Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸRÌNLÁ

Bí Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀

Bí Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀

1, 2. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn ìdílé ní?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ló so tọkọtaya àkọ́kọ́ pọ̀. Bíbélì sọ fún wa pé òun ló dá obìnrin àkọ́kọ́, “ó sì mú un wá fún ọkùnrin náà.” Inú Ádámù dùn gan-an débi tó fi sọ pé: “Èyí gan-an ni egungun látinú egungun mi àti ẹran ara látinú ẹran ara mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:22, 23) Èyí fi hàn pé Jèhófà fẹ́ káwọn tọkọtaya láyọ̀.

2 Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni ìdílé wọn ò láyọ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìlànà ló wà nínú Bíbélì tó lè ran gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé lọ́wọ́ kí ìdílé wọn lè láyọ̀, kí wọ́n sì máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà.​—Lúùkù 11:28.

OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÍ ÀWỌN ỌKỌ MÁA ṢE

3, 4. (a) Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ máa ṣe sí ìyàwó rẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ọkọ àti ìyàwó máa dárí ji ara wọn?

3 Bíbélì sọ pé ó yẹ kí ọkọ tó dáa máa fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bá ìyàwó rẹ̀ gbé. Jọ̀ọ́ ka Éfésù 5:25-29. Ìgbà gbogbo ló yẹ kí ọkọ máa fi ìfẹ́ bá ìyàwó rẹ̀ gbé. Ó tún yẹ kó máa dáàbò bò ó, kó máa tọ́jú rẹ̀, kó má sì ṣe ohunkohun tó lè pa á lára.

4 Àmọ́, kí ló yẹ kí ọkọ ṣe tí ìyàwó rẹ̀ bá ṣàṣìṣe. Bíbélì sọ fún àwọn ọkọ pé: “Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà òdì.” (Kólósè 3:19) Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa rántí pé ẹ̀yin náà máa ń ṣàṣìṣe. Tẹ́ ẹ bá sì fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì yín, ẹ gbọ́dọ̀ máa dárí jí ìyàwó yin. (Mátíù 6:12, 14, 15) Tí ọkọ àti ìyàwó bá múra tán láti dárí ji ara wọn, ó máa jẹ́ kí ìgbéyàwó wọn láyọ̀.

5. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkọ máa bọlá fún ìyàwó rẹ̀?

5 Jèhófà fẹ́ kí ọkọ máa bọlá fún ìyàwó rẹ̀. Ó yẹ kí ọkọ máa ronú dáadáa nípa àwọn ohun tí ìyàwó rẹ̀ nílò. Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an. Tí ọkọ ò bá hùwà tó dáa sí ìyàwó rẹ̀, Jèhófà ò ní gbọ́ àdúrà rẹ̀. (1 Pétérù 3:7) Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló mú ká ṣeyebíye lójú rẹ̀. Ọlọ́run ò sì sọ pé ọkùnrin ló dáa ju obìnrin lọ.

6. Kí ló túmọ̀ sí pé kí ọkọ àti ìyàwó jẹ́ “ara kan”?

6 Jésù sọ nípa ọkọ àti ìyàwó pé, “wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan.” (Mátíù 19:6) Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn, wọn ò sì gbọ́dọ̀ dalẹ̀ ara wọn. (Òwe 5:15-21; Hébérù 13:4) Ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ máa tẹ́ ẹnì kejì rẹ̀ lọ́rùn nínú ọ̀ràn ìbálòpọ̀, wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. (1 Kọ́ríńtì 7:3-5) Kí ọkọ máa rántí pé “kò sí èèyàn kankan tó jẹ́ kórìíra ara rẹ̀, àmọ́ á máa bọ́ ara rẹ̀, á sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.” Torí náà, ó ní láti máa nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀. Ohun tí ìyàwó ń fẹ́ jù lọ ni pé kí ọkọ òun máa ṣe òun jẹ́jẹ́, kó sì máa fi ìfẹ́ hàn sí òun.​—Éfésù 5:29.

OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÍ ÀWỌN ÌYÀWÓ MÁA ṢE

7. Kí nìdí tí ìdílé fi nílò olórí ìdílé?

7 Gbogbo ìdílé ló nílò olórí tá a máa tọ́ ìdílé sọ́nà, kí wọ́n bàa lè máa ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan. Bíbélì sọ ní 1 Kọ́ríńtì 11:3 pé: “Orí gbogbo ọkùnrin ni Kristi; bákan náà, orí obìnrin ni ọkùnrin; bákan náà, orí Kristi ni Ọlọ́run.”

