Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 36

Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe

Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe

Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà. Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà, àwọn òrìṣà yẹn kò ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi jìyà. Wọ́n wá sọ fún Jèhófà pé: ‘A ti dẹ́ṣẹ̀. Jọ̀wọ́ gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.’ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó àwọn òrìṣà wọn dànù, wọ́n sì pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà. Inú Jèhófà kò dùn sí bí ìyà ṣe ń jẹ wọ́n.

Wọ́n wá yan jagunjagun kan tó ń jẹ́ Jẹ́fútà láti ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ Ámónì. Jẹ́fútà sọ fún Jèhófà pé: ‘Tí o bá jẹ́ ká ṣẹ́gun, mo ṣèlérí pé tí mo bá pa dà délé, ẹnikẹ́ni tó bá kọ́kọ́ jáde wá pàdé mi ni mo máa yọ̀ǹda fún ẹ.’ Jèhófà gbọ́ àdúrà Jẹ́fútà, ó sì jẹ́ kó borí ogun náà.

Nígbà tí Jẹ́fútà pa dà délé, ọmọbìnrin rẹ̀ ló kọ́kọ́ jáde wá pàdé rẹ̀, òun sì ni ọmọ kan ṣoṣo tó bí. Ó ń jó, ó sì ń lu tanboríìnì. Kí ni Jẹ́fútà máa ṣe báyìí? Ó rántí ìlérí tó ṣe, ó sì sọ pé: ‘Áà ọmọbìnrin mi! O ti bà mí lọ́kàn jẹ́. Mo ṣèlérí fún Jèhófà. Kí n lè mú ìlérí náà ṣẹ, mo gbọ́dọ̀ rán ẹ lọ sí àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò, láti lọ sìn níbẹ̀.’ Ọmọbìnrin rẹ̀ wá sọ fún un pé: ‘Bàbá mi, tí ẹ bá ti ṣèlérí fún Jèhófà, ẹ gbọ́dọ̀ mú ìlérí yín ṣẹ. Àmọ́, ẹ fún mi ní oṣù méjì, kí n lè wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi lórí àwọn òkè. Lẹ́yìn náà, mo máa lọ.’ Ọmọbìnrin Jẹ́fútà sin Jèhófà tọkàntọkàn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ní àgọ́ ìjọsìn náà. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì máa ń lọ kí i ní Ṣílò lọ́dọọdún.

“Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni tí ó pọ̀ fún baba tàbí ìyá ju èyí tí ó ní fún mi, kò yẹ fún mi.” ​—Mátíù 10:37