Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 34

Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì

Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì

Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì ń bọ òrìṣà. Fún ọdún méje gbáko, àwọn ará Mídíánì máa ń jí ẹran ọ̀sìn wọn, wọ́n sì ń ba irè oko wọn jẹ́. Inú ihò àpáta àti orí òkè ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń sá pa mọ́ sí kí àwọn ará Mídíánì má bàa rí wọn. Wọ́n wá gbàdúrà pé kí Jèhófà gba àwọn. Torí náà, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Gídíónì. Áńgẹ́lì náà sọ pé: ‘Jèhófà ti yàn ẹ́ láti jẹ́ akínkanjú jagunjagun.’ Gídíónì wá béèrè pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀? Èmi tí mi ò jámọ́ nǹkan kan.’

Báwo ni Gídíónì ṣe máa mọ̀ pé Jèhófà ti yan òun? Ó mú òwú kan sílẹ̀, ó sì sọ fún Jèhófà pé: ‘Ní àárọ̀ ọ̀la, tí ìrì bá sẹ̀ sí òwú yìí nìkan tí ilẹ̀ sì gbẹ, èmi yóò mọ̀ pé lóòótọ́ lo fẹ́ kí n gba Ísírẹ́lì là.’ Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, ìrì sẹ̀ sí òwú yẹn nìkan, ilẹ̀ sì gbẹ! Àmọ́ Gídíónì tún sọ pé tó bá di ọjọ́ kejì, kí òwú yẹn nìkan gbẹ, àmọ́ kí ilẹ̀ tutù. Nígbà tí ìyẹn náà ṣẹlẹ̀, ó dá Gídíónì lójú pé Jèhófà ti yan òun lóòótọ́. Ni Gídíónì bá kó àwọn ọmọ ogun jọ láti bá àwọn ará Mídíánì jà.

Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: ‘Èmi yóò mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun. Àmọ́ torí pé àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì pọ̀, ẹ lè máa ronú pé ẹ̀yin fúnra yín lẹ ṣẹ́gun. Sọ fun ẹni tí ẹ̀rù bá ń bà pé kó pa dà sílé.’ Torí náà, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pa dà sílé, ó wá ṣẹ́ ku ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] péré. Jèhófà tún sọ pé: ‘Àwọn ọmọ ogun náà ṣì pọ̀. Kó wọn lọ sí etí odò, kí o sì sọ fún wọn pé kí wọ́n mu omi. Kìkì àwọn tó ń fojú ẹ̀gbẹ́ kan ṣọ́ àwọn ọ̀tá nígbà tí wọ́n ń mu omi ni kí o yàn.’ Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] àwọn ọmọ ogún péré ló ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà wá ṣèlérí pé ìwọ̀nba àwọn ọmọ ogun yẹn ló máa ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Mídíánì tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùnléláàádóje [135,000].

Ní òru ọjọ́ yẹn, Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: ‘Ó ti tó àkókò báyìí láti lọ bá àwọn ọmọ ogún Mídíánì jà!’ Gídíónì fún àwọn ọmọ ogún rẹ̀ ní ìwo àti ìkòkò ńlá kan tí iná wà nínú rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì ṣe bí mo ti ṣe.’ Gídíónì fọn ìwo ọwọ́ rẹ̀, ó fọ́ ìkòkò náà mọ́lẹ̀, ó fi ìná náà sọ́tùn-sósì, ó sì pariwo pé: ‘Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!’ Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọkùnrin náà sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ogun Mídíánì, wọ́n wá ń sá káàkiri. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ara wọn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá.

“Kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.”​—2 Kọ́ríńtì 4:7