Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 44

Wọ́n Kọ́ Tẹ́ńpìlì fún Jèhófà

Wọ́n Kọ́ Tẹ́ńpìlì fún Jèhófà

Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì di ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Kí lo fẹ́ kí n fún ẹ?’ Sólómọ́nì sọ pé: ‘Ọmọdé ni mí, torí náà mi ò gbọ́n. Jọ̀ọ́, fún mi ní ọgbọ́n tí màá fi lè bójú tó àwọn èèyàn rẹ.’ Jèhófà dáhùn pé: ‘Torí pé ọgbọ́n lo béèrè fún, màá sọ ẹ́ di ẹni tó gbọ́n jù láyé. Mo sì máa jẹ́ kí o lówó gan-an. Tí o bá ṣe ohun tí mo fẹ́, wàá pẹ́ láyé.’

Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì, ó lo àwọn nǹkan tó dára gan-an láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà, irú bíi góòlù, fàdákà, igi àti òkúta. Àìmọye àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ṣiṣẹ́ láti kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Ọdún méje [7] ni wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà, lẹ́yìn náà wọ́n ya tẹ́ńpìlì náà sí mímọ́ fún Jèhófà. Wọ́n kọ́ pẹpẹ kan sínú rẹ̀, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti máa ń rúbọ. Sólómọ́nì kúnlẹ̀ níwájú pẹpẹ yẹn, ó sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, tẹ́ńpìlì yìí tóbi lóòótọ́, ó sì rẹwà, àmọ́ kò lè gbà ọ́. Mo bẹ̀ ọ́, máa gbọ́ àdúrà wa, kí inú rẹ sì dùn sí ìjọsìn wa.’ Ṣé inú Jèhófà dùn sí tẹ́ńpìlì yẹn, ṣé ó sì gbọ́ àdúrà Sólómọ́nì? Bẹ́ẹ̀ ni. Torí pé kò pẹ́ tí Sólómọ́nì gba àdúrà náà tán ni iná wá láti ọ̀run, ó sì jó gbogbo ẹbọ tí wọ́n kó sórí pẹpẹ. Ìyẹn fi hàn pé inú Jèhófà dùn sí tẹ́ńpìlì náà. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, inú wọn dùn gan-an.

Ibi gbogbo ni àwọn èèyàn ti gbọ́ pé Ọba Sólómọ́nì ní ọgbọ́n, kì í ṣe ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìkan. Torí náà, àwọn èèyàn máa ń gbé ìṣòro wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kó bá wọn yanjú rẹ̀. Ọbabìnrin ilẹ̀ Ṣébà tiẹ̀ béèrè àwọn ìbéèrè tó ta kókó lọ́wọ́ Sólómọ́nì. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí bí Sólómọ́nì ṣe yanjú àwọn ìbéèrè rẹ̀, ó sọ pé: ‘Mi ò kọ́kọ́ gba ohun tí àwọn èèyàn sọ nípa rẹ gbọ́, àmọ́ èmi fúnra mi ti wá rí i pé ọgbọ́n rẹ kọjá ohun tí àwọn èèyàn sọ. Jèhófà Ọlọ́run tí ò ń sìn ti bù kún rẹ gan-an.’ Ní àsìkò yẹn, nǹkan ń lọ dáradára ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, inú àwọn èèyàn sì ń dùn. Àmọ́, nǹkan máa tó yí pa dà.

“Wò ó! ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ wà níhìn-ín.” ​—Mátíù 12:42