Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 20

Àwọn Ìyọnu Mẹ́fà Tí Ó Tẹ̀ Lé E

Àwọn Ìyọnu Mẹ́fà Tí Ó Tẹ̀ Lé E

Mósè àti Áárónì lọ jíṣẹ́ Jèhófà fún Fáráò, wọ́n sọ fún un pé: ‘Tí o kò bá jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ, mo máa rán àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ sí ilẹ̀ yìí.’ Àwọn eṣinṣin náà kún ilé gbogbo àwọn ọmọ Íjíbítì, àti ilé olówó àti ti tálákà. Gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì pátápátá ló kún fún àwọn eṣinṣin náà. Àmọ́ àwọn eṣinṣin yìí kò dé ilẹ̀ Góṣénì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé. Látorí ìyọnu kẹrin, àwọn ọmọ Íjíbítì nìkan ló ń jìyà àwọn ìyọnu náà. Fáráò wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: ‘Ẹ bá mi bẹ Jèhófà pé kó mú àwọn eṣinṣin náà kúrò. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa lọ.’ Àmọ́, nígbà tí Jèhófà mú àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà kúrò tán, Fáráò kò tún jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Ǹjẹ́ Fáráò tiẹ̀ kọ́gbọ́n kankan nínú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀?

Jèhófà sọ pé: ‘Tí Fáráò kò bá jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ, gbogbo ẹranko àwọn ọmọ Íjíbítì máa ṣàìsàn, wọ́n á sì kú.’ Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, àwọn ẹranko náà bẹ̀rẹ̀ sí í kú. Ṣùgbọ́n kò sí ohun tó ṣe àwọn ẹranko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, Fáráò ń ṣe agídí, kò sì gbà kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

Jèhófà wá ní kí Mósè pa dà lọ sọ́dọ̀ Fáráò, kó sì da eérú sínú afẹ́fẹ́. Eérú náà sì wá di ekuru, ó sì dà pọ̀ mọ́ afẹ́fẹ́. Gbogbo ara àwọn ọmọ Íjíbítì kún fún ekuru náà. Èyí fa eéwo sára àwọn ọmọ Íjíbítì àti àwọn ẹranko wọn, eéwo náà sì máa ń dun èèyàn gan-an. Síbẹ̀, Fáráò kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

Jèhófà tún rán Mósè lọ sọ́dọ̀ Fáráò pé: ‘Kí ló dé tí o kò jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ? Tó bá di ọ̀la, òjò yìnyín máa rọ̀ sórí ilẹ̀ náà.’ Lọ́jọ́ kejì, Jèhófà mú kí òjò yìnyín rọ̀, ó tún mú kí àrá máa sán, iná sì là. Àwọn ọmọ Íjíbítì kò rí irú òjò tí ó le tó báyìí rí. Ọ̀pọ̀ igi ló wó, àwọn nǹkan ọ̀gbìn sì bà jẹ́. Ṣùgbọ́n kò sí ohun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Góṣénì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé. Fáráò tún pe Mósè, ó sì sọ fún un pé: ‘Bá wa bẹ Jèhófà pé kí ó dáwọ́ òjò náà dúró.’ Ó tiẹ̀ tún sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa lọ. Àmọ́ lẹ́yìn tí òjò yìnyín náà dáwọ́ dúró, Fáráò yarí, kò sì jẹ́ kí wọ́n lọ mọ́.

Lẹ́yìn náà, Mósè sọ pé: ‘Ní ìsinsìnyí àwọn kòkòrò eéṣú máa jẹ ohun tí ó bá ṣẹ́ kù nínú nǹkan ọ̀gbìn tí òjò yìnyín náà kò bà jẹ́.’ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòkòrò ya dé, wọ́n sì jẹ gbogbo nǹkan tí ó ṣẹ́ kù lórí àwọn igi àti ní ilẹ̀ náà run. Fáráò tún wá pe Mósè, ó sì ní kó bẹ Jèhófà pé kó lé àwọn kòkòrò náà dànù. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Jèhófà mú kí àwọn kòkòrò náà lọ, Fáráò kò tún gbà kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

Jèhófà tún wá sọ fún Mósè pé: ‘Na ọwọ́ rẹ sí ojú ọ̀run.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ojú ọ̀run dúdú. Fún odindi ọjọ́ mẹ́ta, àwọn ọmọ Íjíbítì kò rí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ wà níbi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé.

Fáráò wá sọ fún Mósè pé: ‘Ìwọ àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa lọ. Ṣùgbọ́n ẹ fi àwọn ẹranko yín sílẹ̀ níbí.’ Mósè fèsì pé: ‘A gbọ́dọ̀ kó àwọn ẹranko wa dání ká lè fi wọ́n rúbọ sí Ọlọ́run wa.’ Inú bí Fáráò gan-an, ó wá pariwo pé: ‘Kó ara rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi! Tí mo bá tún rí ẹ, màá pa ẹ́ ni.’

“Ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”​—Málákì 3:18