Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 45

Ìjọba Ísírẹ́lì Pín sí Méjì

Ìjọba Ísírẹ́lì Pín sí Méjì

Àlàáfíà wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ní gbogbo ìgbà tí Sólómọ́nì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àmọ́ nígbà tó yá, ṣe ni Sólómọ́nì lọ fẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin àjèjì, òrìṣà ni àwọn obìnrin náà sì ń bọ. Bó ṣe di pé Sólómọ́nì náà bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà ilẹ̀ àjèjì nìyẹn. Inú bí Jèhófà gan-an. Jèhófà wá sọ fún Sólómọ́nì pé: ‘Màá gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ìdílé rẹ, màá sì pín in sí méjì. Màá fún ìránṣẹ́ rẹ ní apá tí ó tóbi jù lára rẹ̀, ìdílé rẹ á sì máa jọba ní apá kékeré tó ṣẹ́ kù.’

Jèhófà ṣe ohun kan tó mú kí ìpinnu rẹ̀ ṣe kedere. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì tó ń jẹ́ Jèróbóámù ń rìnrìn-àjò, ló bá pàdé wòlíì kan tó ń jẹ́ Áhíjà. Nígbà tí wọ́n pàdé, Áhíjà fa aṣọ ara rẹ̀ ya, ó sì pín in sọ́nà méjìlá, ó wá sọ fún Jèróbóámù pé: ‘Jèhófà máa gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ ìdílé Sólómọ́nì, ó sì máa pín in sí méjì. Torí náà, mú ẹ̀wù mẹ́wàá lára méjìlá náà, torí pé ìwọ lo máa jẹ ọba lórí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì.’ Nígbà tí Ọba Sólómọ́nì gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa pa Jèróbóámù. Ni Jèróbóámù bá sá lọ sí ìlú Íjíbítì. Nígbà tó yá, Sólómọ́nì kú, ọmọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Rèhóbóámù sì di ọba. Ìgbà yẹn ni Jèróbóámù pa dà sí Ísírẹ́lì.

Àwọn àgbàlagbà tó wà ní Ísírẹ́lì sọ fún Rèhóbóámù pé: ‘Tí o bá ń ṣe dáadáa sí àwọn ará ìlú, wọn kò ní fi ẹ́ sílẹ̀.’ Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ Rèhóbóámù tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ sọ fún un pé: ‘Ṣe ni kí o túbọ̀ fìyà jẹ wọ́n dáadáa. Kí o tún fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn.’ Kàkà kí Rèhóbóámù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàlagbà fún un, ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ ló ṣe. Rèhóbóámù wá bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ àwọn ará ìlú, àwọn èèyàn náà sì pa dà lẹ́yìn rẹ̀. Wọ́n fi Jèróbóámù jọba ẹ̀yà mẹ́wàá, ẹ̀yà mẹ́wàá yìí la wá mọ̀ sí ìjọba Ísírẹ́lì. Ẹ̀yà méjì tó kù la mọ̀ sí ìjọba Júdà, àwọn ará Júdà ò sì pa dà lẹ́yìn Rèhóbóámù. Bí ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì ṣe pín sí méjì nìyẹn.

Jèróbóámù ò fẹ́ kí àwọn èèyàn òun máa lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù torí pé abẹ́ ìjọba Rèhóbóámù ni ibẹ̀ wà. Ṣé o mọ ìdí? Ìdí ni pé ẹ̀rù ń ba Jèróbóámù pé tí wọ́n bá ń lọ síbẹ̀, wọ́n máa pa òun tì, wọ́n á sì pa dà sọ́dọ̀ Rèhóbóámù. Ó wá gbẹ́ ère ọmọ màlúù wúrà méjì fún wọn, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Jerúsálẹ́mù ti jìnnà jù. Ẹ máa ṣe ìjọsìn yín níbí. Bí àwọn èèyàn náà ṣe gbàgbé Jèhófà nìyẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn ère ọmọ màlúù náà.

“Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? . . . Tàbí ìpín wo ni olùṣòtítọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?”​—2 Kọ́ríńtì 6:​14, 15