti bá Ọlọ́run dọ́gba. Bíbélì sọ fún wa pé Baba tóbi ju ọmọ lọ. (Ka Jòhánù 14:28; 1 Kọ́ríńtì 11:3.) Jèhófà nìkan ṣoṣo ni “Ọlọ́run Olódùmarè.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:1) Òun ló lágbára jù lọ láyé àtọ̀run.​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 14.

13. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jésù ní “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí”?

13 Àìmọye ọdún ni Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ fi ṣiṣẹ́ pọ̀, kí ọ̀run àti ayé tó wà. Ó dájú pé wọ́n fẹ́ràn ara wọn gan-an ni! (Jòhánù 3:35; 14:31) Jésù fi ìwà jọ Baba rẹ̀ débi pé Bíbélì pè é ní “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí.”​—Kólósè 1:15.

14. Báwo ni wọ́n ṣe bí Ọmọ Jèhófà sáyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn?

14 Ọmọ Jèhófà tó jẹ́ àyànfẹ́ yìí fi ọ̀run sílẹ̀ tinútinú, wọ́n sì bí i sáyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn. Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀? Lọ́nà ìyanu, Jèhófà fi ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sínú ikùn wúńdíá kan tó ń jẹ́ Màríà. Ìdí nìyẹn tá a fi lè sọ pé Jésù kò ní Bàbá tó jẹ́ èèyàn. Torí náà, Màríà bí ọmọ kan tó jẹ́ ẹni pípé, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.​—Lúùkù 1:30-35.

IRÚ ẸNI WO NI JÉSÙ?

15. Báwo lo ṣe lè túbọ̀ mọ Jèhófà?

15 Tó o bá ka àwọn ìwé Bíbélì bíi Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù, wàá mọ púpọ̀ sí i nípa ìgbésí ayé Jésù àti àwọn ìwà rẹ̀. Àwọn ìwé yẹn ni à ń pè ní ìwé Ìhìn Rere. Ohun tó o bá kà níbẹ̀ máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọ Jèhófà torí pé Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀. Abájọ tí Jésù fi sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.”​—Jòhánù 14:9.

16. Kí ni Jésù kọ́ni? Ibo ni àwọn ẹ̀kọ́ náà ti wá?

16 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń pe Jésù ní “Olùkọ́.” (Jòhánù 1:38; 13:13) Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù kọ́ni ni “ìhìn rere Ìjọba náà.” Kí ni Ìjọba náà? Ó jẹ́ ìjọba kan tí Ọlọ́run ṣètò, tó máa ṣàkóso gbogbo ayé láti ọ̀run, ó sì máa bù kún àwọn èèyàn tó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Mátíù 4:23) Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ohun tí Jésù kọ́ni ti wá. Jésù sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, àmọ́ ó jẹ́ ti ẹni tó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Jésù mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí àwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa ṣàkóso ayé.

17. Ibo ni Jésù ti kọ́ni? Kí nìdí tó fi lo ìtara láti kọ́ àwọn èèyàn?

17 Ibo ni Jésù ti kọ́ni? Ó kọ́ni níbikíbi tó bá ti rí àwọn èèyàn. Ó kọ́ni ní àwọn ìlú ńlá, abúlé, ọjà, ibi ìjọsìn àti nílé àwọn èèyàn. Kò retí pé kí àwọn èèyàn wá bá òun. Lọ́pọ̀ ìgbà, òun ló máa ń lọ bá wọn. (Máàkù 6:56; Lúùkù 19:5, 6) Jésù fi ìtara wàásù, ó sì lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun rẹ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn. Kí nìdí? Ó mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí òun ṣe nìyẹn, ó sì máa ń ṣègbọràn sí Baba rẹ̀. (Jòhánù 8:28, 29) Jésù tún máa ń wàásù torí pé àánú àwọn èèyàn máa ń ṣe é. (Ka Mátíù 9:35, 36.) Ó rí i pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kò kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi fẹ́ ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti gbọ́ ìhìn rere náà.

18. Èwo nínú àwọn ìwà Jésù lo fẹ́ràn jù?