8. Báwo ni ìyàwó ṣe lè ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀?

8 Gbogbo ọkọ ló máa ń ṣàṣìṣe. Àmọ́ tí ìyàwó bá ń ti ìpìnnu ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tó sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ tinútinú, gbogbo ìdílé ló máa jàǹfààní rẹ̀. (1 Pétérù 3:1-6) Bíbélì sọ pé: “Kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Bí ẹ̀sìn ìyàwó bá yàtọ̀ sí ti ọkọ rẹ̀ ńkọ́? Ìyàwó rẹ̀ ṣì gbọ́dọ̀ ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ̀yin aya máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ yín, kó lè jẹ́ pé, tí a bá rí ẹnikẹ́ni tí kò ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, a máa lè jèrè wọn nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn láìsọ ohunkóhun, torí pé wọ́n fojú rí ìwà mímọ́ yín pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:1, 2) Àpẹẹrẹ rere ìyàwó lè ran ọkọ lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ìyàwó rẹ̀ gbà gbọ́, kó sì máa bọ̀wọ̀ fún ohun tí ìyàwó rẹ̀ gbà gbọ́.

9. (a) Kí ló yẹ kí ìyàwó ṣe tí kò bá fara mọ́ èrò ọkọ rẹ̀? (b) Ìmọ̀ràn wo ló wà fún àwọn ìyàwó ní Títù 2:4, 5?

9 Kí ni ìyàwó lè ṣe tí kò bá fara mọ́ èrò ọkọ rẹ̀? Ó yẹ kó ṣàlàyé èrò rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Sérà sọ ohun kan ti inú Ábúráhámù ò dùn sí, àmọ́ Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: “Fetí sí ohùn rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 21:9-12) Ó ṣọ̀wọ́n pé kí ìpinnu ọkọ tó jẹ́ Kristẹni ta ko ohun tí Bíbélì sọ, torí náà, ó yẹ kí ìyàwó rẹ̀ máa tì í lẹ́yìn. (Ìṣe 5:29; Éfésù 5:24) Ìyàwó tó dáa máa ń tọ́jú ìdílé rẹ̀. (Ka Títù 2:4, 5.) Nígbà tí ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ bá rí bó ṣe ń ṣiṣẹ́ kára nítorí wọn, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, wọ́n á sì túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún un.​—Òwe 31:10, 28.

Báwo ni Sérà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn aya?

10. Kí ni Bíbélì sọ nípa ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀?

10 Nígbà míì, àwọn tọkọtaya máa ń kánjú ṣe ìpinnu láti pínyà tàbí láti kọ ara wọn sílẹ̀. Àmọ́, Bíbélì sọ pé, “kí aya má ṣe kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀” àti pé “kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:10, 11) Àwọn ìgbà míì wà tí ipò nǹkan máa ń le débi pé tọkọtaya lè pínyà, àmọ́ ìpinnu yẹn gba pé kéèyàn ronú jinlẹ̀. Ìkọ̀sílẹ̀ ńkọ́? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìdí kan ṣoṣo tó bófin mu tí ọkọ àti aya lè fi kọ ara wọn sílẹ̀ ni tí ẹnì kan nínú wọn bá ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì.​—Mátíù 19:9.

OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÍ ÀWỌN ÒBÍ MÁA ṢE

Jésù jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn tó wà nínú ìdílé

11. Kí làwọn ọmọ nílò jù lọ?

11 Ẹ̀yin òbí, ẹ máa lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú àwọn ọmọ yin. Àwọn ọmọ yín ń fẹ́ àbójútó yín. Ohun tí wọ́n sì nílò jù lọ ni pé kí ẹ kọ́ wọn nípa Jèhófà.​—Diutarónómì 6:4-9.

12. Kí ló yẹ káwọn òbí ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn?

12 Ńṣe ni ayé Sátánì yìí túbọ̀ ń burú sí i, àwọn èèyàn kan sì wà tí wọ́n fẹ́ pa àwọn ọmọ wa lára, kódà wọ́n lè fẹ́ bá wọn ṣèṣekúṣe. Ó máa ń nira fún àwọn òbí kan láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́, ó yẹ káwọn òbí kìlọ̀ fún àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má bàa kó sọ́wọ́ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa yẹra fún wọn. Ẹ̀yin òbí, ẹ gbọ́dọ̀ dáàbò bo àwọn ọmọ yín. *​—1 Pétérù 5:8.

