Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 38

Jèhófà Sọ Sámúsìnì Di Alágbára

Jèhófà Sọ Sámúsìnì Di Alágbára

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà, torí náà Jèhófà gba àwọn Filísínì láyè láti máa ṣàkóso ilẹ̀ wọn. Àmọ́ àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ọ̀kan lára wọn ni Mánóà. Òun àti ìyàwó rẹ̀ kò ní ọmọ kankan. Lọ́jọ́ kan, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí ìyàwó Mánóà. Áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: ‘O máa bí ọmọkùnrin kan. Òun ló máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì. Násírì ló sì máa jẹ́.’ Ṣé o mọ àwọn tí wọ́n ń pè ní Násírì? Àwọn ni wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì fún Jèhófà. Àwọn Násírì kò sì gbọ́dọ̀ gé irun orí wọn.

Nígbà tí wọ́n bí ọmọ náà, Mánóà sọ ọ́ ní Sámúsìnì. Nígbà tí Sámúsìnì dàgbà, Jèhófà sọ ọ́ di alágbára. Sámúsìnì lè fi ọwọ́ lásán pa kìnnìún. Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà tí Sámúsìnì nìkan pa ọgbọ̀n [30] lára àwọn Filísínì. Àwọn Filísínì kórìíra rẹ̀ gan-an, wọ́n sì ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á. Lálẹ́ ọjọ́ kan tí Sámúsìnì ń sùn ní ìlú Gásà, àwọn Filísínì lọ dúró dè é ní ẹnu bodè ìlú, kí wọ́n lè pa á tí ilẹ̀ bá mọ́. Àmọ́ ní àárín òru, Sámúsìnì dìde lọ sí ẹnu bodè ìlú náà, ó sì fa géètì náà yọ lára ògiri. Ó wá gbé e lé èjìká rẹ̀, ó sì rìn lọ sí orí òkè Hébúrónì!

Lọ́jọ́ kan, àwọn Filísínì lọ bá ọ̀rẹ́bìnrin Sámúsìnì, tó ń jẹ́ Dẹ̀lílà, wọ́n sọ fún un pé: ‘A máa san owó ńlá fún ẹ tí o bá lè bá wa wádìí ibi tí Sámúsìnì ti ń rí agbára rẹ̀. A fẹ́ mú un ká sì jù ú sẹ́wọ̀n.’ Owó yẹn wọ Dẹ̀lílà lójú, ó sì gbà láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Àmọ́, Sámúsìnì kò kọ́kọ́ sọ ìdí agbára rẹ̀ fún un. Síbẹ̀ Dẹ̀lílà bẹ Sámúsìnì títí tó fi gbà láti sọ fún un. Ó ní: ‘Wọn kò tíì gé irun orí mi rí, torí pé Násírì ni mí. Tí mo bá gé e, mi ò ní lágbára mọ́.’ Ẹ ò rí i pé àṣìṣe ńlá ni Sámúsìnì ṣe tó fi sọ ìdí agbára rẹ̀ fún Dẹ̀lílà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Dẹ̀lílà ti sọ fún àwọn Filísínì pé: ‘Mo ti mọ ìdí agbára rẹ̀!’ Dẹ̀lílà mú kí Sámúsìnì sùn lórí itan rẹ̀, ẹnì kan sì gé irun orí Sámúsìnì. Dẹ̀lílà wá pariwo pé: ‘Sámúsìnì, àwọn Filísínì ti dé!’ Sámúsìnì fò dìde, àmọ́ kò lágbára mọ́. Àwọn Filísínì gbá a mú, wọ́n yọ ojú rẹ̀, wọ́n sì jù ú sí ẹ̀wọ̀n.

Lọ́jọ́ kan, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Filísínì péjọ sílé òrìṣà wọn, ìyẹn Dágónì, wọ́n sì ń kígbe pé: ‘Ọlọ́run wa ti jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ Sámúsìnì! Ẹ mú un jáde! Ẹ jẹ́ kó wá ṣeré fún wa.’ Wọ́n mú kó dúró sí àárín òpó méjì, wọ́n sì n fi ṣe yẹ̀yẹ́. Sámúsìnì wá gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, jọ̀wọ́ fún mi lágbára lẹ́ẹ̀kan sí i.’ Ní àkókò yìí, irun Sámúsìnì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gùn. Ó wá fi gbogbo agbára rẹ̀ ti òpó ilé náà. Ilé náà wó lulẹ̀, ó sì pa gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ títí kan Sámúsìnì.

“Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”​—Fílípì 4:13