Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 4

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe tí Mo Bá Ṣàṣìṣe?

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe tí Mo Bá Ṣàṣìṣe?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tó o bá ń gbà pé o ṣàṣìṣe, ńṣe lò ń fi hàn pé ọmọlúàbí ni ẹ́, wàá sì túbọ̀ dẹni tó ṣe é fọkàn tán.

LO MÁA ṢE?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Tim ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣeré, ló bá gbá bọ́ọ̀lù lu gíláàsì wíńdò ẹnì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wọn, ó sì fọ́.

Tó bá jẹ́ ìwọ ni Tim, kí lo máa ṣe?

RÒ Ó WÒ NÁ!

OHUN MẸ́TA LO LÈ ṢE:

  1. Sá lọ.

  2. Sọ pé ẹlòmíì ló ṣe é.

  3. Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ẹni tó o ba nǹkan rẹ̀ jẹ́, kó o sì sọ fún un pé wàá sanwó ohun tó o bà jẹ́.

Ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o ṣe Ohun Kìíní. Àmọ́, àṣìṣe yòówù kó o ṣe, ohun tó dára jù ni pé kó o gba ẹ̀bi rẹ lẹ́bi tó o bá ṣàṣìṣe.

ÌDÍ MẸ́TA TÓ FI YẸ KÓ O GBÀ PÉ O ṢÀṢÌṢE

  1. Ohun tó yẹ kó o ṣe nìyẹn.

    Bíbélì sọ pé: “A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:⁠18.

  2. Àwọn èèyàn tètè máa ń dárí ji ẹni tó bá gbà pé òun jẹ̀bi.

    Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.”​—Òwe 28:⁠13.

  3. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, inú Ọlọ́run máa dùn.

    Bíbélì sọ pé: “Oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.”​—Òwe 3:⁠32.

Àwọn agbófinró bu owó ìtanràn lé Karina, tó jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún, torí pé ó fi mọ́tò sáré ju bó ṣe yẹ lọ. Karina wá ń fi ìwé tí wọ́n já fún un pa mọ́ kí dádì ẹ̀ má bàa rí i. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tá a ní kí baba máà gbọ́, baba ló máa parí ẹ̀. Karina sọ pé, “Lẹ́yìn ọdún kan, Dádì mi rí ìwé tí wọ́n já fún mi torí pé mo fi mọ́tò sáré. Bí mo ṣe kó ara mi sí wàhálà nìyẹn o!”

Kí ni Karina rí kọ́? Ó sọ pé: “Téèyàn bá ń bo àṣìṣe rẹ̀ mọ́lẹ̀, ńṣe ló kàn ń dá kún ìṣòro rẹ̀. Wàá ṣì jìyà ohun tó o ṣe lọ́jọ́ iwájú!”

BÓ O ṢE LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ ÀṢÌṢE RẸ

Bíbélì sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jákọ́bù 3:⁠2) Lédè míì, gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe. A ti rí i pé téèyàn bá ń tètè gbà pé òun ṣàṣìṣe, ńṣe ló fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, òun sì níwà àgbà.

Ohun míì tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe rẹ. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Vera sọ pé: “Ńṣe ni mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe kọ̀ọ̀kan tí mo bá ṣe, mo sì máa ń ronú nípa bí ohun tí mo kọ́ látinú àṣìṣe náà ṣe lè mú kí ìwà mi dáa sí i, kí n sì mo ohun tó yẹ kí n ṣe tó bá dìgbà míì.” Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè ṣe é.

Ká sọ pé o yá kẹ̀kẹ́ dádì ẹ, o wá bà á jẹ́. Kí lo máa ṣe?

  • Má sọ nǹkan kan, kó o sì gbà pé dádì ẹ ò ní mọ̀.

  • Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an fún dádì ẹ.

  • Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Dádì ẹ, àmọ́ kó o sọ pé ẹlòmíì ló ṣe é.

O ò ṣe dáadáa nínú ìdánwò kan torí pé o ò kàwé. Kí lo máa ṣe?

  • Sọ pé ìdánwò yẹn le.

  • Gbà pé torí pé o ò kàwé ni kò jẹ́ kó o ṣe dáadáa.

  • Sọ pé torí olùkọ́ yẹn ò fẹ́ràn ẹ ni kò jẹ́ kó o ṣe dáadáa.

Tó o bá ń ronú ṣáá nípa àṣìṣe tó o ti ṣe sẹ́yìn, ńṣe ló dà bí ìgbà tí awakọ̀ kan bá ń ranjú mọ́ dígí tí wọ́n fi ń wo ẹ̀yìn ọkọ̀ dípò kó máa wo iwájú

Wá pa dà sórí àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu bà yẹn. Ronú bíi pé ìwọ ni (1) dádì àti (2) olùkọ́ yẹn. Kí lo rò pé dádì àti olùkọ́ ẹ máa rò nípa ẹ tó o bá gbà pé o ṣàṣìṣe? Kí làwọn méjèèjì máa rò nípa ẹ tó o bá bo àṣìṣe ẹ mọ́lẹ̀?

Wá ronú nípa àṣìṣe kan tó o ṣe lọ́dún tó kọjá, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Àṣìṣe wo lo ṣe? Kí lo sì ṣe nípa àṣìṣe náà?

  • Mo bò ó mọ́lẹ̀.

  • Mo sọ pé ẹlòmíì ló ṣe é.

  • Mo gbà pé mo ṣàṣìṣe.

Tó bá jẹ́ pé o ò gbà pé o ṣàṣìṣe, báwo lọ̀rọ̀ yẹn ṣe pa dà rí lára ẹ?

  • Ó múnú mi dùn​—mi ò tiẹ̀ rí i rò!

  • Mo jẹ̀bi​—Ó yẹ kí n sọ òótọ́.

Ohun tó dáa wo lò bá ti ṣe nípa àṣìṣe náà?

Ẹ̀kọ́ wo lo kọ́ látinú àṣìṣe rẹ?

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Kí nìdí táwọn kan kì í fi í gbà pé àwọn ṣàṣìṣe?

Kí làwọn èèyàn máa rò nípa ẹ tó o bá ń bo àṣìṣe ẹ mọ́lẹ̀, àmọ́ kí ni wọ́n máa rò nípa ẹ tó o bá ń gbà pé o ṣàṣìṣe?​—Lúùkù 16:10.