Ẹ̀KỌ́ 35
Hánà Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Òun ní Ọmọkùnrin
Ọmọ Ísírẹ́lì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹlikénà fẹ́ ìyàwó méjì. Hánà àti Pẹ̀nínà ni orúkọ wọn, àmọ́ Hánà ló fẹ́ràn jù. Pẹ̀nínà máa ń fi Hánà ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé kò rọ́mọ bí, àmọ́ Pẹ̀nínà bímọ tó pọ̀ ní tiẹ̀. Ní ọdọọdún, Ẹlikénà máa ń kó ìdílé rẹ̀ lọ sí àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò láti lọ jọ́sìn. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n wà ní Ṣílò, ó kíyè sí pé inú Hánà ìyàwó rẹ̀ kò dùn rárá. Ó wá sọ pé: ‘Hánà jọ̀ọ́ má sunkún mọ́. Mi ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láéláé. Mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.’
Nígbà tó yá, Hánà lọ dá gbàdúrà. Bó ṣe ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ ló ṣáà ń sunkún. Ó ṣèlérí pé: ‘Jèhófà, tí o bá fún mi ní ọmọkùnrin, ìwọ ni mo máa fún, ó sì máa fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ sìn ẹ́.’
Élì Àlùfáà Àgbà rí i pé Hánà ń sunkún, ó sì ronú pé ó ti mutí yó. Hánà dáhùn pé: ‘Rárá Olúwa mi, mi ò mutí yó. Mo ní ìṣòro ńlá kan ni, mo sì ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.’ Élì wá rí i pé èrò òun kò dára, ló bá sọ fún un pé: ‘Kí Ọlọ́run fún ẹ ní ohun tí o tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀.’ Ara tu Hánà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Kò pé ọdún kan lẹ́yìn náà tó fi bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì. Ǹjẹ́ o mọ bí inú Hánà ṣe máa dùn tó?
Hánà kò gbàgbé ìlérí tó ṣe fún Jèhófà. Bí Hánà ṣe rí i pé Sámúẹ́lì ti dàgbà díẹ̀, ó mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn kó lè máa sin Jèhófà níbẹ̀. Ó sọ fún Élì pé: ‘Ọmọkùnrin tí mo tọrọ lọ́wọ́ Ọlọ́run nìyí. Mo ti yọ̀ǹda rẹ̀ fún Jèhófà títí láé.’ Ọdọọdún ni Ẹlikénà àti Hánà máa ń lọ wo Sámúẹ́lì, wọ́n á sì mú aṣọ kékeré tí kò lápá lọ fún un. Jèhófà tún wá fún Hánà ní ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì míì.
“Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí.”—Mátíù 7:7