Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 43

Ọba Dáfídì Dá Ẹ̀ṣẹ̀

Ọba Dáfídì Dá Ẹ̀ṣẹ̀

Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù kú, Dáfídì di ọba. Ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún ni nígbà yẹn. Lẹ́yìn ọdún mélòó kan tó di ọba, ohun kan ṣẹlẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ kan, ó wà lórí òkè ààfin rẹ̀, ó sì rí obìnrin kan tó rẹwà. Dáfídì wádìí nípa obìnrin yẹn, wọ́n sì sọ fún un pé Bátí-ṣébà ni orúkọ rẹ̀ àti pé ọmọ ogun kan tó ń jẹ́ Ùráyà ni ọkọ rẹ̀. Dáfídì ní kí wọ́n bá òun pe Bátí-ṣébà wá. Dáfídì bá obìnrin náà sùn, obìnrin náà sì lóyún. Dáfídì kò fẹ́ kí àṣírí òun tú. Ó wá sọ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n fi Ùráyà sí iwájú ogun, kí wọ́n sì pa dà lẹ́yìn rẹ̀. Bó ṣe di pé Ùráyà kú sójú ogun nìyẹn, tí Dáfídì sì fẹ́ Bátí-ṣébà.

Àmọ́ Jèhófà rí gbogbo ìwà búburú tí Dáfídì hù. Kí wá ni Jèhófà ṣe? Jèhófà rán wòlíì Nátánì sí Dáfídì. Nátánì sọ fún Dáfídì pé: ‘Ọkùnrin olówó kan ní àgùntàn tó pọ̀ gan-an, tálákà kan sì ní ọmọ àgùntàn kan ṣoṣo, ó sì máa ń tọ́jú rẹ̀ gan-an. Àmọ́, ṣe ni olówó yẹn gba ọmọ àgùntàn kan ṣoṣo tí tálákà náà ní.’ Nígbà tí Dáfídì gbọ́, inú bí i, ó sì sọ pé: ‘Ṣe ló yẹ ká pa ọkùnrin olówó yẹn!’ Nátánì wá sọ fún Dáfídì pé: ‘Ìwọ gan-an ni ọkùnrin yẹn!’ Inú Dáfídì bà jẹ́, ó sì jẹ́wọ́ fún Nátánì pé: ‘Mo ti ṣẹ Jèhófà.’ Ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì dá yẹn mú wàhálà bá òun àti àwọn ará ilé rẹ̀. Jèhófà fi ìyà jẹ Dáfídì, àmọ́ Jèhófà kò jẹ́ kó kú torí pé Dáfídì jẹ́ olóòótọ́, kò sì gbéra ga.

Ó wu Dáfídì láti kọ́ tẹ́ńpìlì fún Jèhófà, àmọ́ Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ni Jèhófà yàn pé kí ó kọ́ tẹ́ńpìlì fún òun. Síbẹ̀, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn nǹkan jọ fún Sólómọ́nì. Dáfídì wá sọ pé: ‘Tẹ́ńpìlì Jèhófà máa tóbi, ó sì máa lẹ́wà gan-an. Àmọ́ Sólómọ́nì ọmọ mi ṣì kéré, torí náà mo ti kó àwọn nǹkan tó máa lò sílẹ̀ fún un.’ Dáfídì kó owó rẹpẹtẹ sílẹ̀ kí wọ́n lè fi kọ́ ilé náà. Ó wá àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ dáadáa. Ó kó àwọn nǹkan míì jọ, bíi góòlù àti fàdákà, ó sì kó àwọn igi kédárì wá láti ìlú Tírè àti Sídónì. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Dáfídì kú, ó fún Sólómọ́nì ní ìwé tí wọ́n ya àwòrán tẹ́ńpìlì náà sí. Ó wá sọ fún un pé: ‘Jèhófà ló ní kí n ya àwòrán yìí sílẹ̀ fún ẹ. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má bẹ̀rù, ṣe bí ọkùnrin, kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà.’

“Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” ​—Òwe 28:13