Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸSÀN-ÁN

Ṣé Òpin Ayé Ti Sún Mọ́lé?

Ṣé Òpin Ayé Ti Sún Mọ́lé?

1. Inú ìwé wo la ti lè mọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la?

ṢÉ O ti gbọ́ ìròyìn kan rí tó mú kó o ronú pé, ‘Ibo layé yìí ń lọ gan-an?’ Bí àjálù àti ìwà ìkà ṣe ń pọ̀ sí i ti mú kí àwọn kan gbà pé òpin ayé ti sún mọ́lé. Ṣé òótọ́ ni? Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí èèyàn tó mọ ọ̀la, Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ ọ́n. Nínú Bíbélì, ó sọ bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáyé yìí lọ́jọ́ iwájú.​—Àìsáyà 46:10; Jémíìsì 4:14.

2, 3. Kí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fẹ́ mọ̀, báwo sì ni Jésù ṣe dá wọn lóhùn?

2 Tá a bá kà nípa òpin ayé nínú Bíbélì, kò túmọ̀ sí pé ayé tá a wà nínú ẹ̀ yìí ló máa pa run, àmọ́ ó túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn burúkú máa pa run. Jésù kọ́ àwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso ayé. (Lúùkù 4:43) Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fẹ́ mọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé, wọ́n béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: “Ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Jésù ò sọ àkókò kan pàtó fún wọn, àmọ́ ó sọ àwọn ohun táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òpin ayé ti sún mọ́lé. Àwọn ohun tí Jésù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ló tí ń ṣẹlẹ̀ báyìí.

3 Ní orí yìí, a máa jíròrò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àkókò tó ṣáájú òpin ayé la wà yìí. Àmọ́, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀ nípa ogun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run ká lè lóye ìdí tí ìwà burúkú fi pọ̀ láyé.

OGUN TÓ ṢẸLẸ̀ NÍ Ọ̀RUN

4, 5. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù di Ọba? (b) Bí Ìfihàn 12:12 ṣe sọ, kí ló ṣẹlẹ̀ láyé lẹ́yìn tí wọ́n lé Sátánì wá sáyé?

4 Orí 8, a kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jésù ṣe di ọba ní ọ̀run lọ́dún 1914. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Ìwé Ìfihàn sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì [ìyẹn Jésù] àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì [ìyẹn Sátánì] náà jà, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jà.” * Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò borí nínú ogun náà, wọ́n sì lé wọn kúrò lọ́run wá sáyé. Ẹ ò rí i pé inú àwọn áńgẹ́lì máa dùn gan-an! Àmọ́, àwọn èèyàn tó wà láyé ńkọ́? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò wàhálà ló máa jẹ́ fún aráyé. Kí nìdí? Ìdí ni pé Èṣù ń bínú gan-an, “ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun.”​—Ìfihàn 12: 7, 9, 12.

5 Èṣù ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti dá wàhálà sílẹ̀ láyé. Ó ń bínú gan-an, torí pé Jèhófà ò ní pẹ́ pa á run. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ohun tí Jésù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 24.

ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN

6, 7. Kí la lè sọ nípa ogun àti ebi ní àkókò wa yìí?

6 Ogun. Jésù sọ pe: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:7) Ogun ti pa ọ̀pọ̀ èèyàn ní àkókò wa yìí ju ti ìgbà èyíkéyìí lọ nínú ìtàn aráyé. Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí Sí Ohun Tó Ń Lọ́ Láyé fi hàn pé láti ọdún 1914, ogun ti pa èèyàn tó ju ọgọ́rùn-ún (100) mílíọ̀nù lọ. Iye èèyàn tí ogun pa láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún, ìyẹn láti ọdún 1900 sí ọdún 2000 fi ìlọ́po mẹ́ta ju iye tí ogun pa ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (1,900) ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Ẹ wo ìbànújẹ́ àti ìrora ńláǹlà tí ogun ti fà fún àìmọye èèyàn!

7 Ebi. Jésù sọ pé: “Àìtó oúnjẹ . . . máa wà.” (Mátíù 24:7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ tá à ń pèsè báyìí ti pọ̀ gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò jẹun kánú. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọn ò ní owó tó tó láti ra oúnjẹ tàbí ilẹ̀ tí wọ́n lè fi dáko. Àìmọye èèyàn ló jẹ́ pé owó táṣẹ́rẹ́ ni wọ́n ń rí ná lójúmọ́. Kódà, Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ìlera Lágbàáyé sọ pé àìmọye ọmọdé ló ń kú lọ́dọọdún torí pé wọn ò rí oúnjẹ aṣaralóore tó pọ̀ tó jẹ.

