Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 5

Nóà Kan Áàkì

Nóà Kan Áàkì

Nígbà tó yá, àwọn èèyàn pọ̀ gan-an láyé. Àmọ́ ìwà tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ń hù kò dáa rárá. Kódà, àwọn áńgẹ́lì kan bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà búburú. Wọ́n fi ọ̀run sílẹ̀ wá sí ayé. Ṣé o mọ ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ ṣe bí àwa èèyàn, kí wọ́n sì fẹ́ ìyàwó.

Àwọn áńgẹ́lì yẹn fún àwọn ìyàwó wọn lóyún, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin. Nígbà tí àwọn ọmọ yẹn dàgbà, wọ́n lágbára gan-an, wọ́n sì máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn. Wọ́n tún máa ń ṣèkà fún àwọn èèyàn. Inú Jèhófà ò dùn sí ìwà búburú yẹn. Torí náà, Jèhófà pinnu pé òun máa fi omi tó pọ̀ gan-an pa àwọn èèyàn náà run.

Àmọ́, ọkùnrin kan wà tí kò bá wọn lọ́wọ́ sí ìwà búburú. Nóà ni orúkọ rẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Òun àti ìyàwó rẹ̀ bí ọmọkùnrin mẹ́ta, orúkọ àwọn ọmọ náà ni, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyàwó kan. Jèhófà sọ fún Nóà pé kó kan áàkì kan kí òun àti ìdílé rẹ̀ lè wà nínú rẹ̀ nígbà tí òjò ńlá bá ń rọ̀. Áàkì náà dà bí àpótí tó tóbi gan-an, àmọ́ tó lè dúró sórí omi. Jèhófà tún sọ fún Nóà pé kó kó àwọn ẹranko sínú áàkì náà, kí àwọn ẹranko náà má bàa kú sínú òjò ńlá tó máa rọ̀ yẹn.

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Jèhófà bá Nóà sọ̀rọ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kan áàkì náà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta [50] ọdún tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ fi kan áàkì yẹn. Bí Jèhófà ṣe ní kí wọ́n ṣe é náà ni wọ́n ṣe é. Yàtọ̀ síyẹn, Nóà tún máa ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé Ọlọ́run máa tó fi omi pa wọ́n run. Àmọ́, wọn ò gbọ́rọ̀ sí Nóà lẹ́nu.

Nígbà tó yá, Ọlọ́run ní kí wọ́n wọnú áàkì náà. Ṣé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Orí tó kàn máa ṣàlàyé.

“Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” ​—Mátíù 24:37