Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KỌKÀNDÍNLÓGÚN

Dúró Sọ́dọ̀ Jèhófà

Dúró Sọ́dọ̀ Jèhófà

1, 2. Ibo la ti lè rí ààbò lónìí?

KÁ SỌ pé ò ń rin níta lọ́jọ́ ti ìjì líle kan ń jà. Òkùnkùn ṣú bolẹ̀, mọ̀nàmọ́ná bẹ̀rẹ̀ sí í kọ yẹ̀rì, ààrá sì bẹ̀rẹ̀ sí í sán. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Lo bá wá ibì kan láti sá pa mọ́ sí. Wo bí ará ṣe má tù ẹ́ tó nigbà tó o bá rí ibi ààbò tí àfẹ́sí òjò kò lè dé!

2 Irú ipò yẹn làwa náà wà lónìí. Ńṣe ni nǹkan ń burú sí i láyé yìí. O lè wá béèrè pé, ‘Ibo ni mo ti lè rí ààbò?’ Ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù nínú Bíbélì sọ pé: “Màá sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni ibi ààbò mi àti odi ààbò mi, Ọlọ́run mi tí mo gbẹ́kẹ̀ lé.” (Sáàmù 91:2) Ní báyìí, Jèhófà máa ń tù wá lára nígbà tá a bá níṣòro, ó sì tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ọjọ́ ọ̀la wa máa dára gan-an.

3. Ọ̀nà wo la lè gbà fi Jèhófà ṣe ibi ààbò wa?

3 Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà dáàbò bò wá? Ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tá a ní, ó sì lágbára ju ẹnikẹ́ni tó lè fẹ́ pa wá lára lọ. Kódà tí ohun tó burú bá ṣẹlẹ̀ sí wa ní báyìí, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: ‘Ẹ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.’ (Júùdù 21) Ó yẹ ká dúró sọ́dọ̀ Jèhófà ká lè rí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ gbà tá a bá wà nínú ìṣòro. Àmọ́, ọ̀nà wo la lè gbà ṣe é?

FI HÀN PÉ O MỌYÌ ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN

4, 5. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa?

4 Tá a bá fẹ́ dúró sọ́dọ̀ Jèhófà, ó yẹ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Ronú nípa gbogbo àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa. Ó dá ayé tó rẹwà fún wa, ó sì dá ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ewéko àtàwọn ẹranko tó fani mọ́ra sínú rẹ̀. Ó sì tún fún wa ní oúnjẹ aládùn àti omi tó mọ́ láti mu. Jèhófà jẹ́ ká mọ orúkọ rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ àgbàyanu nínú Bíbélì. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa nígbà tó rán Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. (Jòhánù 3:16) Ẹbọ ìràpadà yẹn ló mú ká máa retí ohun àgbàyanu lọ́jọ́ iwájú.

5 Jèhófà ti ṣètò Ìjọba Mèsáyà, ìjọba ọ̀run yìí ló máa fòpin sí gbogbo ìyà láìpẹ́. Ìjọba náà máa sọ ayé di Párádísè, gbogbo èèyàn á sì máa gbé inú rẹ̀ ní ayọ̀ àti àlàáfíà títí láé. (Sáàmù 37:29) Ọ̀nà míì tí Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa ni pé ó ń kọ́ wa bá a ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa jù lọ nísinsìnyí. Ó tún sọ pé ká máa gbàdúrà sí òun, ó sì ṣe tán láti gbọ́ àdúrà wa nígbà gbogbo. Jèhófà ti fi hàn kedere pé òun nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

6. Báwo lo ṣe máa fi hàn pé o mọyì ìfẹ́ Jèhófà?

6 Báwo lo ṣe máa fi hàn pé o mọyì ìfẹ́ Jèhófà? Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ torí gbogbo ohun tó ti ṣe fún ẹ. Ó ṣeni láàánú pé aláìmoore ni ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí nígbà tí Jésù wà láyé. Ìgbà kan wà tí Jésù wo adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá sàn, àmọ ẹnì kan ṣoṣo nínú wọn lo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Lúùkù 17:12-17) Ó yẹ ká dà bí ọkùnrin tó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù yẹn. Ó yẹ kí àwa náà máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nígbà gbogbo.

7. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe yẹ kó pọ̀ tó?

7 Ó tún yẹ ká fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn, gbogbo ara wọn àti gbogbo èrò wọn. (Ka Mátíù 22:37.) Kí ni èyí túmọ̀ sí?

8, 9. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun?