8, 9. Báwo la ṣe mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa ìmìtìtì ilẹ̀ àti àrùn ti ṣẹ?

8 Ìmìtìtì ilẹ̀. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé.” (Lúùkù 21:11) Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára gan-an ti wá di ohun tó ń wáyé lọ́dọọdún. Láti ọdún 1900, ìmìtìtì ilẹ̀ ti pa àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀síwájú tó ti bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mú kó ṣeé ṣe láti tètè mọ̀ tí ìmìtìtì ilẹ̀ bá fẹ́ ṣẹlẹ̀, síbẹ̀ ó ṣì ń pa ọ̀pọ̀ èèyàn.

9 Àrùn. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé, “àjàkálẹ̀ àrùn” máa wà. Ìyẹn ni pé, àwọn àrùn tó léwu á tètè máa tàn kálẹ̀, á sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn. (Lúùkù 21:11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn dókítà ti mọ bí wọ́n ṣe máa tọ́jú oríṣiríṣi àìsàn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ àìsàn ni kò gbóògùn. Kódà, ìròyìn kan sọ pé lọ́dọọdún àìmọye èèyàn ló ń kú nítorí àwọn àìsàn bí ikọ́ ẹ̀gbẹ, ibà àti kọ́lẹ́rà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn dókítà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí ọgbọ̀n (30) àrùn míì, àwọn kan lára wọn kò sì gbóògùn.

ÌWÀ TÍ ÀWỌN ÈÈYÀN Á MÁA HÙ NÍ ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN

10. Kí ló fi hàn pé 2 Tímótì 3:​1-5 ti ń ṣẹ lóde òní?

10 2 Tímótì 3:1-5, Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ bí ìwà àwọn èèyàn ṣe máa rí láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ó sọ pé

  • wọ́n á nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan

  • wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó

  • wọ́n á máa ṣàìgbọràn sáwọn òbí wọn

  • wọ́n á jẹ́ aláìṣòótọ́

  • wọn ò ní nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn

  • wọn ò ní lè kó ara wọn níjàánu

  • wọ́n á jẹ́ oníwà ipá àti oníjàgídíjàgan

  • wọ́n á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run

  • wọ́n á jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run, àmọ́ ìwà wọn ò ní fi hàn bẹ́ẹ̀

11. Bí Sáàmù 92:7 ṣe sọ, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn burúkú?

11 Ṣé bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń hùwà lágbègbè ẹ nìyẹn? Ìwà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń hù kárí ayé nìyẹn. Àmọ́ Ọlọ́run máa wá nǹkan ṣe sí i láìpẹ́. Ó ṣèlérí pé: “Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bíi koríko, tí gbogbo àwọn aṣebi sì gbilẹ̀, kí wọ́n lè pa run títí láé ni.”​—Sáàmù 92:7.

ÌRÒYÌN AYỌ̀ MÁA WÀ NÍ ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN

12, 13. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti kọ́ wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

12 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìrora àti ìyà máa kún inú ayé. Àmọ́, Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn nǹkan rere máa ṣẹlẹ̀.

“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”​—Mátíù 24:14

13 A máa túbọ̀ lóye Bíbélì. Nígbà tí wòlíì Dáníẹ́lì ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn, ó ní: “Ìmọ̀ tòótọ́ sì máa pọ̀ yanturu.” (Dáníẹ́lì 12:4) Ìyẹn ni pé, Ọlọ́run máa jẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ túbọ̀ lóye Bíbélì ju bí wọ́n ṣe lóye rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Jèhófà sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì láti ọdún 1914. Bí àpẹẹrẹ, ó ti jẹ́ ká mọ bí orúkọ rẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó àti ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé. Ó tún kọ́ wa ní òtítọ́ nípa ìràpadà, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú àti àjíǹde. A tún ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro wa. A sì tún ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀ àti bá a ṣe lè gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Àmọ́, kí ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń fi ohun tí wọ́n ti kọ́ yìí ṣe? Àsọtẹ́lẹ̀ míì dáhùn ìbéèrè yìí.​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 21 àti 25.

