Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸWÀÁ

Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì

Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì?

JÈHÓFÀ fẹ́ ká mọ àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì sì wà lára ìdílé Ọlọ́run. Nínú Bíbélì, a pè wọ́n ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Jóòbù 38:7) Kí ni iṣẹ́ àwọn áńgẹ́lì? Báwo ni wọ́n ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà àtijọ́? Ṣé wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ lónìí?​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 8.

2. Tá ló dá àwọn áńgẹ́lì? Áńgẹ́lì mélòó ló wà?

2 Ó yẹ ká mọ ibi tí àwọn áńgẹ́lì ti wá. Kólósè 1:16 jẹ́ ká mọ̀ pé lẹ́yìn tí Jèhófà dá Jésù, ó “dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé.” Àwọn áńgẹ́lì sì wà lára wọn. Áńgẹ́lì mélòó ló wà? Bíbélì sọ pé àìmọye àwọn áńgẹ́lì ló wà.​—Sáàmù 103:20; Ìfihàn 5:11.

3. Kí ni Jóòbù 38:​4-7 sọ fún wa nípa àwọn áńgẹ́lì?

3 Bíbélì tún kọ́ wa pé Jèhófà ti dá àwọn áńgẹ́lì kó tó dá ayé. Báwo ló ṣe ri lára àwọn áńgẹ́lì nígbà tí wọ́n rí ayé? Ìwé Jóòbù sọ fún wa pé inú wọn dùn gan-an. Wọ́n jẹ́ ìdílé kan tó ń sin Jèhófà ní ìṣọ̀kan.​—Jóòbù 38:4-7.

ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ MÁA Ń RAN ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN LỌ́WỌ́

4. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn?

4 Látìgbà tí Ọlọ́run ti dá àwọn áńgẹ́lì ni wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Àwọn áńgẹ́lì fẹ́ mọ ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún ayé àtohun tó fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn. (Òwe 8:30, 31; 1 Pétérù 1:11, 12) Ó dájú pé inú wọn á bà jẹ́ gan-an nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀. Ńṣe ni á sì túbọ̀ máa dùn wọ́n bí wọ́n ṣe ń rí i pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ló ń ṣàìgbọràn sí Jèhófà lónìí. Àmọ́, tí ẹnì kan bá ronú pìwà dà, tó sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, inú àwọn áńgẹ́lì máa ń dùn gan-an. (Lúùkù 15:10) Àwọn áńgẹ́lì fẹ́ràn àwọn tó ń sin Ọlọ́run. Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà láyé, ó sì máa ń lo àwọn áńgẹ́lì láti dáàbò bò wọ́n. (Hébérù 1:7, 14) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.

“Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún náà lẹ́nu.”​—Dáníẹ́lì 6:22

5. Báwo ni àwọn áńgẹ́lì ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ nígbà àtijọ́?

5 Nígbà tí Jèhófà fẹ́ pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run, ó rán áńgẹ́lì méjì láti lọ ran Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa pa run. (Jẹ́nẹ́sísì 19:15, 16) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn kan ju wòlíì Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún, àmọ́ àwọn kìnnìún náà kò pa á jẹ, torí pé ‘Ọlọ́run rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà.’ (Dáníẹ́lì 6:22) Àpẹẹrẹ míì ni ti àpọ́sítélì Pétérù, nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan láti tú u sílẹ̀. (Ìṣe 12:6-11) Àwọn áńgẹ́lì tún ran Jésù lọ́wọ́ nígbà tó wà láyé. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tó ṣe ìrìbọmi, ‘àwọn áńgẹ́lì ṣe ìránṣẹ́ fún un.’ (Máàkù 1:13) Nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n pa Jésù, áńgẹ́lì kan tún “fún un lókun.”​—Lúùkù 22:43.

6. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì máa ń ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ lóde òní? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn báyìí?

6 Lónìí, àwọn áńgẹ́lì kì í fara han àwa èèyàn mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Àmọ́, Ọlọ́run ṣì máa ń lo àwọn áńgẹ́lì láti ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà pàgọ́ yí àwọn tó bẹ̀rù Rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.” (Sáàmù 34:7) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń lo àwọn áńgẹ́lì láti máa dáàbò bò wá? Torí pé a ní àwọn ọ̀tá tó jẹ́ alágbára, tí wọ́n fẹ́ ṣèkà fún wa. Ta ni wọ́n? Ibo ni wọ́n ti wá? Ọ̀nà wo ni wọ́n fẹ́ gbà ṣèkà fún wa? Ká lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà.

