Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 31

Joshua and the Gibeonites

Joshua and the Gibeonites

Gbogbo ìlú tó kù ní Kénáánì ló gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Jẹ́ríkò. Àwọn ọba ìlú tó kù wá sọ pé àwọn jọ máa bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà. Ṣùgbọ́n àwọn ará Gíbéónì dá ọgbọ́n kan tó yàtọ̀ sí ti àwọn tó kù. Wọ́n wọ aṣọ tó ti gbó lọ sọ́dọ̀ Jóṣúà, wọ́n ní: ‘Ọ̀nà jíjìn la ti wá. A ti gbọ́ nípa Jèhófà àti gbogbo ohun tó ṣe fún un yín ní Íjíbítì àti ní Móábù. A fẹ́ kí ẹ ṣèlérí fún wa pé ẹ kò ní bá wa jagun, a sì máa di ìránṣẹ́ yín.’

Jóṣúà gba ohun tí wọ́n sọ, ó sì ṣèlérí fún wọn. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó gbọ́ pé irọ́ ni àwọn èèyàn yìí pa fún òun. Àṣé ilẹ̀ Kénáánì tó wà ní itòsí ni wọ́n ti wá. Jóṣúà wá béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Gíbéónì yìí pé: ‘Kí ló dé tí ẹ fi parọ́ fún wa?’ Wọ́n dáhùn pé: ‘Ẹ̀rù ló bà wá! A mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run yín ń jà fún un yín. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má pa wá.’ Torí ìlérí tí Jóṣúà ti ṣe fún wọn tẹ́lẹ̀, kò pa wọ́n.

Kò pẹ́ ni àwọn ọba Kénáánì márùn-ún àti àwọn ọmọ ogun wọn wá halẹ̀ mọ́ àwọn ará Gíbéónì. Jóṣúà àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì lọ dáàbò bo àwọn ará Gíbéónì. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjà ní kùtùkùtù àárọ̀ ọjọ́ kejì. Bí àwọn ará Kénáánì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ nìyẹn. Gbogbo ibi tí wọ́n ń sá gbà ni Jèhófà ń rọ yìnyín tó dà bí òkúta lé wọn lórí. Lẹ́yìn ìyẹn, Jóṣúà gbàdúrà pé kí Jèhófà mú kí oòrùn dúró sójú kan. Kí nìdí tó fi ní kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí oòrùn kò dúró sójú kan rí? Ìdí ni pé ó mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí Jèhófà kò lè ṣe. Oòrùn sì dúró fún odindi ọjọ́ kan gbáko títí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣẹ́gun àwọn ọba Kénáánì àti àwọn ọmọ ogun wọn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 79]