Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 13

Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn

Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn

Jèhófà ṣèlérí fún Jékọ́bù pé òun máa dáàbò bò ó bí òun ṣe dáàbò bo Ábúráhámù àti Ísákì. Ìlú Háránì ni Jékọ́bù ń gbé, ó fẹ́ ìyàwó níbẹ̀, ó ní ọmọ tó pọ̀, ó ní àwọn ìránṣẹ́, ó sì ní nǹkan tó pọ̀ gan-an.

Nígbà tó yá, Jèhófà sọ fún Jékọ́bù pé: ‘Pa dà sí ìlú rẹ.’ Torí náà, Jékọ́bù àti ìdílé rẹ̀ gbéra, wọ́n sì rìnrìn-àjò pa dà sílé. Ojú ọ̀nà ni wọ́n wà tí àwọn èèyàn kan ti wá sọ fún Jékọ́bù pé: ‘Ísọ̀ ìkejì rẹ ń bọ̀ wá pàdé rẹ, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀!’ Ẹ̀rù ba Jékọ́bù, ó rò pé ńṣe ni Ísọ̀ fẹ́ wá bá òun àti ìdílé òun jà. Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: ‘Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n mi.’ Lọ́jọ́ kejì, Jékọ́bù fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Ísọ̀. Àwọn nǹkan tó fi ránṣẹ́ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù, ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Nígbà tí Jékọ́bù dá wà ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, ó rí áńgẹ́lì kan. Òun àti áńgẹ́lì yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í jà títí di àárọ̀ ọjọ́ kejì. Jékọ́bù fara pa, síbẹ̀ kò fi áńgẹ́lì náà sílẹ̀. Áńgẹ́lì yẹn wá sọ pé: ‘Fi mi sílẹ̀, jẹ́ kí n máa lọ.’ Àmọ́ Jékọ́bù sọ pé: ‘Mi ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, àyàfi tí o bá bù kún mi.’

Nígbà tó yá, áńgẹ́lì náà bù kún Jékọ́bù. Ó wá dá Jékọ́bù lójú pé Jèhófà kò ní jẹ́ kí Ísọ̀ bá òun jà.

Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jékọ́bù rí Ísọ̀ àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀ ní iwájú. Jékọ́bù fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́yìn, ó lọ bá Ísọ̀, ó sì tẹrí ba fún un ní ìgbà méje. Ísọ̀ náà sáré lọ bá Jékọ́bù, ó sì dì mọ́ ọn. Àwọn méjèèjì bú sẹ́kún, wọ́n sì parí ìjà wọn. Ǹjẹ́ o rò pé inú Jèhófà dùn sí ọ̀nà tí Jékọ́bù gbà yanjú ọ̀rọ̀ yẹn?

Lẹ́yìn náà, Ísọ̀ pa dà sílé rẹ̀, Jékọ́bù náà sì pa dà sí ilé tiẹ̀. Ọmọkùnrin méjìlá [12] ni Jékọ́bù ní. Orúkọ wọn ni Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì, Júdà, Dánì, Náfútálì, Gádì, Áṣérì, Ísákárì, Sébúlúnì, Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. Jèhófà lo ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin yẹn láti gba àwọn ìbátan rẹ̀ là. Ọmọkùnrin náà ni Jósẹ́fù. Ṣé o mọ bí Jèhófà ṣe lò ó? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

“Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.”​—Mátíù 5:​44, 45