Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 42

Jónátánì Láyà, Ó sì Jẹ́ Adúrótini

Jónátánì Láyà, Ó sì Jẹ́ Adúrótini

Jónátánì ni orúkọ ọmọkùnrin tí Ọba Sọ́ọ̀lù kọ́kọ́ bí. Jagunjagun tó láyà ni, kì í bẹ̀rù. Dáfídì tiẹ̀ sọ pé Jónátánì yára ju ẹyẹ idì lọ, ó sì lágbára ju kìnnìún lọ. Lọ́jọ́ kan, Jónátánì rí àwọn ọmọ ogun Filísínì tí wọ́n tó ogún [20] lórí òkè kan. Ó wá sọ fún ẹni tó máa ń ràn án lọ́wọ́ pé: ‘Tí Jèhófà bá fún wa ní àmì nìkan ni a máa lọ bá wọn jà. Bí àwọn ọmọ ogun yẹn bá sọ fún wa pé ká máa bọ̀, a máa lọ bá wọn jà.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Àwọn ọmọ ogun Filísínì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa gòkè bọ̀, ká jọ jà!’ Bí Jónátánì àti ìkejì rẹ̀ ṣe lọ bá wọn nìyẹn, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun náà.

Torí pé Jónátánì ni àkọ́bí lára àwọn ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, òun ló yẹ kó jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Ṣùgbọ́n Jónátánì mọ̀ pé Jèhófà ti yan Dáfídì láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì, kò sì bínú sí i. Ńṣe ni òun àti Dáfídì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Àwọn méjèèjì ṣèlérí pé àwọn á máa ti ara àwọn lẹ́yìn, àwọn ò sì ní fi ara wọn sílẹ̀. Jónátánì wá bọ́ ẹ̀wù rẹ̀ ó sì fún Dáfídì, ó tún fún un ní idà, ọrun àti bẹ́líìtì rẹ̀ kí Dáfídì lè mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Nígbà tí Dáfídì sá lọ torí Sọ́ọ̀lù, Jónátánì lọ bá Dáfídì níbi tó wà, ó sì sọ fún un pé: ‘Má bẹ̀rù, ṣó o gbọ́? Ìwọ ni Jèhófà yàn láti jẹ́ ọba. Bàbá mi náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.’ Ṣé ìwọ náà fẹ́ ní ọ̀rẹ́ tó dà bíi Jónátánì?

Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jónátánì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu torí Dáfídì. Ó mọ̀ pé bàbá òun fẹ́ pa Dáfídì, ó wá sọ fún bàbá rẹ̀ pé: ‘Inú Ọlọ́run kò ní dùn tí ẹ bá pa Dáfídì; kò hùwà burúkú kankan.’ Ṣé Sọ́ọ̀lù wá gbọ́rọ̀ sí ọmọ rẹ̀ lẹ́nu? Rárá o, ṣe ló bínú gan-an sí Jónátánì. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì kú sójú ogun lọ́jọ́ kan náà.

Lẹ́yìn tí Jónátánì kú, Dáfídì lọ wá ọmọ Jónátánì tó ń jẹ́ Mefibóṣẹ́tì. Nígbà tí Dáfídì rí Mefibóṣẹ́tì, ó sọ fún un pé: ‘Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni èmi àti bàbá rẹ, torí náà mo máa tọ́jú ẹ. Wàá máa gbé nínú ààfin mi, wàá sì máa jẹun lọ́dọ̀ mi.’ Ó dájú pé Dáfídì kò gbàgbé Jónátánì ọ̀rẹ́ rẹ̀.

“Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”​—Jòhánù 15:​12, 13