Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 11

Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò

Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò

Torí pé Ábúráhámù kọ́ Ísákì ọmọ rẹ̀ dáadáa, ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì gba gbogbo ìlérí Jèhófà gbọ́. Àmọ́ nígbà tí Ísákì wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe ohun kan tó ṣòro ṣe. Ǹjẹ́ o mọ ohun náà?

Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Jọ̀ọ́, mú ọmọ kan ṣoṣo tí o ní, ẹ jọ lọ sí orí òkè kan nílẹ̀ Móráyà kí o sì fi ọmọ náà rúbọ.’ Ábúráhámù kò mọ ìdí tí Jèhófà fi ní kó ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe ohun tí Jèhófà sọ.

Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, Ábúráhámù àti Ísákì pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ méjì rin ìrìn àjò lọ sí Móráyà. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n dé ìtòsí ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n sì ń wo òkè náà ní iwájú. Ábúráhámù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé kí wọ́n dúró de àwọn, òun àti Ísákì sì lọ láti rúbọ. Ábúráhámù ní kí Ísákì ru igi tí wọ́n máa lò, Ábúráhámù sì mú ọ̀bẹ lọ́wọ́. Ísákì béèrè lọ́wọ́ bàbá rẹ̀ pé: ‘Ẹran tí a máa fi rúbọ dà?’ Bàbá rẹ̀ sì dáhùn pé: ‘Ọmọ mi, Jèhófà máa fún wa ni ẹran tí a máa lò.’

Nígbà tí wọ́n dé orí òkè náà, wọ́n ṣe pẹpẹ kan. Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù fi okùn di ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Ísákì, ó sì gbé e sórí pẹpẹ náà.

Ábúráhámù wá mú ọ̀bẹ láti pa ọmọ rẹ̀. Ṣàdédé ló gbọ́ ohùn áńgẹ́lì Jèhófà láti ọ̀run, tó sọ pé: ‘Ábúráhámù! Má fọwọ́ kan ọmọ yẹn! Nísinsìnyí ni mo gbà pé o ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tí o fi ṣe tán láti fi ọmọ rẹ rúbọ.’ Ìgbà yẹn ni Ábúráhámù rí àgbò kan tí ìwo rẹ̀ há sínú igbó. Kíá, ó tú Ísákì sílẹ̀, ó sì fi àgbò náà rúbọ dípò rẹ̀.

Láti ọjọ́ yẹn lọ ni Jèhófà ti ń pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ òun. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jèhófà fi ń pè é bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní kí Ábúráhámù ṣe ló máa ń ṣe, nígbà míì ó tiẹ̀ lè má mọ ìdí tí Jèhófà fi ní kí òun ṣe nǹkan náà.

Jèhófà tún wá ṣèlérí fún Ábúráhámù bó ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Mo máa bù kún ẹ, mo máa mú kí àwọn ọmọ rẹ pọ̀ gan-an.’ Èyí túmọ̀ sí pé ipasẹ̀ ìdílé Ábúráhámù ni Jèhófà máa gbà bù kún gbogbo èèyàn rere.

“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”​​—Jòhánù 3:16