13. Báwo ló ṣe yẹ káwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn?

13 Ojúṣe àwọn òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà. Báwo lo ṣe yẹ kó o máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ? Àwọn ọmọ rẹ nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ ìbáwí tó o máa fún wọn kò gbọ́dọ̀ le jù. (Jeremáyà 30:11) Torí náà, má ṣe bá àwọn ọmọ rẹ wí nígbà tí inú bá ń bí ẹ. Ọ̀rọ̀ rẹ ò gbọ́dọ̀ “dà bí ìgbà tí idà gúnni,” kó sì ṣe wọ́n léṣe. (Òwe 12:18) Kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa gbọ́ràn.​—Éfésù 6:4; Hébérù 12:9-11; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 30.

OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÍ ÀWỌN ỌMỌ MÁA ṢE

14, 15. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn ọmọ máa ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn?

14 Jésù máa ń ṣègbọràn sí Baba rẹ̀ nígbà gbogbo, kódà títí kan ìgbà tí kò rọrùn fún un. (Lúùkù 22:42; Jòhánù 8:28, 29) Lọ́nà kan náà, Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu.​—Éfésù 6:1-3.

15 Ẹ̀yin ọmọ, tẹ́ ẹ bá tiẹ̀ rò pé ó ṣòro fún yín láti gbọ́ràn sáwọn òbí yín lẹ́nu, ó yẹ kẹ́ ẹ máa rántí pé tẹ́ ẹ bá ṣègbọràn, inú Jèhófà àtàwọn òbí yín máa dùn sí yín. *​—Òwe 1:8; 6:20; 23:22-25.

Kí ló máa ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá dán wọn wò láti ṣe ohun tí kò dáa?

16. (a) Ọ̀nà wo ni Sátánì ń gbà dán àwọn ọ̀dọ́ wò kí wọ́n lè ṣe ohun tí kò dáa? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o yan àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́?

16 Èṣù lè lo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn ọ̀dọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ láti dán ẹ wò, kó o bàa lè ṣe ohun tí kò dáa. Èṣù mọ̀ pé ó máa ṣòro gan-an láti borí ìdẹwò náà. Bí àpẹẹrẹ̀, àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófa ni Dínà ọmọbìnrin Jékọ́bù yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Èyí sì fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà fún oun àti ìdílé rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2) Tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ò bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n lè mú kó o ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra, èyí sì máa fa ọ̀pọ̀ ẹ̀dùn ọkàn fún ìwọ àti ìdílé rẹ, kò sì ní mú inú Ọlọ́run dùn. (Òwe 17:21, 25) Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé kó o yan àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́.​—1 Kọ́ríńtì 15:33.

BÍ ÌDÍLÉ RẸ ṢE LÈ LÁYỌ̀

17. Kí ni ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé?

17 Tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run fún wọn, á jẹ́ kí wọ́n lè yẹra fún wàhálà àti ọ̀pọ̀ ìṣòro. Torí náà, tó o bá jẹ́ ọkọ, kó o nífẹ̀ẹ́ ìyáwó rẹ kó o sì máa fi ìfẹ́ bá a gbé. Tó o bá jẹ́ ìyàwó, máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ kó o sì máa tẹrí ba fún un, kó o máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìyàwó tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Òwe 31:10-31. Tó o bá jẹ́ òbí, máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Òwe 22:6) Tó o bá jẹ́ bàbá, máa tọ́ ìdílé rẹ sọ́nà “dáadáa.” (1 Tímótì 3:4, 5; 5:8) Kí ẹ̀yin ọmọ sì máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu. (Kólósè 3:20) Ẹ máa rántí pé kò sẹ́ni tí kò lè ṣàṣìṣe nínú ìdílé, torí náà ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kẹ́ ẹ sì máa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ara yín. Ó dájú pé, àwọn ìtọ́sọ́nà Jèhófà tó lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé lọ́wọ́ wà nínú Bíbélì.

^ ìpínrọ̀ 12 O lè rí ìsọfúnni púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ ní orí 32 ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ ìpínrọ̀ 15 Ọmọ kan kò ní ṣègbọràn táwọn òbí rẹ̀ bá ní kó ṣe ohun tó ta ko òfin Ọlọ́run.​—Ìṣe 5:29.