ÀWỌN Ọ̀TÁ WA TÁ Ò LÈ RÍ

7. Kí ni àwọn èèyàn ṣe nítorí pé Sátánì tàn wọ́n jẹ?

7 A kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí 3 pé áńgẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, ó sì fẹ́ máa darí àwọn èèyàn. Bíbélì pe áńgẹ́lì náà ní Sátánì Èṣù. (Ìfihàn 12:9) Sátánì ti mú kí àwọn èèyàn kan ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó tan Éfà jẹ, látìgbà yẹn sì ló ti ń tan ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ. Àmọ́, àwọn kan jẹ́ olóòótọ́. Díẹ̀ lára wọn ni Ébẹ́lì, Énọ́kù àti Nóà.​—Hébérù 11:4, 5, 7.

8. (a) Báwo ni àwọn áńgẹ́lì kan ṣe di ẹ̀mí èṣù? (b) Kí ni àwọn ẹ̀mí èṣù ṣe tí wọn ò fi kú nígbà Ìkún Omi?

8 Nígbà ayé Nóà, àwọn áńgẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n kúrò ní ọ̀run, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé bí èèyàn. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ńṣe ni àwọn áńgẹ́lì náà wá sí ayé torí kí wọ́n lè fẹ́ ìyàwó. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:2.) Àmọ́, kò tọ́ fún àwọn áńgẹ́lì láti ṣe ohun tí wọ́n ṣe yẹn. (Júùdù 6) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn láyé ìgbà yẹn wá bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ìbàjẹ́ àti ìwà ipá bíi ti àwọn áńgẹ́lì burúkú yẹn. Jèhófà wá pinnu pé òun máa fi ìkún omi pa àwọn èèyàn burúkú run. Àmọ́, ó gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ là. (Jẹ́nẹ́sísì 7:17, 23) Kí àwọn áńgẹ́lì burúkú yẹn má bàa kú, wọ́n pa dà sí ọ̀run. Bíbélì pe àwọn áńgẹ́lì burúkú yẹn ní ẹ̀mí èṣù. Wọ́n dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, Èṣù sì wá di alákòóso wọn.​—Mátíù 9:34.

9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹ̀mí èṣù nígbà tí wọ́n pa dà sí ọ̀run? (b) Kí ló kàn tá a máa kẹ́kọ̀ọ́?

9 Torí pé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jẹ́ ọlọ̀tẹ̀, Jèhófà kò gbà wọ́n pa dà láti dara pọ̀ mọ́ ìdílé rẹ̀. (2 Pétérù 2:4) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù náà kò lè para dà di èèyàn mọ́, síbẹ̀ wọ́n ṣì ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà.” (Ìfihàn 12:9; 1 Jòhánù 5:19) Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń tan ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ.​—Ka 2 Kọ́ríńtì 2:11.

BÍ ÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ ṢE Ń TAN ÀWỌN ÈÈYÀN JẸ

10. Báwo ni àwọn ẹ̀mí èṣù ṣe máa ń tan àwọn èèyàn jẹ?

10 Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn ẹ̀mí èṣù máa ń gbà tan àwọn èèyàn jẹ. Táwọn èèyàn bá fẹ́ bá ẹ̀mí èṣù lò, wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ fúnra wọn, wọ́n sì lè lọ sọ́dọ̀ àwọn babaláwo tàbí àwọn aríran. Irú àṣà yìí àti àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ọn ni wọ́n ń pè ní ìbẹ́mìílò. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pàṣẹ fún wa pé ká sá fún ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù. (Gálátíà 5:19-21) Bí ọdẹ kan ṣe máa ń lo pańpẹ́ láti mú àwọn ẹranko, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹ̀mí èṣù ṣe máa ń lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti tan àwọn èèyàn jẹ kí wọ́n lè máa darí wọn.​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 26.

