Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 7

Ilé Gogoro Bábélì

Ilé Gogoro Bábélì

Lẹ́yìn tí omi pa àwọn èèyàn búburú run, àwọn ọmọ Nóà bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ, àwọn ọmọ wọn sì pọ̀ gan-an. Bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tàn káàkiri ilẹ̀ ayé. Ohun tí Jèhófà sì fẹ́ kí wọ́n ṣe nìyẹn.

Ṣùgbọ́n, àwọn kan wà lára àwọn èèyàn náà tí kò ṣègbọràn sí Jèhófà. Wọ́n sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká kọ́ ìlú ńlá kan síbí, ká sì máa gbé ibẹ̀. A máa kọ́ ilé gogoro kan, tó máa ga gan-an tí orí rẹ̀ sì máa kan ọ̀run. Tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á mọ̀ wá níbi gbogbo.’

Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́lé nìyẹn, àmọ́ inú Jèhófà kò dùn sí ohun tí àwọn èèyàn yẹn ń ṣe, torí náà Jèhófà dá iṣẹ́ yẹn dúró. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn? Jèhófà mú kí wọ́n máa sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lójijì, nǹkan yí pa dà, wọn ò gbọ́ èdè ara wọn mọ́, bó ṣe di pé wọn kò lè kọ́lé mọ́ nìyẹn. Orúkọ ìlú tí wọ́n ń kọ́ nígbà yẹn la wá mọ̀ sí Bábélì, tí ó túmọ̀ sí “Ìdàrúdàpọ̀.” Àwọn èèyàn náà tú ká, wọ́n sì lọ gbé níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé. Àmọ́, ìwà búburú tó ti mọ́ wọn lára náà ni wọ́n ń hù ní àwọn ibi tí wọ́n lọ. Ṣé gbogbo èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn ló ń hùwà búburú àbí àwọn kan wà tó ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà? Inú orí tó kàn la ti máa mọ̀.

‘Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óò rẹ̀ wálẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.’​​—Lúùkù 18:14