Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 17

Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà

Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà

Ìdílé Jékọ́bù túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Íjíbítì, àwọn la wá mọ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí Jékọ́bù àti Jósẹ́fù kú, Fáráò míì di ọba ní ilẹ̀ Íjíbítì. Ẹ̀rù ń ba ọba yẹn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i àti pé ọwọ́ àwọn ará Íjíbítì kò ní lè ká wọn. Torí náà, Fáráò sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú. Ó wá fipá mú wọn pé kí wọ́n máa ṣe búlọ́ọ̀kù, kí wọ́n sì tún máa ṣe àwọn iṣẹ́ míì tó le. Àmọ́ bí àwọn ará Íjíbítì ṣe ń fipá mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i. Inú Fáráò kò dùn pé wọ́n ń pọ̀ sí i, torí náà ó pàṣẹ pé tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá bí ọmọkùnrin, kí wọ́n pa ọmọ náà. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ṣé ọkàn wọn máa balẹ̀?

Obìnrin kan wà tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, orúkọ rẹ̀ ni Jókébédì. Nígbà tí obìnrin yẹn bí ọmọkùnrin kan, kò fẹ́ kí wọ́n pa ọmọ náà, ó wá gbé e sínú apẹ̀rẹ̀ kan, ó sì gbé e pa mọ́ sí àárín àwọn òdòdó tó wà ní etí Odò Náílì. Míríámù tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ọmọ náà dúró sí ìtòsí kó bàa lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀.

Obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọba Fáráò wá wẹ̀ ní odò yẹn, ó sì rí apẹ̀rẹ̀ náà. Nígbà tó ṣí i, ó rí i tí ọmọ náà ń sunkún, àánú rẹ̀ sì ṣe é. Míríámù ẹ̀gbọ́n ọmọ jòjòló náà wá béèrè pé: ‘Ṣé kí n bá yín wá obìnrin kan tó máa bá yín tọ́jú ọmọ náà?’ Nígbà tí ọmọ ọba yẹn sọ pé kí Míríámù ṣe bẹ́ẹ̀, ó lọ pe Jókébédì màmá wọn. Ọmọ ọba Fáráò wá sọ fún Jókébédì pé: ‘Gbé ọmọ yìí, bá mi tọ́jú rẹ̀, mo máa san owó fún ẹ.’

Nígbà tí ọmọ kékeré náà dàgbà, Jókébédì mú un lọ sọ́dọ̀ ọmọbìnrin ọba Fáráò. Obìnrin yẹn wá mú ọmọ náà gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mósè. Inú ilé ọba ni Mósè dàgbà sí, kò sì sí ohun tó fẹ́ tí wọn ò ní lè ṣe fún un. Àmọ́ Mósè kò gbàgbé Jèhófà. Ó mọ̀ pé òun kì í ṣe ọmọ Íjíbítì, pé ọmọ Ísírẹ́lì ni òun. Torí náà, ó pinnu pé Jèhófà ni òun máa sìn.

Nígbà tí Mósè pé ogójì [40] ọdún, ó pinnu pé òun máa ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Inú Mósè kò dùn nígbà tó rí ọmọ Íjíbítì kan tó ń lu ọmọ Ísírẹ́lì kan. Torí bẹ́ẹ̀, ó lu ọmọ Íjíbítì náà pa, ó wá fi erùpẹ̀ bo òkú rẹ̀ mọ́lẹ̀. Nígbà tí Fáráò gbọ́ ohun tí Mósè ṣe, ó wá ọ̀nà láti pa Mósè. Àmọ́ Mósè sá lọ sí ilẹ̀ Mídíánì. Jèhófà rí Mósè níbi tó wà, ó sì tọ́jú rẹ̀.

“Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè . . . fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò, ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run.”​—Hébérù 11:​24, 25