Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 16

Ta Ni Jóòbù?

Ta Ni Jóòbù?

Ọkùnrin kan wà tó ń gbé nílẹ̀ Úsì tó sì ń jọ́sìn Jèhófà. Orúkọ rẹ̀ ni Jóòbù. Ọkùnrin yẹn lówó gan-an, ó sì ní àwọn ọmọ àti àwọn ìránṣẹ́ tó pọ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó máa ń ṣe oore fún àwọn tálákà, ó sì tún máa ń ṣe oore fún àwọn tí ọkọ wọn ti kú àti àwọn ọmọ tí kò ní òbí. Àmọ́, ṣé bí Jóòbù ṣe ń ṣe oore yẹn wá sọ pé kò ní ní ìṣòro kankan?

Èṣù ń ṣọ́ Jóòbù, àmọ́ Jóòbù kò mọ̀ pé ó ń ṣọ́ òun. Jèhófà sọ fún Sátánì pé: ‘Ǹjẹ́ o kíyè sí Jóòbù ìránṣẹ́ mi? Kò sí ẹni tó dà bíi rẹ̀ ní ayé. Ó máa ń tẹ́tí sí mi, ó sì máa ń hùwà rere.’ Sátánì dáhùn pé: ‘Mo gbà pé Jóòbù máa ń ṣe ohun tí o fẹ́. Ò ń dáàbò bò ó, o sì ń bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ó ní ilé, ó ní ilẹ̀, ó sì ní àwọn ẹran tó pọ̀. Tí o bá gba gbogbo ẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, wàá rí i pé kò ní sìn ẹ́ mọ́.’ Jèhófà wá sọ pé: ‘O lè lọ dán Jóòbù wò. Àmọ́, o kò gbọ́dọ̀ pa á.’ Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà kí Sátánì dán Jóòbù wò? Ó dá Jèhófà lójú pé Jóòbù máa jẹ́ olóòótọ́.

Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí í kó ìdààmú bá Jóòbù. Àkọ́kọ́, ó rán àwọn ará ìlú Sábéà pé kí wọ́n jí àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Jóòbù. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi iná jó gbogbo àgùntàn Jóòbù. Nígbà tó yá, àwọn ará ìlú Kálídíà wá jí àwọn ràkúnmí rẹ̀. Wọ́n tún pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń tọ́jú àwọn ẹranko yẹn. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan tó burú jù tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù? Lọ́jọ́ kan tí àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ń ṣe àríyá, ilé wó pa gbogbo wọn. Inú Jóòbù bà jẹ́ gan-an, àmọ́ kò fi Jèhófà sílẹ̀.

Síbẹ̀, Sátánì kò fi Jóòbù sílẹ̀. Ó tún mú kí àìsàn ṣe Jóòbù, tó fi jẹ́ pé ééwo wà ní gbogbo ara Jóòbù, ara sì máa ń ro ó. Jóòbù kò mọ ìdí tí gbogbo nǹkan yẹn fi ń ṣẹlẹ̀ sí òun. Síbẹ̀, Jóòbù kò fi Jèhófà sílẹ̀, ó ṣì ń jọ́sìn rẹ̀. Inú Ọlọ́run dùn sí Jóòbù gan-an torí pé Jóòbù ṣì ń jọ́sìn rẹ̀.

Nígbà tó yá, Sátánì rán àwọn ọkùnrin mẹ́ta láti lọ dán Jóòbù wò. Wọ́n sọ fún un pé: ‘O ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ kan tí o kò jẹ́wọ́ rẹ̀, torí rẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe ń fi ìyà jẹ ẹ́.’ Jóòbù sọ pé: ‘Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, mi ò dẹ́ṣẹ̀ kankan.’ Àmọ́, Jóòbù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Jèhófà ló fa ìṣòro tí òun ní, ó tún sọ pé Ọlọ́run kò ṣe dáadáa sí òun.

Ọ̀dọ́kùnrin kan wà níbẹ̀ tó ń jẹ́ Élíhù. Ó wà níbẹ̀ nígbà tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn ń bá Jóòbù sọ̀rọ̀. Élíhù dá sí ọ̀rọ̀ náà, ó ní: ‘Ọ̀rọ̀ tí gbogbo yín sọ kò dára. Jèhófà tóbi ju gbogbo wa lọ. Ọlọ́run kì í ṣe búburú rárá. Ó ń rí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì máa ń ran àwa èèyàn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.’

Lẹ́yìn ìyẹn ni Jèhófà wá bá Jóòbù sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: ‘Ibo lo wà nígbà tí mo dá ọ̀run àti ayé? Kí ló dé tí o fi sọ pé mi ò ṣe dáadáa sí ẹ? Ò ń sọ̀rọ̀, àmọ́ o kò mọ ìdí tí àwọn nǹkan yìí fi ń ṣẹlẹ̀.’ Jóòbù gbà pé òun ṣe àṣìṣe, ó sì sọ pé: ‘Jọ̀ọ́, má bínú. Tẹ́lẹ̀, ṣe ni mo gbọ́ nípa rẹ, àmọ́ mo ti wá mọ̀ ẹ́ báyìí. Kò sí ohun tí ìwọ Ọlọ́run kò lè ṣe. Jọ̀ọ́, dárí jì mí fún gbogbo ohun tí mo ti sọ.’

Nígbà tó yá, Jóòbù bọ́ nínú ìṣoro yẹn, Jèhófà mú kí ara rẹ̀ yá, ó sì mú kí Jóòbù ní nǹkan tó pọ̀ jú ohun tó ní tẹ́lẹ̀ lọ. Jóòbù pẹ́ láyé gan-an, ó sì gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀. Jèhófà bù kún Jóòbù torí pé ó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kódà lásìkò tí nǹkan le. Ṣé wàá ṣe bíi ti Jóòbù, kí o sì ṣe ìfẹ́ Jèhófà kódà nígbà ìṣòro?

“Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá.”​—Jákọ́bù 5:11