14. Ibo ni ìhìn rere nípa Ìjọba náà ti dé? Àwọn wo ló sì ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà?

14 Iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” (Mátíù 24:3, 14) À ń wàásù Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ohun tó ju igba ó lé ọgbọ̀n (230) ilẹ̀ lọ àti ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje (700). Ìyẹn ni pé, kárí ayé ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà látinú “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà” ti ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí ìjọba náà jẹ́ àti ohun tó máa ṣe fún aráyé. (Ìfihàn 7:9) Ọ̀fẹ́ sì ni wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ kórìíra wọn bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wọn, kò sí ohun tó lè dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró.​—Lúùkù 21:17.

KÍ LO MÁA ṢE?

15. (a) Ṣé o gbà pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí, kí sì nìdí tó o fi gbà bẹ́ẹ̀? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tí ò ṣègbọràn?

15 Ṣé o gbà pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí? Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ọjọ́ ìkẹyìn ló ti ń ṣẹ. Láìpẹ́, Jèhófà máa dá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà dúró, lẹ́yìn náà “òpin” á dé. (Mátíù 24:14) Kí ni òpin náà? Amágẹ́dọ́nì ni, ìyẹn ìgbà tí Ọlọ́run máa mú gbogbo ìwà burúkú kúrò. Tí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, Jèhófà máa lo Jésù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára láti pa ẹni yẹn run. (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Lẹ́yìn náà, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò tún ní ṣi àwọn èèyàn lọ́nà mọ́. Gbogbo àwọn tó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run tí wọ́n sì fara mọ́ Ìjọba rẹ̀ máa rí bí gbogbo ìlérí Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ.​—Ìfihàn 20:1-3; 21:3-5.

16. Bí òpin ṣe ń sún mọ́lé, kí ló yẹ kó o ṣe?

16 Ayé tí Sátánì ń ṣàkóso rẹ̀ yìí máa dópin láìpẹ́. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kó o bi ara rẹ pé, ‘Kí ló yẹ kí n ṣe?’ Jèhófà fẹ́ kó o kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan látinú Bíbélì, ó sì fẹ́ kó o fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ. (Jòhánù 17:3) Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ìpàdé láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Bíbélì. Gbìyànjú kó o máa lọ sáwọn ìpàdé yẹn déédéé. (Ka Hébérù 10:24, 25.) Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kó o yí àwọn ìwà kan pa dà, má ṣe bẹ̀rù láti ṣe àwọn àyípadà náà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ máa sún mọ́ Ọlọ́run.​—Jémíìsì 4:8.

17. Kí nìdí tó fi máa ya àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ lẹ́nu nígbà tí òpin bá dé?

17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé ìparun àwọn èèyàn burúkú máa dé lójijì “bí olè ní òru.” (1 Tẹsalóníkà 5:2) Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìfiyèsí àwọn àmì tó fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. Ó sọ pé: “Torí bí àwọn ọjọ́ Nóà ṣe rí gẹ́lẹ́ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín [tàbí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn]. Torí bó ṣe rí ní àwọn ọjọ́ yẹn ṣáájú Ìkún Omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fa àwọn obìnrin fún ọkọ, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì, wọn ò fiyè sí i títí Ìkún Omi fi dé, tó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ èèyàn máa rí.”​—Mátíù 24:37-39.

18. Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fún wa?

18 Jésù kìlọ̀ pe a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí “àjẹjù, ọtí àmujù àti àníyàn ìgbésí ayé” pín ọkàn wa níyà. Ó ní òpin máa dé lójijì “bí ìdẹkùn.” Ó tún sọ pé “ó máa dé bá gbogbo àwọn tó ń gbé ní gbogbo ayé.” Lẹ́yìn náà, ó wá sọ pé: “Ẹ máa wà lójúfò, kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ [tàbí kí ẹ máa gba àdúrà àtọkànwá] nígbà gbogbo, kí ẹ lè bọ́ nínú gbogbo nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ yìí, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ èèyàn.” (Lúùkù 21:​34-36) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fetí sí ìkìlọ̀ Jésù? Torí pé láìpẹ́, ayé burúkú tí Sátánì ń ṣàkóso, yìí máa pa run. Àwọn tó bá rí ojú rere Jèhófà àti Jésù nìkan ló máa la òpin náà já, tí wọ́n á sì máa gbé títí láé nínú ayé tuntun.​—Jòhánù 3:16; 2 Pétérù 3:13.

^ ìpínrọ̀ 4 Máíkẹ́lì ni orúkọ míì tí Jésù Kristi ń jẹ́. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo Àlàyé Ìparí Ìwé 23.