Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 22

Iṣẹ́ Ìyanu ní Òkun Pupa

Iṣẹ́ Ìyanu ní Òkun Pupa

Nígbà tí Fáráò rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kúrò ní Íjíbítì, ó dùn ún pé òun jẹ́ kí wọ́n lọ. Ó wá pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé: ‘Ẹ kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun mi jáde, kí ẹ sì jẹ́ ká lé wọn! Kò yẹ ká jẹ́ kí wọ́n lọ.’ Bó ṣe di pé òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyẹn.

Jèhófà ló ń darí àwọn èèyàn rẹ̀, ó lo kùrukùru ní ọ̀sán, ó sì ń lo iná ní alẹ́. Ó darí wọn gba ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n pa àgọ́.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Fáráò àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí wọ́n ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n torí pé wọn kò mọ ibi tí àwọn máa sá gbà, àwọn ọmọ ogun Íjíbítì rèé lẹ́yìn, Òkun Pupa sì wà ní iwájú. Wọ́n wá sọ fún Mósè pé: ‘Ikú ti dé! Ò bá ti fi wá sílẹ̀ ní Íjíbítì.’ Àmọ́ Mósè sọ pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì rí bí Jèhófà ṣe máa gbà wá là.’ Ó ṣe kedere pé Mósè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kó àwọn àgọ́ wọn. Ní òru yẹn, Jèhófà mú kí kùrukùru náà lọ sí ẹ̀yìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó wá wà ní àárín wọn àti àwọn ọmọ Íjíbítì. Kùrukùru yẹn mú kí òkùnkùn wà ní ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Íjíbítì, ó sì mú kí ìmọ́lẹ̀ wà ní ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Jèhófà sọ fún Mósè pé kó na ọwọ́ rẹ̀ sí òkun náà. Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí afẹ́fẹ́ tó lágbára fẹ́ ní gbogbo òru títí ilẹ̀ fi mọ́. Bó ṣe di pé òkun yẹn pín sí méjì nìyẹn, ó sì mú kí ọ̀nà wà tí wọ́n lè gbà kọjá. Ojú ọ̀nà yẹn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà, tí omi náà sì dà bí ògiri ní ọ̀tún àti òsì wọn.

Àwọn ọmọ ogun Fáráò tẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ inú òkun náà. Jèhófà wá mú kí nǹkan dojú rú fún àwọn ọmọ ogun Fáráò. Bó ṣe di pé ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fò yọ nìyẹn. Ni àwọn ọmọ ogun náà bá pariwo pé: ‘Ẹ jẹ́ kí á pa dà lẹ́yìn wọn! Jèhófà ló ń jà fún wọn.’

Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Na ọwọ́ rẹ sí òkun náà.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, omi náà ya bo àwọn ọmọ ogun Íjíbítì mọ́lẹ̀. Fáráò àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì kú. Kò sí ẹnì kankan nínú wọn tí ó yè.

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé òdìkejì òkun, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin yin Jèhófà pé: “Jẹ́ kí n kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti di gbígbéga fíofío. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó gbé sọ sínú òkun.” Bí àwọn èèyàn náà ṣe ń kọrin, àwọn obìnrin ń jó, wọ́n sì ń lu ìlù tanboríìnì. Inú wọ́n dùn pé ní báyìí àwọn ti kúrò lóko ẹrú.

“Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?’ ”​—Hébérù 13:6