18 Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lọ́kàn. Onínúure ni, ó sì ṣeé sún mọ́. Kódà, àwọn ọmọdé máa ń fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Máàkù 10:13-16) Jésù kì í ṣe ojúsàájú. Ó kórìíra ìwà ìbàjẹ́ àti ìrẹ́jẹ. (Mátíù 21:12, 13) Lásìkò tó gbé ayé, àǹfààní díẹ̀ ni àwọn obìnrin ní láwùjọ, wọn kì í sì í buyì fún wọn. Àmọ́, gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń buyì kún àwọn obìnrin tó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. (Jòhánù 4:9, 27) Jésù tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lálẹ́ ọjọ́ kan, ó fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, iṣẹ́ tó jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ ló sábà máa ń ṣe é.​—Jòhánù 13:2-5, 12-17.

Jésù wàásù fún àwọn èèyàn níbikíbi tó bá ti rí wọn

19. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jésù mọ ohun tí àwọn èèyàn nílò, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́?

19 Jésù mọ ohun tí àwọn èèyàn nílò, ó sì máa ń fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Èyí hàn nínú bó ṣe lo agbára Ọlọ́run láti wo àwọn èèyàn sàn lọ́nà ìyanu. (Mátíù 14:14) Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá bá Jésù, ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.” Ìrora àti ìyà tí ọkùnrin yẹn ń jẹ mú kí Jésù ṣe nǹkan sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́. Torí náà, Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó wá sọ fún un pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.” Bí ara ọkùnrin náà ṣe yá nìyẹn o! (Máàkù 1:40-42) Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára ọkùnrin yẹn?

ÌGBÀ GBOGBO LÓ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ SÍ BABA RẸ̀

20, 21. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá kan ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run?

20 Jésù ni àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ tó bá kan ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ó jẹ́ olóòótọ́ sí Baba rẹ̀ láìka gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i àti gbogbo ohun tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe sí i. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kò dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí Èṣù dán an wò. (Mátíù 4:1-11) Àwọn kan lára ìbátan Jésù ò gbà pé òun ni Mèsáyà, wọ́n tiẹ̀ sọ pé “orí rẹ̀ ti yí,” síbẹ̀ ńṣe ni Jésù ń bá iṣẹ́ Ọlọ́run lọ. (Máàkù 3:21) Kódà, nígbà tí àwọn ọ̀tá hùwà ìkà sí i, Jésù ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kò sì gbẹ̀san lára wọn.​—1 Pétérù 2:21-23.

21 Kódà nígbà tí Jésù ń jìyà tó sì fẹ́ kú ikú oró, ó ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Ka Fílípì 2:8.) Fojú inú wo bí Jésù ṣe fara da ọ̀pọ̀ ìnira lọ́jọ́ tó kú. Wọ́n fi àṣẹ ọba mú un, àwọn ẹlẹ́rìí èké fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ń sọ̀rọ̀ òdì, àwọn adájọ́ oníwà ìbàjẹ́ dá a lẹ́bi, àwọn èèyàn fi ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn ṣọ́jà dá a lóró, wọ́n sì kàn án mọ́ òpó igi. Nígbà tó ń kú lọ, ó kígbe pé: “A ti ṣe é parí!” (Jòhánù 19:30) Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn tí Jésù kú, Jèhófà jí i dìde, ó sì sọ ọ́ di ààyè nínú ẹ̀mí. (1 Pétérù 3:18) Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, Jésù pa dà sí ọ̀run, ó “jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,” ó ń dúró de ìgbà tí Ọlọ́run máa sọ ọ́ di Ọba.​—Hébérù 10:12,13.

22. Àǹfààní wo la ní torí pé Jésù jẹ́ olóòótọ́ sí Baba rẹ̀?

22 Torí pé Jésù jẹ́ olóòótọ́ sí Baba rẹ̀, ìyẹn á mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè bí Jèhófà ṣe fẹ́. Nínú orí tó kàn, a máa jíròrò bí ikú Jésù á ṣe mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbé ayé títí láé.

^ ìpínrọ̀ 11 À ń pe Jèhófà ní Baba torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. (Àìsáyà 64:8) À ń pe Jésù ní Ọmọ Ọlọ́run torí pé Jèhófà ló dá a. Bíbélì tún pe Ádámù àti àwọn áńgẹ́lì ní ọmọ Ọlọ́run.​—Jóòbù 1:6; Lúùkù 3:38.