Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 40

Dafidi ati Golayati

Dafidi ati Golayati

Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Lọ sí ilé Jésè. Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ló máa di ọba Ísírẹ́lì.’ Torí náà, Sámúẹ́lì lọ sí ilé Jésè. Nígbà tó rí àkọ́bí Jésè, Sámúẹ́lì ronú pé: ‘Ọmọkùnrin yìí ló máa jẹ́.’ Àmọ́ Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé kì í ṣe òun. Jèhófà sọ fún un pé: ‘Ọkàn èèyàn ni mo máa ń wò, kì í ṣe bí èèyàn ṣe rí.’

Jésè wá mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́fà míì wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì. Àmọ́ Sámúẹ́lì sọ fún Jésè pé: ‘Jèhófà kò mú ẹnì kankan lára wọn. Ǹjẹ́ o ní àwọn ọmọkùnrin míì?’ Jésè dáhùn pé: ‘Ó ṣì ku ọ̀kan, àbúrò gbogbo wọn, Dáfídì ni orúkọ rẹ̀. Ó wà níbi tó ti ń tọ́jú àwọn àgùntàn mi.’ Nígbà tí wọ́n mú Dáfídì dé, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Ẹni tí mo fẹ́ gan-an nìyẹn!’ Sámúẹ́lì da òróró sórí Dáfídì, ó sì yàn án pé òun ló máa di ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú.

Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn ará Filísínì jagun. Ọkùnrin kan wà lára àwọn ọmọ ogun Filísínì yẹn tó ga gan-an tó sì lágbára, Gòláyátì ni orúkọ rẹ̀. Ojoojúmọ́ ló máa ń fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹ rán ẹnì kan sí mi kó wá bá mi jà. Tó bá ṣẹ́gun, a máa di ẹrú yín. Àmọ́ tí mo bá ṣẹ́gun rẹ̀, e máa di ẹrú wa.’

Àsìkò yẹn ni Dáfídì wá sí ibi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà, ó wá gbé oúnjẹ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí àwọn náà jẹ́ ọmọ ogun. Nígbà tí Dáfídì gbọ́ ohun tí Gòláyátì ń sọ, ó sọ pé: ‘Mo máa bá ọkùnrin yẹn jà!’ Ọba Sọ́ọ̀lù sọ fún un pé: ‘Ọmọdé ni ẹ́, àgbàlagbà ni òun.’ Dáfídì dáhùn pé: ‘Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́.’

Sọ́ọ̀lù fẹ́ kí Dáfídì wọ ẹ̀wù ogun rẹ̀, àmọ́ Dáfídì sọ pé: ‘Mi ò lè wọ ẹ̀wù yìí.’ Dáfídì mú rọ́bà tó fi máa ń ta òkúta, ó sì lọ sí etí odò kan. Ó ṣa òkúta márùn-ún tó ń dán dáadáa, ó sì kó wọn sínú àpò tó wà lọ́wọ́ rẹ̀. Dáfídì wá sáré lọ bá Gòláyátì. Nígbà tí Gòláyátì rí i, ó sọ pé: ‘Máa bọ̀, ìwọ ọmọ kékeré yìí. Tí mo bá pa ẹ́ tán, àwọn ẹyẹ àti ẹranko ló máa jẹ òkú rẹ.’ Dáfídì kò bẹ̀rù. Ó sọ fún ọkùnrin náà pé: ‘Ìwọ mú idà àti ọ̀kọ̀ láti wá bá mi jà, àmọ́ èmi máa bá ẹ jà ní orúkọ Jèhófà. Àwa kọ́ ni ò ń bá jà, Ọlọ́run lò ń bá jà. Gbogbo àwọn tó wà níbí lónìí ló máa mọ̀ pé Jèhófà lágbára ju idà àti ọ̀kọ̀ tí o gbé dání. Jèhófà máa fi gbogbo yín lé wa lọ́wọ́.’

Dáfídì wá mú ọ̀kan lára òkúta yẹn sínú rọ́bà ọwọ́ rẹ̀, ó fi rọ́bà náà dáadáa, ó sì fi rọ́bà náà ta òkúta náà. Jèhófà ran Dáfídì lọ́wọ́, ńṣe ni òkúta yẹn wọ orí Gòláyátì lọ. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Gòláyátì ṣubú lulẹ̀, ó sì kú. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Filísínì, wọ́n sì sá lọ. Ṣé ìwọ náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi ti Dáfídì?

“Fún ènìyàn kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”​—Máàkù 10:27

1 Sámúẹ́lì 16:​1-13; 17:​1-54