Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 26

Àwọn Amí Méjìlá

Àwọn Amí Méjìlá

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní orí Òkè Sínáì, wọ́n rin ìrìn àjò gba àwọn aṣálẹ̀ Páránì lọ sí ibì kan tó ń jẹ́ Kádéṣì. Níbẹ̀, Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Rán ọkùnrin méjìlá [12] látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ yìí ni mo máa fún ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì.’ Torí náà, Mósè yan ọkùnrin méjìlá [12], ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ Kénáánì wò bóyá ó dáa fun iṣé àgbẹ̀. Kí ẹ sì wo bí wọ́n ṣe lágbára tó, bóyá inú àgọ́ ni wọ́n ń gbé tàbí ìlú ńlá.’ Jóṣúà àti Kálébù wà lára àwọn amí méjìlá náà, gbogbo wọn sì gba ilẹ̀ Kénáánì lọ.

Àwọn amí yìí pa dà lẹ́yìn ogójì [40] ọjọ́, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀tọ́, pómégíránétì, àti èso àjàrà wálé. Wọ́n sọ pé: ‘Ilẹ̀ náà dára, àmọ́ àwọn èèyàn ibẹ̀ lágbára gan-an, ògiri wọn sì tún ga gìrìwò.’ Kálébù wá sọ pé: ‘A lè ṣẹ́gun wọn. Ẹ jẹ́ ká lọ mú wọn balẹ̀ báyìí!’ Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Kálébù fi sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé òun àti Jóṣúà gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Àmọ́ àwọn amí mẹ́wàá tó kù sọ pé: ‘Rárá! Àwa ò ní tẹ̀lé yín lọ sí ibikíbi. Àwọn ará ìlú yẹn ga gan-an, wọ́n sì lágbára! Ńṣe la dà bí kòkòrò kékeré ní ẹ̀gbẹ́ wọn.’

Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bà jẹ́. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn, wọ́n sì ń sọ fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ ká yan ẹlòmíì táá máa darí wa, ká sì pa dà sí Íjíbítì. Kí ló dé tí a fi máa gba ilẹ̀ Kénáánì lọ kí wọ́n lè pa wá dà nù?’ Jóṣúà àti Kálébù sọ pé: ‘Ẹ má ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ẹ má sì bẹ̀rù rárá. Jèhófà máa dáàbò bò wá.’ Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́. Àní wọ́n tiẹ̀ fẹ́ pa Jóṣúà àti Kálébù!

Kí ni Jèhófà wá ṣe? Ó sọ fún Mósè pé: ‘Pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, síbẹ̀ wọn kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Fún ohun tí wọ́n ṣe yìí, wọn kò ní kúrò nínú aṣálẹ̀ yìí fún ogójì [40] ọdún, ibẹ̀ sì ni wọ́n máa kú sí. Àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú Jóṣúà àti Kálébù ló máa gba ilẹ̀ tí mo ṣèlérí pé màá fún un yín.’

“Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣọkàn ojo, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré?” ​—Mátíù 8:26