Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 12

Jékọ́bù Rí Ogún Gbà

Jékọ́bù Rí Ogún Gbà

Nígbà tí Ísákì pé ẹni ogójì [40] ọdún, ó fẹ́ Rèbékà. Ísákì nífẹ̀ẹ́ Rèbékà ìyàwó rẹ̀ gan-an. Nígbà tó yá, wọ́n bí ìbejì, ọkùnrin sì làwọn méjèèjì.

Orúkọ èyí àkọ́kọ́ ni Ísọ̀, orúkọ èkejì sì ni Jékọ́bù. Ísọ̀ fẹ́ràn kó máa ṣeré jáde, ó sì tún máa ń pa ẹran gan-an. Àmọ́ Jékọ́bù fẹ́ràn kó máa wà nílé.

Láyé àtijọ́, tí bàbá kan bá kú, àkọ́bí rẹ̀ ọkùnrin ló máa ń gba ohun tó pọ̀ jù lára ohun tí bàbá náà ní. Àwọn nǹkan tí bàbá náà fi sílẹ̀ lẹ́yìn tó kú là ń pè ní ogún. Àwọn ìlérí tí Jèhófà bá Ábúráhámù ṣe wà lára ogún ìdílé Ísákì. Ísọ̀ kò ka àwọn ìlérí yẹn sí pàtàkì, àmọ́ Jékọ́bù mọyì àwọn ìlérí yẹn gan-an.

Lọ́jọ́ kan tí Ísọ̀ dé láti ibi tó ti lọ pa ẹran, ó ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. Nígbà tó wọlé, ó gbóòórùn oúnjẹ tí Jékọ́bù ń sè, ó wá sọ fún un pé: ‘Ebi ń pa mí gan-an! Fún mi ní díẹ̀ lára oúnjẹ tí ò ń sè!’ Jékọ́bù dáhùn pé: ‘Mo máa fún ẹ, àmọ́ kọ́kọ́ ṣèlérí fún mi pé èmi ni màá gba ogún tó yẹ kí o gbà.’ Ísọ̀ wá dáhùn pé: ‘Kí ló kàn mí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ogún! Wò ó, ó ti di tìẹ. Ṣáà fún mi ní oúnjẹ.’ Ṣé o rò pé ohun tí Ísọ̀ ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu? Kò bọ́gbọ́n mu rárá. Ísọ̀ sọ ohun pàtàkì nù torí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré.

Nígbà tí Ísákì di arúgbó, ó rí i pé ó yẹ kí òun bù kún àkọ́bí òun. Àmọ́ Rèbékà ìyá wọn ran Jékọ́bù tó jẹ́ àbúrò lọ́wọ́, Jékọ́bù ló sì rí ìbùkún náà gbà. Nígbà tí Ísọ̀ mọ̀ pé Jékọ́bù ti gba ìbùkún òun, inú bí i gan-an, ó sì pinnu pé òun máa pa ìkejì òun. Ísákì àti Rèbékà ò fẹ́ kí Jékọ́bù kú, torí náà wọ́n sọ fún un pé: ‘Ó yá, wá lọ máa gbé lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n màmá rẹ̀ títí dìgbà tí inú Ísọ̀ á fi rọ̀.’ Jékọ́bù ṣe ohun tí àwọn òbí rẹ̀ sọ fún un, ó sì sá kúrò nílé.

“Àǹfààní wo ni ó jẹ́ fún ènìyàn kan láti jèrè gbogbo ayé, kí ó sì pàdánù ọkàn rẹ̀? Ní ti gidi, kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?”​​—Máàkù 8:​36, 37