Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 3

Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run

Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run

Lọ́jọ́ kan tí Éfà dá wà, ejò kan bá a sọ̀rọ̀. Ejò yẹn sọ pé: ‘Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ èyíkéyìí lára èso igi tó wà nínú ọgbà yìí?’ Éfà dáhùn pé: ‘A lè jẹ lára èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìi àyàfi ẹyọ kan péré tí Ọlọ́run sọ pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ èso rẹ̀. Tí a bá jẹ èyí tó ní ká má jẹ, a máa kú.’ Ejò yẹn wá sọ pé: ‘Ẹ ò ní kú. Jẹ́ kí n sọ òtítọ́ fún ẹ, tí ẹ bá jẹ ẹ́, ẹ máa dà bí Ọlọ́run.’ Ṣé òótọ́ ni ejò yẹn sọ? Rárá, irọ́ ló pa. Àmọ́, Éfà gba ohun tí ejò yẹn sọ gbọ́. Torí pé Éfà tẹjú mọ́ èso yẹn, èso yẹn wù ú jẹ. Ó jẹ èso náà, ó sì tún fún ọkọ rẹ̀. Ádámù mọ̀ pé tí àwọn bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, àwọn máa kú. Síbẹ̀, Ádámù jẹ èso náà.

Kí ilẹ̀ ọjọ́ yẹn tó ṣú, Jèhófà bá Ádámù àti Éfà sọ̀rọ̀. Ó ní kí wọ́n ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ṣàìgbọràn. Ádámù sọ pé Éfà ló fún òun jẹ, Éfà sì sọ pé ejò ló fà á. Torí pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, Jèhófà lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Jèhófà wá fi àwọn áńgẹ́lì àti idà tó ń yọ iná ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ọgbà yẹn. Ǹjẹ́ o mọ ìdí? Ìdí ni pé kò fẹ́ kí Ádámù àti Éfà pa dà sínú ọgbà yẹn mọ́ láéláé.

Jèhófà sọ pé òun máa fìyà jẹ ẹni tó parọ́ fún Éfà. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé kì í ṣe ejò gan-an ló bá Éfà sọ̀rọ̀? Jèhófà kò dá àwọn ejò pé kí wọ́n máa sọ̀rọ̀. Áńgẹ́lì burúkú kan ló mú kí ejò yẹn sọ̀rọ̀. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kí ó lè tan Éfà jẹ ni. Áńgẹ́lì yẹn là ń pè ní Sátánì Èṣù. Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa pa Sátánì run. Tí Jèhófà bá ti pa á run, kò ní lè máa tan àwọn èèyàn jẹ mọ́.

‘Apànìyàn ni Èṣù nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀.’​​—Jòhánù 8:44