8 Ṣé kéèyàn kàn sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ti tó? Rárá o. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, gbogbo ara wa àti gbogbo èrò wa, a máa fi hàn nínú ìwà wa pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Mátíù 7:16-20) Bíbélì kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere pé tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a ó máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Ṣé ìyẹn ṣòro? Rárá, torí pé “àwọn àṣẹ” Jèhófà “kò nira.”​—Ka 1 Jòhánù 5:3.

9 Tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, a máa láyọ̀, ìgbésí ayé wa á sì dùn. (Àìsáyà 48:17, 18) Àmọ́, kí ló máa jẹ́ ká dúró sọ́dọ̀ Jèhófà? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

TÚBỌ̀ MÁA SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ

10. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?

10 Kí lo lè ṣe láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Ẹ̀kọ́ tó o kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ kó o túbọ̀ mọ Jèhófà dáadáa, ó sì ti jẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ńṣe ló dà bí iná téèyàn dá, tó fẹ́ kó máa jó lala. Bí iná tó ń jó ṣe nílò igi kó lè máa jó nìṣó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i kí ọ̀rẹ́ ìwọ àti Jèhófà lè máa lágbára sí i.​—Òwe 2:1-5.

Bí iná tá a dá ṣe nílò igi láti máa jó lala, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ fún Jèhófà ṣe nílò ohun táá mú kó máa jó lala

11. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

11 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá kọ́ àwọn nǹkan tó máa yà ẹ́ lẹ́nu gan-an. Wo bó ṣe rí lára méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà tó ń ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fún wọn. Wọ́n sọ pé: “Àbí ẹ ò rí i bí ọkàn wa ṣe ń jó fòfò nínú wa bó ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ lójú ọ̀nà, tó ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?”​—Lúùkù 24:32.

12, 13. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run? (b) Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà tutù?

12 Bí Ìwé Mímọ́ ṣe wọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ́kàn nígbà tí wọ́n lóye ohun tí wọ́n ń kọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì ṣe wọ̀ ẹ́ lọ́kàn nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ohun tó ò ń kọ́. Ìyẹn ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà kó o sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó dájú pé, o ò ní fẹ́ kí ìfẹ́ yìí di tútù.​—Mátíù 24:12.

13 Tó o bá ti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ó yẹ kó o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí ọ̀rẹ́ yín lè lágbára sí i. O gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti Jésù, kó o sì máa ronú nípa ohun tó ò ń kọ́ àti bó o ṣe lè fi sílò nínú ìgbésí ayé rẹ. (Jòhánù 17:3) Nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bi ara rẹ pé: ‘Kí ni ohun tí ibí yìí ń kọ mi nípa Jèhófà Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi yẹ kí n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi àti gbogbo ara mi?’​—1 Tímótì 4:15.

14. Báwo ni àdúrà ṣe lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà máa lágbára?

14 Tó o bá ní ọ̀rẹ́ àtàtà kan, àjọṣe yín máa lágbára tẹ́ ẹ bá ń sọ̀rọ̀ déédéé. Lọ́nà kan náà, tá a ba ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé nínú àdúrà, ìyẹn á mú kí ìfẹ́ tá a ní fún un túbọ̀ lágbára. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:17.) Àdúrà jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run. Ó yẹ ká máa bá a sọ̀rọ̀ látọkàn wá nígbà gbogbo. (Sáàmù 62:8) Kò yẹ ká máa gba àdúrà àkọ́sórí, àmọ́ ó yẹ ká máa gbàdúrà látọkàn wá. Ó dájú pé tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń gbàdúrà látọkàn wá, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á máa lágbára.

MÁA SỌ FÚN ÀWỌN ÈÈYÀN NÍPA JÈHÓFÀ

15, 16. Irú ọwọ́ wo ló yẹ kó o fi mú iṣẹ́ ìwàásù?

15 Tá a bá fẹ́ dúró sọ́dọ̀ Jèhófà, ó tún yẹ ká máa sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà. (Lúùkù 1:74) Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ pàtàkì tí Jésù ní kí gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ṣe nìyẹn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní láti máa wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Ṣé o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀?​—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé iṣẹ́ ìwàásù yìí jẹ́ ohun tó ṣeyebíye gan-an; ìdí nìyẹn tó fi pè é ní “ìṣúra.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o ní láti ṣe ni pé kó o máa sọ fáwọn èèyàn nípa Jèhófà àti ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé. Ara ọ̀nà tó o lè gbà sin Jèhófà nìyẹn, ó sì mọyì ohun tó ò ń ṣe fún un. (Hébérù 6:10) Ìṣẹ ìwáásù tún lè ṣe ìwọ àtàwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ láǹfààní, torí pé ńṣe lò ń ran ara rẹ àtàwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.) Ṣé iṣẹ́ míì wà tó tún lè fúnni láyọ̀ ju èyí lọ?

17. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fi iṣẹ́ ìwàásù falẹ̀?

17 Kò yẹ ká fi iṣẹ́ ìwàásù falẹ̀. A gbọ́dọ̀ “wàásù ọ̀rọ̀ náà,” ó sì yẹ ká ṣe é “láìfi falẹ̀.” (2 Tímótì 4:2) Ó yẹ kí àwọn èèyàn gbọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé! Ó sún mọ́lé, ó sì ń yára bọ̀ kánkán!” Òpin náà “kò ní pẹ́ rárá!” (Sefanáyà 1:14; Hábákúkù 2:3) Ó dájú pé láìpẹ́ Jèhófà máa pa ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí run. Àmọ́ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká kìlọ̀ fáwọn èèyàn kí wọ́n lè pinnu láti sin Jèhófà.

18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tòótọ́?

18 Jèhófà fẹ́ ká jọ́sìn òun pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn kan, àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú, ní pàtàkì jù lọ bí ẹ ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti máa wà ní gbogbo ìpàdé. Àwọn ìpàdé yẹn máa ń fún wa láǹfààní láti fún ara wa ní ìṣírí àti okun.

19. Kí la lè ṣe tó máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa?

19 Tó o ba ń lọ sáwọn ìpàdé yìí, wàá rí àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa jọ́sìn Jèhófà. Wàá rí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun ti wọ́n lè ṣe láti jọ́sìn Jèhófà bíi tìẹ. Àwọn náa jẹ́ aláìpé bíi tìẹ, wọ́n sì máa ń ṣàṣìṣe. Tí wọ́n bá sì ṣàṣìṣe, múra tán láti dárí jì wọ́n. (Ka Kólósè 3:13.) Àwọn ànímọ́ rere àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ ni kó o máa wò, èyí á jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ wọn, kó o sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

ÌYÈ TÒÓTỌ́

20, 21. Kí ni “ìyè tòótọ́”?

20 Jèhófà fẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbé ìgbésí ayé tó dáa jù lọ. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbésí ayé tá a máa gbé lọ́jọ́ iwájú máa yàtọ̀ pátápátá sí èyí tá à ń gbé lónìí.

Jèhófà fẹ́ kó o ní “ìyè tòótọ́.” Ṣé o fẹ́?

21 Lọ́jọ́ iwájú, kì í ṣe àádọ́rin (70) tàbí ọgọ́rin (80) ọdún péré la máa fi wà láàyè, kàkà bẹ́ẹ̀ a ó máa wà láàyè títí láé. A máa gbádùn “ìyè àìnípẹ̀kun” nínú Párádísè tó rẹwà, a sì máa ní ìlera pípé, àlàáfíà àti ayọ̀. Ìyẹn ni Bíbélì pè ní “ìyè tòótọ́.” Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa fún wa ní ìyè tòótọ́ yìí, àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe báyìí láti “dì í mú gírígíri.”​—1 Tímótì 6:12, 19.

22. (a) Báwo la ṣe lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí”? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe bá a ṣe lè sapá tó ló máa jẹ́ ká ní ìyè ayérayé?

22 Báwo la ṣe lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí”? A gbọ́dọ̀ “máa ṣe rere” ká sì “máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere.” (1 Tímótì 6:18) Ìyẹn túmọ̀ sí pé ó yẹ ká máa fi àwọn ohun tá à ń kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù. Àmọ́, kì í ṣe nípa ìsapá wa la fi máa ní ìyè tòótọ́. Kì í ṣe bá a ṣe lè sapá tó ló máa jẹ́ ká ní ìyè ayérayé. Jèhófà ló fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí, ó sì jẹ́ ọ̀nà kan tó gbà fi “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” rẹ̀ hàn. (Róòmù 5:15) Ó wu Baba wa ọ̀run gan-an láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní ẹ̀bùn yìí.

23. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe ìpinnu tó tọ́ ní báyìí?

23 Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mò ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà?’ Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àyípadà kan, ó yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀ ní báyìí. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti gbọ́ràn sí i lẹ́nu, Jèhófà máa jẹ́ ibi ààbò wa. Ó máa dáàbò bo àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí. Lẹ́yìn náà, Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó máa rí i dájú pé a gbé inú Párádísè títí láé. Ó dájú pé o lè ní ìyè tòótọ tó o bá ṣe ìpinnu tó tọ́ ní báyìí!