11. Kí ni iṣẹ́ wíwò, kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ yẹra fún un?

11 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà táwọn ẹ̀mí èṣù ń gbà tan àwọn èèyàn jẹ ni iṣẹ́ wíwò. Ìyẹn ni pé kí èèyàn máa lo agbára òkùnkùn láti wádìí nípa ọjọ́ ọ̀la tàbí ohun tí èèyàn kò mọ̀. Díẹ̀ lára ohun tí wọ́n máa ń lò ni wíwo ìràwọ̀, wíwá àmì, wíwo káàdì, gíláàsì tàbí àtẹ́lẹwọ́ láti sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé àwọn àṣà yìí ò burú, àmọ́ ó burú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹ̀mí èṣù àti àwọn tó ń woṣẹ́ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ni. Nínú ìwé Ìṣe 16:​16-18, a kà nípa “ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́” tó ń jẹ́ kí ọmọbìnrin kan máa ‘woṣẹ́.’ Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọmọbìnrin náà kò ní agbára láti máa woṣẹ́ mọ́.

12. (a) Kí nìdí tó fi léwu láti bá òkú sọ̀rọ̀? (b) Kí nìdí tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò fi gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìbẹ́mìílò?

12 Àwọn ẹ̀mí èṣù tún máa ń lo ọ̀nà míì láti tan àwọn èèyàn jẹ. Wọ́n ń fẹ́ káwọn èèyàn gbà gbọ́ pé a lè bá òkú sọ̀rọ̀ àti pé àwọn tó ti kú ṣì wà láàyè níbì kan, wọ́n sì lè bá wa sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n ṣe wá ní jàǹbá. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tàbí ìbátan rẹ̀ ti kú lè lọ bá abẹ́mìílò kan tó gbà pé ó lè bá òkú sọ̀rọ̀. Abẹ́mìílò náà lè sọ ohun kan nípa ẹni tó ti kú yẹn tó máa jẹ́ kí inú ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan rẹ̀ dùn tàbí kó dọ́gbọ́n yí ohùn rẹ̀ pa dà bíi pé ẹni tó ti kú náà ló ń sọ̀rọ̀. (1 Sámúẹ́lì 28:3-19) Ọ̀pọ̀ àwọn àṣà ìsìnkú ló dá lórí ìgbàgbọ́ pé àwọn òkú ṣì wà láàyè níbì kan. Díẹ̀ lára àwọn àṣà náà ni ayẹyẹ ìsìnkú, ayẹyẹ òkú ẹ̀gbẹ, títu àwọn òkú lójú, ààtò ṣíṣe opó tàbí ṣíṣe àìsùn òkú. Tí àwa Kristẹni bá kọ̀ láti bá wọn dá sí irú àwọn àṣà yìí, àwọn ẹbí tàbí ará ìlú lè máa bú wa tàbí kí wọ́n pa wá tì. Àmọ́, àwa Kristẹni mọ̀ pé àwọn òkú kò sí láàyè níbì kankan. A ò lè bá wọn sọ̀rọ̀, wọn ò sì lè ṣe wá ní jàǹbá. (Sáàmù 115:17) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra! Kò yẹ ká máa wá bá a ṣe máa bá òkú tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù sọ̀rọ̀, a ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí àṣà ìbẹ́mìílò kankan.​—Ka Diutarónómì 18:10, 11; Àìsáyà 8:19.

13. Kí ni ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù tẹ́lẹ̀ ti ṣe?

13 Yàtọ̀ sí pé àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń tan àwọn èèyàn jẹ, wọ́n tún máa ń dẹ́rù bà wọ́n. Lónìí, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ mọ̀ pé “ìgbà díẹ̀” ló kù tí Ọlọ́run máa pa àwọn run. Torí náà, wọ́n ń bínú gan-an, wọ́n sì túbọ̀ ń hùwà ipá tó burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. (Ìfihàn 12:12, 17) Àmọ́, àìmọye èèyàn tó ń bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù ni kò bẹ̀rù wọn mọ́. Báwo ni wọ́n ṣe bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù?

GBÉJÀ KO ÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ KÓ O SÌ BỌ́ LỌ́WỌ́ WỌN

14. Báwo la ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù bíi ti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?

