Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 1

Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé

Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé

Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa. Òun ló dá àwọn nǹkan tí a lè fojú rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí. Kí Ọlọ́run tó dá àwọn nǹkan tí a lè rí, ó kọ́kọ́ dá àwọn áńgẹ́lì. Ọlọ́run dá àwọn áńgẹ́lì tí ó pọ̀ gan-an. Ṣé o mọ bí àwọn áńgẹ́lì ṣe rí? Bí Ọlọ́run ṣe rí náà ni àwọn áńgẹ́lì ṣe rí. A kò lè rí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ni a kò lè rí àwọn áńgẹ́lì. Áńgẹ́lì tí Jèhófà kọ́kọ́ dá máa ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́. Áńgẹ́lì yìí ran Jèhófà lọ́wọ́ nígbà tí Jèhófà dá àwọn ìràwọ̀, oòrùn àti gbogbo nǹkan míì. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá ni ilẹ̀ ayé wa yìí.

Jèhófà wá ṣe ayé yìí lọ́nà tí àwa èèyàn àti àwọn ẹranko fi máa lè gbé inú rẹ̀. Ó jẹ́ kí oòrùn máa ràn dé ayé. Ó dá àwọn òkè ńláńlá, odò àti omi òkun tó pọ̀ gan-an.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jèhófà ṣe lẹ́yìn náà? Jèhófà sọ pé: ‘Mo máa dá àwọn koríko, ewéko àti àwọn igi.’ Bó ṣe di pé àwọn igi bẹ̀rẹ̀ sí í so èso lóríṣiríṣi nìyẹn, tí oríṣiríṣi ẹ̀fọ́ àti àwọn òdòdó sì bẹ̀rẹ̀ sí í hù. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà dá gbogbo àwọn ẹranko, ó dá àwọn ẹyẹ tó ń fò, àwọn ẹranko tó ń fàyà fà, èyí tó ń rìn nílẹ̀ àti àwọn tó ń gbé inú omi. Àwọn ẹranko kan tóbi gan-an, àpẹẹrẹ kan ni erin. Àwọn ẹranko míì sì kéré, eku wà lára irú àwọn ẹranko bẹ́ẹ̀. Ẹranko wo lo fẹ́ràn jù?

Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún áńgẹ́lì àkọ́kọ́ yẹn pé: ‘Jẹ́ ká dá èèyàn.’ Ọlọ́run kò dá àwa èèyàn àti àwọn ẹranko bákan náà, a yàtọ̀ síra. Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé a lè ronú, ká sì ṣe oríṣiríṣi nǹkan míì. A lè sọ̀rọ̀, a lè rẹ́rìn-ín, a sì lè gbàdúrà. Àwa la tún máa bójú tó ilẹ̀ ayé yìí àti àwọn ẹranko. Ṣé o mọ orúkọ ọkùnrin tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá? Wàá rí i nínú ẹ̀kọ́ tó kàn.

“Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” ​​—Jẹ́nẹ́sísì 1:1