Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 30

Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́

Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́

Nígbà tí àwọn amí ilẹ̀ Ísírẹ́lì dé Jẹ́ríkò, ilé obìnrin kan tó ń jẹ́ Ráhábù ni wọ́n wọ̀. Nígbà tí ọba Jẹ́ríkò gbọ́, ó rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n lọ mú wọn wá nílé Ráhábù. Àmọ́, Ráhábù fi àwọn amí náà pa mọ́ sí òrùlé ilé rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun dé, ńṣe ló júwe ibòmíì fún wọn. Ó wá sọ fún àwọn amí náà pé: ‘Mo máa ràn yín lọ́wọ́ tórí mo mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú yín, àti pé ẹ máa ṣẹ́gun ìlú yìí. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣèlérí fún mi pé ẹ kò ní pa èmi àti àwọn mọ̀lẹ́bí mi.’

Àwọn amí náà sọ fún Ráhábù pé: ‘A ṣèlérí pé kò sẹ́nì kankan nínú ilé rẹ tó máa fara pa.’ Wọ́n wá sọ pé: ‘So okùn pupa yìí mọ́ ojú wíndò rẹ kí ìdílé rẹ má bàa pa run.’

Ráhábù jẹ́ kí àwọn amí yìí fi okùn kan sọ̀ kalẹ̀ láti ojú wíndò rẹ̀. Wọ́n sì sá lọ sórí àwọn òkè láti fara pa mọ́ fún ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n tó pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírélì sọdá Odò Jọ́dánì láti lọ gba ilẹ̀ náà. Ìlú Jẹ́ríkò ni wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́gun. Jèhófà ní kí wọ́n máa rìn bí ológun yíká ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà, tó bá wá di ọjọ́ keje, kí wọ́n rìn yíká lẹ́ẹ̀méje. Lẹ́yìn náà, kí àwọn àlùfáà fọn kàkàkí wọn, kí àwọn ológun sì fi gbogbo agbára wọn pariwo. Bí ògiri Jẹ́ríkò ṣe wó lulẹ̀ nìyẹn! Àmọ́ ilé Ráhábù tí wọ́n kọ́ mọ́ ògiri ìlú kò wó. Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ kò kú torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

“Lọ́nà kan náà, a kò ha polongo Ráhábù . . . pẹ̀lú ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́, lẹ́yìn tí ó ti gba àwọn ońṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn?”​—Jákọ́bù 2:25