Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 8

Ábúráhámù àti Sárà Ṣègbọràn sí Ọlọ́run

Ábúráhámù àti Sárà Ṣègbọràn sí Ọlọ́run

Ìlú kan wà tí kò jìnnà sí Bábélì, orúkọ ìlú yẹn ni Úrì. Òrìṣà ni àwọn èèyàn ìlú yìí máa ń bọ, àmọ́ ọkùnrin kan wà ní ìlú yẹn tó ń sin Jèhófà. Orúkọ ọkùnrin náà ni Ábúráhámù.

Lọ́jọ́ kan, Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Kúrò ní ìlú yìí, kí o sì fi àwọn èèyàn rẹ sílẹ̀, kí o lọ máa gbé nílẹ̀ kan tí mo máa fi hàn ẹ́.’ Jèhófà wá ṣèlérí fún un pé: ‘Mó máa sọ ẹ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, mo tún máa ṣe àwọn nǹkan dáadáa fún àwọn èèyàn níbi gbogbo láyé nítorí rẹ.’

Ábúráhámù kò mọ ibi tí Jèhófà ní kó lọ, àmọ́ ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Torí náà, Ábúráhámù ṣègbọràn, òun àti Sárà ìyàwó rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú Térà bàbá rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kó gbogbo ẹrù wọn, wọ́n sì forí lé ibi tó jìnnà gan-an tí Jèhófà júwe fún wọn.

Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75] ni Ábúráhámù nígbà tí òun àti ìdílé rẹ̀ dé ibi tí Jèhófà ní kí wọ́n lọ. Orúkọ ibẹ̀ ni Kénáánì. Ìlú yẹn ni wọ́n wà nígbà tí Ọlọ́run tún bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ tó sì ṣèlérí fún un pé: ‘Ṣé o rí gbogbo ìlú yìí, àwọn ọmọ rẹ ni màá fún.’ Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Ábúráhámù àti Sárà kò tíì bímọ lásìkò tí Jèhófà ṣèlérí yẹn? Torí náà, báwo ni Jèhófà ṣe máa mú kí ọmọ wọn jogún ilẹ̀ náà?

“Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù . . . fi ṣègbọràn ní jíjáde lọ sí ibì kan tí a ti yàn án tẹ́lẹ̀ láti gbà gẹ́gẹ́ bí ogún; ó sì jáde lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ibi tí òun ń lọ.” ​—Hébérù 11:8