14 Bíbélì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gbéjà ko àwọn ẹ̀mí èṣù ká a sì bọ́ lọ́wọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn kan ní ìlú Éfésù ti bá àwọn ẹ̀mí èṣù lò kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Báwo ni wọ́n ṣe bọ́? Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń pidán kó àwọn ìwé wọn jọ, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo èèyàn.” (Ìṣe 19:19) Torí pé wọ́n fẹ́ di Kristẹni, wọ́n sun gbogbo àwọn ìwé tí wọ́n fi ń pidán. Ó ṣe pàtàkì pé kí ìwọ náà ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Àwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà gbọ́dọ̀ kó gbogbo ohun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù dà nù. Èyí kan àwọn ìwé, wíwo ìràwọ̀, àwọn fíìmù, orin, géèmù, àwọn bébà ara ògiri tó ní àwòrán ẹ̀mí èṣù tàbí agbára abàmì tàbí ohunkóhun tó lè mú kí ìbẹ́mìílò dà bí ohun tí kò léwu. Ó tún kan oríṣiríṣi nǹkan táwọn èèyàn máa ń lò sára láti fi dáàbò bo ara wọn.​—1 Kọ́ríńtì 10:21.

15. Kí la tún lè ṣe láti gbéjà ko Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù?

15 Lẹ́yìn ọdún mélòó kan táwọn Kristẹni ní Éfésù dáná sun ìwé tí wọ́n fi ń pidán, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn pé wọ́n ṣì tún ní “ìjà” kan “pẹ̀lú agbo ọmọ ogun àwọn ẹ̀mí burúkú.” (Éfésù 6:12) Òótọ́ ni, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sun àwọn ìwé tí wọ́n fi ń pidán, síbẹ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù náà ṣì ń wá ọ̀nà láti ṣe wọ́n ní jàǹbá. Torí náà, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe? Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, tí ẹ ó fi lè paná gbogbo ọfà oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfésù 6:16) Bí apata ṣe máa ń dáàbò bo ṣọ́jà kan lójú ogun, ìgbàgbọ́ wa lè dáàbò bò wá. Tá a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó lágbára pé Jèhófà lè dáàbò bò wá, àá lè gbéjà ko Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù.​—Mátíù 17:20.

16. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà lágbára sí i?

16 Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà lágbára sí i? Ìgbàgbọ́ wa máa lágbára tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ láti gbára lé Jèhófà fún ààbò. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò ní lè ṣe wá ní jàǹbá.​—1 Jòhánù 5:5.

17. Kí ni ohun míì tó lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù?

17 Kí ló tún kù tó yẹ káwọn Kristẹni ní Éfésù ṣe? Torí pé wọ́n ń gbé ní ìlú tí ìbẹ́mìílò ti pọ̀ gan-an, Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa gbàdúrà ní gbogbo ìgbà.” (Éfésù 6:18) Ó yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Jèhófà dáàbò bò wọ́n nígbà gbogbo. Àwa náà ńkọ́? Inú ayé tí ìbẹ́mìílò ti pọ̀ gan-an là ń gbé. Torí náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà máa dáàbò bò wá, ká sì máa lo orúkọ rẹ̀ tá a bá ń gbàdúrà. (Ka Òwe 18:10.) Tá a bá ń gbàdúrà pé kí Jèhófà gbà wá lọ́wọ́ Sátánì, Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa.​—Sáàmù 145:19; Mátíù 6:13.

18, 19. (a) Báwo la ṣe lè borí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù? (b) Ìbéèrè wo la máa dáhùn ní orí tó kàn?

18 Tá a bá mú gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò kúrò ní ìgbésí ayé wa, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bò wá, a máa lè gbéjà ko Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù. Torí náà, kò yẹ ká máa bẹ̀rù wọn. (Ka Jémíìsì 4:7, 8.) Jèhófà lágbára ju àwọn ẹ̀mí èṣù lọ ní gbogbo ọ̀nà. Ó fìyà jẹ wọ́n nígbà ayé Nóà, tó bá sì di ọjọ́ iwájú, ó máa pa wọ́n run. (Júùdù 6) Máa rántí pé Jèhófà kò fi wá sílẹ̀ láti dá ìjà náà jà. Ó máa ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti dáàbò bò wá. (2 Àwọn Ọba 6:15-17) Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, a sì máa borí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù.​—1 Pétérù 5:6, 7; 2 Pétérù 2:9.

19 Àmọ́, tó bá jẹ́ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá, kí nìdí tí Ọlọ́run kò ṣe tíì pa wọ́n run? A máa dáhùn ìbéèrè yìí ní orí tó kàn.